Sheikh Dahiru Usman OFR (tí wọ́n bí ní 29 June ọdún 1927) jẹ́ onímọ̀ Islam ní orílè èdè Nàìjíríà. Ó tún jé olórí ẹgbẹ́ Islamic Sufi tí àwọn ọmọ Nàìjíríà mọ̀ sí Tijaniyyah.

Ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Sheikh Dahiru Bauchi sí ilẹ̀ Ìlà oòrùn ní Gombe, ní Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ wá láti Bauchi, ní apá Ìlà oòrùn Gombe. Àwọn ẹbí ìyá rẹ̀ náà wá láti Gombe. Wọ́n bí Dahiru Bauchi ní ọdún Hijri, ní 1346 (Gregorian calendar: June 29, 1927).

Ètò èkọ́

àtúnṣe

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, Dahiru Bauchi kẹ́kọ̀ọ́ nípa Kùránì mímọ̀ lábẹ́ ìṣàkóso bàbá rẹ̀, ìyẹn Alhaji Usman. Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ náà, ó kọ́ bí a ti ń ka Kùránì lórí gẹ́gẹ́ bí i bàbá rẹ̀ náà ṣe mọ̀ ọ́. Ó kàwẹ́ lábẹ́ ìdarí àọn ọ̀jọ̀gbọ́n bí i Shaykh Tijani Usman Zangon-Bare-bari, Shaykh Abubakar Atiku àti Shaykh Abdulqadir Zaria. Ó sì gba Tijjaniyyah Tariqah. Bàbá rẹ̀ jẹ́ His Tijani muqaddam (Imam), tí wọ́n fún ní àṣẹ (ijāzah) fún tariqa. Dahiru Bauchi ni igbákeji alága ti Fatwa Committee ti Supreme Council Of Islamic Affairs (NSCIA) ní Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọdún márùndínlọ́gọ́rùn-ún (95), àmọ́ ó sì ta kébé, bí i ọ̀dọ́.[1]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Mohammed, Ahmed; Bauchi (2015-04-02). "Buhari’s victory God’s answer to prayers of Nigerians- Dahiru Bauchi". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-25. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]