Duro Ladipo
Dúró Ládipọ̀ (1931–1978) jẹ́ ọ̀kan lára àwon ògúná gbòngbò olùkọ̀tàn eléré oníṣe Yorùbá tí ń dátó lẹ́nu ìgbín ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ lẹ́yìn ìmúnisìn àwọn òyìnbó. Àwọn ìwé àpilẹ̀kọ rẹ̀ dá lórí èdè Yorùbá, ̀ó kó gbogbo ohun àmúyẹ àṣà Yorùbá bí tàwọ̀n àkoni ìgbà ìwáṣè nínú ọ̀pọ̀ ìwé àpilẹ̀kọ rẹ̀, ní èyí tí ó ṣàyípadà rẹ̀ sí àwọn ohun ìgbafẹ́, àwòrán àti sinimá àgbéléwò.eré oníṣe Ọ̣ba kò so (The King did not Hang), jẹ́ ọ̀kan kàǹkà lára ìtàn akọni ìgbà ìwáṣẹ̀ tí ó ṣòro nípa bí ọba Ṣàngó ṣe di Òriṣà àkúnlẹ̀bọ, loyin-mọmọ àdò láti Nàìjíríà títí dé àwùjọ àgbáyé pàá pàá jùlọ àwùjọ ìpéjọ-pò àkọ́kọ́ 'Commonwealth Arts Festival' ní 1965 àti ní ilẹ̀ aláwọ̀ funfun pátá pátá European,níbi tí lámèyítọ́ ilẹ̀ Berlin kan, ọ̀gbẹ́ni Ulli Beier tí ṣe gbémi n gbé ọ wò láàrín Ládípọ̀ sí Karajan.[1] Ládípọ̀ sábà ma ń kópa nínú eré oníṣe rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n wo Dúró Ládípọ̀ ní ìlànà onígbàgbọ́, tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ adarí ìjọ mímọ́ ti Àgùdà (Anglican) ní Òṣogbo. Àmọ́ ṣá, ó ṣe é ṣe kí Ládípọ̀ ti já ìfun bàbá baba rẹ̀ tí ó ṣe àtìpó wá láti Òṣogbo léyìn Ogun Jálumi je. Bàbá yìí fẹ́ràn àwọn ìtàn akọni ìgbà ìwáṣẹ̀ pàá pàá jùlọ èyí tí ó bá ṣẹ̀ wá láti Ọ̀yọ́, bí ó tilè jẹ́ wípé wón mọ bàbá baba rẹ̀ mọ́ Ṣàngó àti Ọya bíbọ nígbà ayé rẹ̀.[2]
Ìrìnkèríndò iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeLádípọ̀ gbìyànjú gidi tí ó sì lààmì laaka látàrí ìgbìyànjú rẹ̀ láti tan àṣà, ìṣẹ̀se àti àkọmọ̀nà Yorùbá jákè jádò àgbáyé kódà nígbà tí ó wà ní abẹ́ àṣẹ àwọn ̀òbí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́. Nígbà èwe rẹ̀, ó ma ń yọ́ kúrò nílé láti lọ wo ìran ọdún ìbílẹ̀ Yorùbá. Ìfara-fọkàn sáṣà yí ni ó jẹ́ kí ó ma patú oríṣi ríṣi nínú eré oníṣe orí-ìtàgé àti àwọn àpilẹ̀kọ rẹ̀ lọ́kan ò jọ̀kan. Lẹ́yìn tí ó kúrò ní Òṣogbo, ó gbéra lọ sí Ìbàdàn, ní bi tí ó ti ń ṣiṣẹ́ olùkọ́. Lásìkò tó wà ní Ìbàdàn, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ tó dá ẹgbẹ́ òṣèré M̀bárí M̀báyọ̀ kalẹ̀, ní èyí tí ó sì tún ṣe ìfilọ́ọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ náà ní Òṣogbo tí ẹgbẹ́ náà sì digi àlọ́yè fún ìdàgbàsókè àti ìgbélárugẹ iṣẹ́ ọpọpọlọ àti ọpọ òṣèré ní ìlú lẹ́yìn tí ó ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwúrí láti ọ̀dọ̀ Beier, Òṣogbo. Nínú gbogbo ìgbòkè-gbodò iṣẹ́ rè yí náà ni Dúró Ládípọ̀ ti kọ ìtàn Yorùbá mẹ́wàá tí ó kún fún orin, ìlù, ijó, òwe, ìsínjẹ àti àwọn orin ìwúrí lọ́kan ò jọ̀kan.[3]
Dúró Ládípọ̀ dá ẹgbẹ́ òṣèré tirẹ̀ ka lẹ̀ ní ọdún 1961, ní èyí tó kẹ́sẹ-járí pẹ̀lú ẹgbẹ́ M̀bárí M̀báyọ̀ ní Òṣogbo. Òkìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adarí ẹgbẹ́ yìí ló ṣokùnfà àwọn eré oníṣe rẹ̀ méta kan: Ọbamoro ní 1962, Ọba kò so àti Ọbá Wàjà ní 1964. Ọbá Wàjà (The King is Dead) ni ó fẹnu sọlẹ̀ sórí ìtàn tó gún gbajú-gbajà òǹkọ̀wé eré oníṣe kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Wọlé Ṣóyínká tí ó fi kọ eré onítàn "Ikú àti Ẹlẹ́ṣin Ọba" (Death and the King's Horseman.)[4] Bákan náà ni Ládípọ̀ tún gbé eré oníṣe kan àrà òtò yọ tí ó pè níMọ́remí, eré oníṣe tó dá lórị́ bí akọni obìnrin ìgbà ìwáṣè Yorùbá kan tí ó ń jẹ́ orúkọ eré onítàn náà. Lẹ́yìn ò reyìn, Ládípọ̀ yí ẹgbẹ́ M̀bárí M̀báyò. padà sí ibi tí a ti ń kọ́ ijó ìbílẹ̀, àti ibùdó tí ọ̀pọ̀ ẹlẹ́bùn ọpọlọ ti lè pàdé pọ̀, tí wọ́n sì ti ṣàlékún ìmọ̀ wọ́n gbogbo.Láìfọ̀tá pè, Dúró Ládípọ̀ kọ àwọn ìwé àpilẹ̀kọ eré oníṣe bíi: 'Sùúrù Baba Ìwà' àti 'Tanímọwọ́ Ikú'. Bákan náà ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn àpilẹ̀kọ eré onítàn rẹ̀ ti di sinimá àgbéléwò lóde òní lórí amóhùn-máwòrán.kódà, òun ló dá ètò Bodè Wásinimi sílẹ̀ fún ilé iṣé amóhùnmáwòrán NTA (Nigerian Television Authority) ti Ìbàdàn.[5]
Ní ọdún 1977, Dúró Ládípọ̀ kópa nínú eré ìdíje ti Festac '77, ọdún ìdíje ẹlẹ́kejì irú rẹ̀ tí ó tóbi jùlọ lágbàyé tí aláwọ̀ dúdú àti funfun tí kopá tó Lààmì laaka nílù Èkó.
Àkọsílẹ̀
àtúnṣe- ↑ Ulli Beier, p.c. (1965) to Prof.
- ↑ Online, Tribune (2016-08-02). "What most people do not know about Duro Ladipo —Son". Tribune. Retrieved 2018-05-22.
- ↑ "Remembering the thunderking of theatre, Duro Ladipo". Opinion. 2017-08-02. Archived from the original on 2020-11-12. Retrieved 2018-05-22.
- ↑ Soyinka, Wole (2002). Death and the King's Horseman. W.W. Norton. p. 5. ISBN 0-393-32299-8.
- ↑ Published (2015-12-15). "With Ajagun Nla, Duro Ladipo returns to stage". Punch Newspapers. Retrieved 2018-05-22.
Àwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- Ladipọ, Duro (1972). Ọba kò so (The king did not hang) — Opera by Duro Ladipọ. (Transcribed and translated by R. G. Armstrong, Robert L. Awujọọla and Val Ọlayẹmi from a tape recording by R. Curt Wittig). Ibadan: Institute of African Studies, University of Ibadan.