Dan Archibong
Brigada Jeneral Dan Patrick Archibong[1] (4 October 1943 - 11 March 1990) je omo ogun I'll Naijiria ti o si je Gomina ijoba ologun ti Ipinle Cross River lati Osu Seere 1984 titi di 1986.[2]
Donald Etiebet ni eni ti o saaju Dan Archibong gori aleefa ni Ipinle Cross River ti Eben Ibim Princewill si gori aleefa leyin iku Dan Archibong.
A bi Dan Archibong ni ojo kerin, osu Obama, odun 1943 o si ku ni ojo kokonla, osu Erena, odun 1990 (4 October 1943 to 11 March 1990). O je omo odun merindinlaadota (46) ni igba iku re.
Dan Archibong fi aya; Arabirin Florence Dan-Archibong ati omo mefa (6) ti Arthur Javis Archibong si je okan ninu won.
Ile eko awon olugbeja ti Naijiria, NDA (Nigerian Defence Academy) ti ilu Zaria ni Ipinle Kaduna ni Dan Archibong ti k'awe gb'oye.
Ni Osu Seere odun 1964 ni NDA gba Archibong wole gege bi akeko sugbon rogbodiyan to wake ni orile ede Naijiria ni odun 1966 dii lowo lati pari eko re. O pada si NDA leyin ogun o si gba ase ni Osu Ogun, odun 1970 (August 1970).
Leyin igba ti o di Kolonel, a yan Archibong lati je Gomina ologun ti Ipinle Cross River ni Osu Seere, odun 1984 leyin iyoninipo to mu ki Jenera Muhammadu Buhari gba ijoba. Archibong je Gomina ologun Ipinle Cross River titi di odun 1986.
Archibong tun je oludari Ẹka ti awọn iwadi apapo ni Ologun Òfin ati Oṣiṣẹ Koleji ti Jaji lati ojo kerindinlogun, osu Seere, odun 1988 titi di ojo kini, osu Seere, odun 1990 (16 January 1988 to 1 January 1990) leyin igba ti o di Brigada.
O je olori osise si olori gbogbogbo ni asiko iku re. O ku ninu ijamba oko ni ojo kokonla, osu Erena, odun 1990 ni opopona Eko si Ibadan. Ko si eleri tabi awon ipalara miran, eyi ti o je ki awon iroyin atenudenu jade wipe iku re o ki n se ti ijamba rara.
Barraki Patrick Dan Archibong, Calabar ni a so leyin Dan Archibong sugbon leyin igba die, oruko re yi pada si oruko ilu.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
àtúnṣe- ↑ "Dan Archibong". Wikipedia. 2006-08-15. Retrieved 2022-02-28.
- ↑ Cahoon, Ben (1967-05-27). "Nigerian States". World Statesmen.org. Retrieved 2022-02-28.