Commonwealth Youth Council

Ìgbìmọ̀ Ọ̀dọ́ ti Commonwealth

àtúnṣe

CYC(Commonwealth Youth Council) jẹ́ onírúurú àwọn àjọ tí ó tóbi jùlọ ní àgbáyé. Àwọn olórí ìjọba ti Commonwealth ti kọ́kọ́ gba ìdásílẹ̀ ọ̀dọ́ ti Commonwealth wọlé ní agbègbè Perth ní oṣù kọkànlá ọdún 2011 kí wọn tó wá se ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ ọ̀dọ́ yi ní ọdún 2013 pẹ̀lú àtìlẹyìn ẹ̀ka ti o nrisi ètò àwọn ọ̀dọ́ Commonwealth ti Commonwealth Secretariat.[1][2]. Ìgbìmọ̀ yí nko ipa lórí ìtẹ̀síwájú àti ìdàgbàsókè àwọn ọ̀dọ́ wọ́n sì tún nse àmójútó lórí orísirísi akitiyan tí àjọ Commonwealth nse ní ẹ̀ka ti àwọn ̀ọdọ́. Ìgbìmọ̀ yí lo tun nṣiṣẹ gẹ́gẹ́ bi asojú àwọn ọ̀dọ́ laarin ojileladọrun àwọn orílẹ̀-èdè Commonwealth.[3].

Àwọn Ètò Ìmúṣẹ́ṣe ti CYC

àtúnṣe

Orísirísi àwọn ètò ìmúṣẹ́ṣe ni wón ti jíròrò ti wọ́n si ti fi ohùn ṣọ̀kan lé lórí. Àwọn bii

Ètò àwòṣe fún ọrọ̀ ajé

àtúnṣe

Àwọn ọ̀dọ́ ti Commonwealth mọ pe àìníṣẹ́ àwọn ọ̀dọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpèníjà tó ga jùlọ to nkojú àwọn orílẹ̀-èd̀e tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́. Àìníṣẹ́ jẹ́ èyí tí kò dara ní èyíkèyí ọjọ́ orí, sùgbọ́n fún àwọn ọ̀dọ́, àìníṣẹ́ ọjọ́ pípẹ́ jẹ́ ǹkan tó lápẹrẹ. Àwọn òṣìṣẹ́ àti oníṣòwò tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ nlọwọ sí ìdàgbà sókè ọrọ̀ ajé kakaakiri agbègbè Commonwealth.[4]

Ètò àwòṣe fún àyíká

àtúnṣe

Àyípadà ojú ọjọ́ ́ntẹ̀síwájú láti jẹ́ ìpèníjà pàtàkì fún àwọn orilẹ̀-èdè tí ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Commonwealth paapa fún àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ndagba tí wọ́n si ńkojú ìpèníjà ojú ọjọ́. Nípa bayi, àwọn ìgbìmọ̀ ọ̀dọ́ Commonwealth tẹnumọ́ pàtàkì ìmúgbòòrò agbára orísun àyípadà ọjó tí ó dára ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun pàtàkì ní orílẹ̀-èdè.[5]

Ètò àwòṣe fún òṣèlú

àtúnṣe

Tí a bá wo bí títóbi àgbègbè ṣe ńgbòòrò si, ó se pàtàkì fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ orílẹ̀-èdè Commonwealth láti fi àwọn ọ̀dọ́ sí ipò ti o ma mú kí ìdàgbàsókè ki o dúró ṣinṣin. A gbọ́dọ̀ mú àìní àwọn ọ̀dọ́ yi, ìlépa wọn àti ìpèníjà wọn ní òkúkúndùn. Ní pàtàkì, a gbọ́dọ̀ ṣe akitiya láti ri i dájú wípé a ka ohùn àwọn ọdọ tí a ti patì sí. Paapa bí àwọn ọ̀dọ́ ti nsise takuntakun láti mú àlàáfíà wá sí ayé. Ó se pàtàkì láti mọ wípé ìlàjà àti níní òye aṣa jẹ àwọn ipa ọ̀nà gboogi si ìṣọ̀kan àwùjọ.[6].

Ètò àwòṣe fún àwùjọ

àtúnṣe

Àwọn ọ̀dọ́ ṣe pàtàkì nínú ètò ẹ̀kọ́ sùgbọ́n nígbàgbogbo ni wọ́n kìí sábà kan sí wọn nígbàtí wọ́n ba nṣe àgbékalẹ̀, àmúṣe tàbí ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìlànà iṣẹ́ tó kàn wọ́n taara ba n wáyé. Àwọn ìlànà-iṣẹ́ ọ̀dọ́ ti orílẹ̀-èdè ni láti dáhùn sí àwọn ìpèníjà tó nkojú àwọn ọ̀dọ́, pẹ̀lú ṣíṣe àtìlẹ́hìn lórí àwọn ìṣe àti àlàyé tí ó jọmọ́ ìbálòpọ̀ àti ìlera nípa ìbísí, ìlera ti o jẹmọ́ ọpọlọ àti àwọn àrùn tí kii sabaa ran mọ ènìyàn.[7]

Ìtókasí

àtúnṣe
  1. "Commonwealth Youth Council – the most diversified youth-led organization in the world". 
  2. "Commonwealth Youth Council | the Commonwealth". Archived from the original on 2019-09-07. Retrieved 2019-11-25. 
  3. "Commonwealth Youth Council – the most diversified youth-led organization in the world". 
  4. "Commonwealth Youth Council – the most diversified youth-led organization in the world". 
  5. "Commonwealth Youth Council – the most diversified youth-led organization in the world". 
  6. "Commonwealth Youth Council – the most diversified youth-led organization in the world". 
  7. http://commonwealthyouthcouncil.com/