Delphine Zanga Tsogo (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kejìlá ọdún 1935, tí ó sì kú ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 2020)[1] jẹ́ òǹkọ̀wé, ajàfẹ́tọ̀ọ́-obìnrin àti olóṣèlú ilẹ̀ Cameroon. Ó ṣiṣẹ́ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Cameroon láti ọdún 1965 sí ọdún 1972. Orúkọ ìdílé ọkọ rẹ̀ ni Tsanga.[2][3]

Delphine Zanga Tsogo
Delphine Zanga Tsogo
Ọjọ́ìbí(1935-12-21)Oṣù Kejìlá 21, 1935
Lomié, British Cameroon
AláìsíJuly 16, 2020(2020-07-16) (ọmọ ọdún 84)
National Assembly Member
In office
1965–1972
ÀàrẹAhmadou Ahidjo

Ìgbésíayé rẹ̀

àtúnṣe

Ìlú Lomié ni wọ́n bi sí, ó sì kàwé ní Douala, kí ó ṣẹ̀ tó lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ nọ́ọ̀sì ní ìlú Toulouse, ní France. Ó padà lọ sí Cameroon ní ọdún 1960, láti lọ ṣiṣẹ́ nọ́ọ̀sì ní àwọn ilẹ́-ìwòsàn lóríṣiríṣi. Ní ọdún 1964, wọ́n yàn án sípò ààrẹ ìgbìmọ̀ àwọn obìnrin ilẹ̀ Cameroon. Láti ọdún 1970 wọ ọdún 1975, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i ìgbákejì mínísítà fún ètò ìlèra àti ọ̀rọ̀ àwọn ará-ìlú.[4] Láti ọdún 1975 wọ 1984, ó jẹ́ mínísítà Social Affairs fún ìlú Cameroon.[5]

Ó sìn gẹ́gẹ́ bí i ààrẹ alámòójútó ìgbìmọ̀ United Nations International Research and Training Institute for the Advancement of Women, bákan náà ni wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí i ààrẹ Comité Régional Africain de Coordination pour l’Intégration des Femmes au Développement àti igbákejì ààrẹ International Council of Women. Wọ́n fi orúkọ rẹ̀ sọ National Order of Merit ti ìlú Faranse.[6]

Ní ọdún 1983, ó kọ ìtàn-àròsọ àkọ́kọ́ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Vies de Femmes (Ìgbésí ayé àwọn obìnrin). Lẹ́yìn náà ni ó kọ L'Oiseau en cage (Ẹyẹ inú àgọ̀) ní ọdún tó tẹ̀le.[7]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Nécrologie : Delphine Tsanga n’est plus Àdàkọ:In lang
  2. "Delphine Zanga Tsogo". University of Western Australia. 
  3. "Mme Tsanga Delphine". Elections Cameroon. Archived from the original on 2015-08-01. Retrieved 2015-02-18.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named bio
  5. "Mme Tsanga Delphine". Elections Cameroon. Archived from the original on 2015-08-01. Retrieved 2015-02-18.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named elections3
  7. Gikandi, Simon (2003). Encyclopedia of African Literature. Routledge. pp. 815–16. ISBN 1134582234. https://books.google.com/books?id=hKmCAgAAQBAJ&pg=PA815.