D'banj
Dapo Daniel Oyebanjo tí a bí ni ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹfà, ọdún 1980 ní Zaria, Ipinle Kaduna, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bíi D'banj jẹ́ akọrin àti oníṣòwò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni oludásílẹ̀ Mo' Hits Records, tí Don Jazzy jẹ́ aṣàgbéjáde orin ní ilé-iṣẹ́ náà. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ̀, díẹ̀ lára wọn ni; akorin ilè Africa tó dára jù lọ ní MTV Europe Music Awards 2007,[1] akọrin toh dára jù lọ ní ọdún 2009 ní MTV Africa Music Awards 2009,[2] òṣèré tó dára jù lọ ni àgbáyé ní 2011 BET Awards, àti akọrin ilẹ̀ Africa tó nh tà jù ní 2014 World Music Awards.
D'banj | |
---|---|
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Dapo Daniel Oyebanjo |
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíi | The Koko Master,Igwe,Skibanj |
Irú orin | R&B, African hip hop |
Occupation(s) | Singer-songwriter, instrumentalist |
Instruments | Harmonica, Singing |
Years active | 2004–present |
Labels | Mo' Hits Records |
Associated acts | Cigada of Cyprus, Mo' Hits Records, Don Jazzy, SHOLA SCOTT |
Website | Official website |
Oyebanjo mú orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ tí ń ṣe D'banj láti ara orúkọ àkọ́kọ́ rẹ̀, Dapo àti orúkọ bàbá rẹ̀, Oyebanjo. Ó di gbajúgbajà látara orin "Oliver Twist" tó kọ ní ọdún 2012.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeD'banj, tí àwọn èèyàn mọ̀ sí Kokomaster tàbí Bangalee, ni a bí ni ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹfà, ọdún 1980 ní Zaria, apá Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bàbá rẹ̀ jẹ́ ajagun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ oníṣòwò láti ìlú Shagamu, ní Ogun. D'banj ní àwọn àbúrò tó jẹ́ ìbeji, Taiwo àti Kehinde Oyebanjo.[3]
Ìbẹ̀rẹ̀ orin kíkọ
àtúnṣeFemi Oyebanjo, tí ń ṣe ẹ̀gbọ́n D'banj ló sọ D'banj di ẹni tó nífẹ̀ẹ́ orin kíkọ. Femi kú nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún nínú ọkọ̀ òfurufú kan tó já .[4] Ìfẹ́ tí D'banj ní sí orin kíkọ borí ìtakò tó dojuhkọ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Oh tiraka láti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀, ìtàn yìí wà nínú orin rẹ̀ kan All Da Way.[5]
Lẹ́yìn ikú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó mú dùrù ẹ̀gbọ́n rẹ́, ó sì máa ń lò ó láti fi kọrin ní ilé-ilwé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń wá tẹ́tí si. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ láti lọ kọ́ mechanical engineering ní Lagos State University, àmọ́ kò parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nítorí ìdaṣẹ́sílẹ̀ àwọn olùkọ́. Ó lọ sí ìlú London láti lọ parí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ibẹ̀ ló ti pàdé Don Jazzy, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ aṣógbà ní ilé-iṣẹ́ náà. Don Jazzy ràn án lọ́wọ́ láti gbé orin àkọ́kọ́ rẹ̀ "Tolongo" jáde.[6]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "D'Banj – Full Biography". MTV Base. Archived from the original on 14 July 2011. Retrieved 25 August 2010. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "MTV Africa Music Awards – Winners". MTV Base. Archived from the original on 3 January 2010. Retrieved 25 August 2010. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "KaySwitch romances Meenakshi Monica". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 31 January 2014. Retrieved 14 November 2021.
- ↑ "7. He Ironizes, He Ironizes Not, He Ironizes", Ethical Dimension of the 'Decameron', Toronto: University of Toronto Press, pp. 119–138, 31 January 2015, ISBN 978-1-4426-2575-4, doi:10.3138/9781442625754-010
- ↑ "D'Banj – Full Biography". MTV Base. Archived from the original on 14 July 2011. Retrieved 25 August 2010. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Smith, Caspar Llewellyn (23 June 2012). "I'm with D'Banj" (in en-GB). The Observer. ISSN 0029-7712. https://www.theguardian.com/music/2012/jun/23/d-banj-interview-nigerian-music-star.
blah blah blah