Gurdeep Roy (orúko ibí rẹ̀ ni Mohinder Purba; tí a bí ní ọjọ́ kínní oṣù Kejìlá ọdún 1957), tí ọ̀pọ̀lopọ̀ mọ̀ sí Deep Roy, jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Kenya àti Britain. Nítorí pé ko ga tàrà(gíga rẹ̀ ko ju 132 centimetres (4 ft 4 in) lọ,[1] ó ma ń sábà kópa àwọn ènìyàn tí kò ga nínú àwọn eré, bí àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bi Teeny Weeny nínú The NeverEnding Story àti Oompa-Loompas nínú Charlie and the Chocolate Factory, Keenser in Star Trek, àti nínú àwọn eré bi The X-Files, Doctor Who, àti Eastbound & Down.

Deep Roy
Roy ní Florida SuperCon ti ọdún 2014
Ọjọ́ìbíMohinder Purba
1 Oṣù Kejìlá 1957 (1957-12-01) (ọmọ ọdún 67)
Nairobi, Kenya Colony
Orúkọ mírànGurdeep
Iṣẹ́
  • Òṣeré
  • stuntman
  • puppeteer
Ìgbà iṣẹ́1976–present
Heightruben aguirre is 6’7”
Olólùfẹ́
Millie Farris (m. 2014)

Nípa ayé àti Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Roy ní ọjọ́ kínní oṣù Kejìlá ọdún 1957[2]Nairobi[3] sínú ìdílé India(àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè India). Ó lọ ilé-ìwé láti kọ́ nípa ìṣirò ní London kí ó tó fi ilé ìwé sílè nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún. Ó padà lọ The Slim Wood. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré perewu ní ọdún 1976 nínú ìsòrí kẹrindínlọ́gọ́rin eré The New Avengers, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Target!", ó kópa gẹ́gẹ́ bi Klokoe. Ó ṣeré ní ọdún kan náà nínú eré The Pink Panther Strikes Again. Àwọn eré míràn tí ó ti farahàn láti ìgbà náà ni Doctor Who, Star Wars: The Empire Strikes Back, Greystoke: The Legend of Tarzan, Lord of the Apes, Planet of the Apes (2001), Big Fish (2003), Corpse Bride (2005), Charlie and the Chocolate Factory (2005).[4], The X-Files, Flash Gordon, Return to Oz (gẹ́gẹ́ bi Tin Woodman), The Dark Crystal, The NeverEnding Story, Alien from L.A., Howling VI: The Freaks, Return of the Jedi gẹ́gẹ́ bi Droopy McCool.[5], Transformers: Revenge of the Fallen (2009), Star Trek, Star Trek Into Darkness àti Star Trek Beyond àti àwọn eré míràn.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Abramovitch, Seth (25 August 2016). "Little People, Big Woes in Hollywood: Low Pay, Degrading Jobs and a Tragic Death". Hollywood Reporter. Retrieved 11 March 2023. 
  2. "Famous Birthdays". Minneapolis Star Tribune: p. A2. December 1, 2017none ; "Today's Birthdays". The Baltimore Sun: p. A9. December 1, 2014. 
  3. "Roy | Star Trek". StarTrek.com. CBS Television Distribution and CBS Interactive Inc. Retrieved 30 April 2021. 
  4. Scott, A. O. (15 July 2005). "Film review: Looking for the Candy, Finding a Back Story". The New York Times. https://movies.nytimes.com/2005/07/15/movies/15char.html. 
  5. "Deep Roy - IMDb". IMDb.com. IMDb, Inc. Retrieved 30 April 2021.