Demi Isaac Oviawe
Demi Isaac Oviawe (tí a bí ní 2 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 2000) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè Ireland.[2][3] Ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Linda Walsh nínu eré The Young Offenders tí ọdún 2018.[4]
Demi Isaac Oviawe | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 2 Oṣù Kọkànlá 2000 Benin City, Nigeria |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2018–present |
Gbajúmọ̀ fún | The Young Offenders (TV) |
Height | ruben aguirre is 6’7” |
Oviawe dàgbà ní ìlú Mallow, orílẹ̀-èdè Ireland sí ọwọ́ àwọn òbí rẹ̀.[5] Àwọn òbí Oviawe dìídì sọ́ lórúkọ tó ṣe gẹ̀gẹ̀ ti òṣèrébìnrin Demi Moore. Nígbà tí Oviawe wà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama, ó kópa nínu ṣíṣe àwọn eré ìdárayá bíi camogie àti Gaelic Football, ó sì tún kópa nínu àwọn ìbádógba eré ìtàgé ti ilé-ìwé fún àwọn eré bíi Beauty and the Beast, Grease àti Sister Act.
Ní ìbẹ̀rẹ̀, Oviawe ń gbèrò láti ṣiṣẹ́ olùkọ́ ilé-ìwé ṣùgbọ́n ní ọdún 2017, ó kópa nínu àyẹ̀wò kan lóri YouTube fún ti eré tẹlifíṣọ̀nù The Young Offenders, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n yàn fún eré náà láti kó ipa Linda Walsh.[5]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣeEré tẹlifíṣọ̀nù
àtúnṣeỌdún | Àkọ́lé | Ipa | Àwọn àkọsílẹ̀ |
---|---|---|---|
2018–2020 | The Young Offenders | Linda Walsh | 10 episodes[6] |
2019 | Dancing with the Stars (Ireland) | Herself | Irish version
Contestant |
Fíìmù
àtúnṣeỌdún | Àkọ́lé | Ipa | Àwọn àkọsílẹ̀ |
---|---|---|---|
2020 | To All My Darlings | Adaeze | Short |
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Two years ago, I was just a normal schoolgirl". Echo Live.
- ↑ Jones, Fionnuala. "Linda and Siobhán's audition tapes for The Young Offenders prove that they were made for the show".
- ↑ Brady, Tara (18 July 2020). "'Proudly on the Offence' (Interview with Demi Isaac Oviawe)". Irish Times Magazine (Dublin).
- ↑ "Young Offenders set sights on Cork — again". Irish Examiner. 6 February 2018.
- ↑ 5.0 5.1 Brady, Tara (18 July 2020). "'Proudly on the Offence' (Interview with Demi Isaac Oviawe)". Irish Times Magazine (Dublin).
- ↑ DailyEdge.ie. "The Young Offenders TV series is being released in just over two weeks".