Dọlápọ̀ Oṣínbàjò

Dọlápọ̀ Oṣínbàjò (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje ọdún 1967 jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti ìyàwó igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Òsínbàjò. Dọlápọ̀ jẹ́ ọmọọmọ gbajúgbajà òṣèlú àti olórí-òṣèlú àná àwọn ẹ̀yà àwọn Yorùbá, olóògbé Ọbáfẹ́mi Awolọ́wọ̀.[1]

Dọlápọ̀ Oṣínbàjò

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ bí ọkọ rẹ̀, Dọlápọ̀ jẹ́ amọ̀fin. Ó kàwé gboyè gẹ́gẹ́ bí amọ̀fin tí wọ́n fún un ìwé ẹ̀rí amọ̀fin lọ́dún 1990. Ọdún 1989 ní ó fẹ́ Igbákejì Ààrẹ, Yẹmí Òsínbàjò lọ́kọ.[2] Yàtọ̀ sí iṣẹ́ amọ̀fin, Dọlápọ̀ Òsínbàjò jẹ́ oǹkọ̀wé,[3] òun ni oǹkọ̀wé ìwé kan lédè Gẹ̀ẹ́sì tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "They Call Me Mama!"

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Dolapo Osinbajo at 52: Seven things you should know about her". The Nation Newspaper. 2019-07-16. Retrieved 2019-12-19. 
  2. "Dolapo Osinbajo: A cultural icon! - The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2019-07-10. Archived from the original on 2019-12-19. Retrieved 2019-12-19. 
  3. "Dolapo Osinbajo Biography - Age, Birthday, Parents, Awolowo - MyBioHub". MyBioHub. 2018-08-08. Retrieved 2019-12-19.