David Datro Fofana (Wọ́n bí i lọ́jọ́ 22 Oṣù Kejìlá Ọdún 2002) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù-ṣiṣẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ivory Coast tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù fún ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-ṣiṣẹ́ Chelsea lórílẹ̀-èdè England, bẹ́ẹ̀ náà ló ń gbá bọ́ọ̀lù fún ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí orílẹ̀-èdè Ivory Coast.

Datro Fofana
Personal information
OrúkọDavid Datro Fofana
Ọjọ́ ìbí22 Oṣù Kejìlá 2002 (2002-12-22) (ọmọ ọdún 22)
Ibi ọjọ́ibíOuragahio, Ivory Coast
Ìga1.81 m
Playing positionForward
Club information
Current clubChelsea
Senior career*
YearsTeamApps(Gls)
2019–2021AFAD
2021–2022Molde42(15)
2023–Chelsea0(0)
National team
2019–Ivory Coast3(0)
* Senior club appearances and goals counted for the domestic league only and correct as of 24 October 2022.

† Appearances (Goals).

‡ National team caps and goals correct as of 16 November 2022

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù

àtúnṣe

Fofana bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù- rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ agbábọ́ọ̀lù AFAD lórílẹ̀-èdè Ivory Coast, níbẹ̀ ni àwọn aṣàwárí àwọn ọmọ ẹlẹ́bùn agbábọ́ọ̀lù láti orílẹ̀-èdè France, Belgium àti Norway fi jà fitafita láti rà á fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù-jẹ̀un wọn.[1] Lọ́jọ́ 2,oṣù kejì ọdún 2021, Fofana tọwọ́ bọ̀wẹ́ àdéhùn ọlọ́dún mẹ́rin pẹ̀lú ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-jẹ̀un tí Molde.[2] Nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ rẹ̀ àkọ́kọ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-jẹ̀un Molde nínú ìdíje UEFA Europa League, amì-ayò mẹ́ta mẹ́ta ni wọ́n gbá pẹ̀lú ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-jẹ̀un Hoffenheim lọ́jọ́ 18 oṣù kejì ọdún 2021, òun ni ó gbá amì-ayò ìkẹta ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-jẹ̀un rẹ̀ wọlé ní ìṣẹ́jú mẹ́rìnléláàádọ́rin (74).[3]

Lọ́jọ́ 28 oṣù Kejìlá ọdún 2022, wọ́n kéde pé, Fofana yóò dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-jẹ̀un Chelsea lọ́jọ́ 1 oṣù January ọdún 2023.[4]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù-díje láàárín orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè

àtúnṣe

Fofana kópa nínú ìdíje orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí Ivory Coast nínú ìdíje CHAN 2020 tí wọ́n pàdánù amì-ayò méjì sí òdo sọ́wọ́ ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-díje tí orílẹ̀-èdè Niger lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 2019 .[5]

Àwọn àtòjọ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbábọ́ọ̀lù-jẹun

àtúnṣe

Ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-jẹun

àtúnṣe

Àdàkọ:Updated[6]

Appearances and goals by club, season and competition
Ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù-jẹun Sáà Líìgì Ife-ẹ̀yẹ ti orílẹ̀-èdè Ife-ẹ̀yẹ ti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè Àpapọ̀
Líìgì àgbábuta Iye ìkópa Iye amì-ayò Iye ìkópa Iye amì-ayò Iye ìkópa Iye amì-ayò Iye ìkópa Iye amì-ayò
Molde 2021 Eliteserien 18 0 3 1 5[lower-alpha 1] 1 26 2
2022 24 15 5 3 10[lower-alpha 2] 4 39 22
Total 42 15 8 4 15 5 65 24
Chelsea 2022–23 Premier League 0 0 0 0 0 0 0 0
Career total 42 15 8 4 15 5 65 24
  1. Three appearances and one goal in UEFA Europa League, two appearances in UEFA Europa Conference League
  2. Appearances in UEFA Europa Conference League

International

àtúnṣe

Àdàkọ:Updated[7]

Appearances and goals by national team and year
National team Year Apps Goals
Ivory Coast 2022 3 0
Total 3 0

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe