Cyril Nri

òṣèré, oǹkọ̀wé àti olùdarí fiimu

Cyril Ikechukwu Nri tí wọ́n bí ní ọjọ́ kaẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 1961. Jẹ́ British-Nigerian òṣèré, ònkọ̀tàn àti adarí eré tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Adam Okaro nínú eré àtìgbà-dégbà orí amóhù-máwòrán The Bill.

Cyril Nri
Cyril Nri in 2004
Ọjọ́ìbíCyril Ikechukwu Nri
25 Oṣù Kẹrin 1961 (1961-04-25) (ọmọ ọdún 63)
Nàìjíríà
Iṣẹ́Actor, writer, film director
Àwọn ọmọ2

Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Bàbá ati Ìyá Nri jẹ́ ọmọ ẹ̀yà Igbo tí wọ́n sa àsálà fún ẹ̀mí wọn ní àsìkò ogun abẹ́lé Biafra bẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdú 1968. [1] Òun àti àwọn òbí rẹ̀ kó lọ sí orílẹ̀-èdè Portugal nígbà tí no wa ní ọmọ ọdún keje, wọ́n sì tún kò lọ síLondon lẹ́yìn náà.

Nri lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Holland Park School i mm tí ó wà ní apá ìwọ̀ Oòrùn ìlú London, ibẹ̀ ni ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ń kópa nínú eré orí-ìtàgé bíi Three Penny Opera. Ó tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ The Young Vic Youth Theatre tí ó wà ní agbègbè Waterloo ní London. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ eré oníṣẹ́ ní Bristol Old Vic Theatre School. Agbègbè south London ni Nri ń gbé láti ọdún 1980s.

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré

àtúnṣe

Nri di gbajúmọ̀ látàrí ipa rẹ̀ tí ó kó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ìtàn Adam Okaro, nínú eré agbéléwò orí amóhù-máwòrán ITV tí wọ́n pe akòrí rẹ̀ níThe Bill. Ó tún kópa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ìtàn Graham níbi tí ó ti jẹ́ agbẹjọ́rò oun ati Miles ati Anna, nínú eré onípele tí wọ́n ń ṣàfihàn rẹ̀ ní orí amóhù-máwòrán BBC TV tí wọ́n pe akọ́lé rẹ̀ ní This Life.

Lẹ́yìn tí Cyril kẹ́kọ́ ìmọ̀ eré oníṣẹ́ tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí ń were jẹun níb Royal Shakespeare Company níbi tí ó ti kọ́kọ́ kópa gẹ́gẹ́ bí Lucuis nínú eré tí Ron Daiel's gbé jáde ní ọdún 1982 tí wọ́n pe akọ́lé rẹ̀ ní Julius Caesar. Ó tún kópa gẹ́gẹ́ ẹ̀dá ìtà ìtàn Ariel nínú eré The Tempest.

Ní ọdún 2008, ó tún kópa nínú eré Waking the Dead tí wọ́n ń ṣàfihàn rẹ̀ ní orí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán BBC.

Ó sì tún kópa nínú eré The ObserverRoyal National Theatre.

Ní ọdún 2009 ati 2010, ó kópa nínú eré Law & Order UK tí ó sì tún kópa nínú eré yí kan náà tí wọ́n gbé jáde ní ọdún 2012 ati ọdún 2013.

Ní inú osù kọkànlá ọdún 2010, ó tún kópa nínú ìpele kẹrin eré The Sarah Jane Adventures, "Lost in Time". Ó sì padà tún kópa nínú ibẹ̀rẹ̀ ìpín Karùn-ún eré náà ní ọdún 2011, "Sky".

Ní ọdún 2016, ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti British Academy Television Award fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ìtàn Lance nínú eré Russell T. Davies tí óbjẹ́ ọ̀kan lára eré onípele orí amóhù-máwòrán Cucumber. Ó tún kópa nínú eré Goodnight Sweetheart níbi tí ó ti kópa gẹ́gẹ́ bí Dókítà ní ilé ìwòsàn tí ìyàwó Yvonne Sparrow ti bí àbíkú.

Ó kópa nínú eré oníṣẹ́ kan tí ó jẹ́ ti ilé iṣẹ́ asọ̀rọ̀-mágbèsì BBC gbé kalẹ̀ ní ọdún 2020. Noughts and Crosses.

Ìgbé ayé rẹ̀

àtúnṣe

Nri ni ó ti ṣe ìgbéyàwó rí àmọ́ ó ti di gay báyí.[2][3] Ó ti ní àwọn ọmọ méjì tí wọ́n ti dàgbà.

Àwọn eré tí ó ti kópa

àtúnṣe

=Àwọn ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "Archived copy". Archived from the original on 2011-08-09. Retrieved 2010-09-26.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Positive Nation: Search Results". positivenation.co.uk. Archived from the original on 31 August 2011. Retrieved 16 July 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "100 Great Black Britons". 100greatblackbritons.com. Archived from the original on 3 July 2015. Retrieved 16 July 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Crims Episode Three". BBC. Retrieved 25 January 2015. 
  5. "Gordon and French: Cyril Nri". Archived from the original on 31 August 2016. Retrieved 31 August 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)

Àwọn àsopọ̀ ìta

àtúnṣe

Àdàkọ:Authority control