Ìgbaná

(Àtúnjúwe láti Combustion)

Ìgbaná tabi ìjóná ni a n pe gbogbo itunse apopoogun (chemical reaction) to n mu igbona ati imole wa. Igbana je ifesi Iresile-Isodioloksijini. Ni igba atijo won n pe gbogbo ifesi mo oksijini (O2) to mu igbona ati imole wa ni igbana. Sugbon loni a mo pe awon ohun alara miran na le fa orisi igbana. Iru awon ohun alara bayi ni Florini (F2) , Klorini (Cl2) at.bb.lo. Botiwukoje ni igba ti a ba n soro nipa igbana, lai se itumo mo ohun kankan, o tumo si igbana mo oksijini tabi afefe. Ni pataki awon igbana adapo alemin (organic compound) n sele pelu O2 tabi pelu awon ohun alara to ni oksijini bi afefe tabi baba oloksijini(II) (CuO).

The flames caused as a result of a fuel undergoing combustion (burning)


Irú ìgbaná

àtúnṣe

A le pin igbana si eyi topari ati eyi tikopari gege bi iye O2 to wa ati awon ìwàkání igba na.

  • Igbana topari je igbana to n sele pelu opo oksijini ti ko ni adapo alegbogi (chemical compound) tikojona. O soro gidi lati ni igbona topari nitoripe ko si ona kankan ti adapo alegbogi tikojona ko ni wa.
  • Igbana tabi ijona tikopari n sele ti opoiye oksijini to wa fun lilo ko to ninu ifesi alegbogi ohun. O si se e se ki iye oksijini toto o wa sugbon ona ti ijona na n sele ko gba laaye ki gbogbo oksijini ibe o se e lo.