Derek William Bentley (30 Osu kefa Ọdun 1933 – 28 Oṣu Kini Ọdun 1953) jẹ ọkunrin ara ilu Gẹẹsi kan ti a pa nipa siso o ro titi emi fi bo ni enu re fun ipaniyan ọlọpa kan lakoko igbiyanju idigun jale kan. Christopher Craig, ẹni ọdun mokan din l'ogun ti o je ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ Bentley, ni a fi ẹsun ipaniyan naa kan. Bentley fi idi re mule wipe Bentley jẹbi ẹsun kikopa ninu itapa si ofin naa, nipasẹ ilana ofin kan ninu iwe ofin ile Gẹẹsi ti a mo si “ ifọwọsowọpọ ”, nitori wipe iwa idigun jale yi ni a se pelu isokan. Idajo naa ko wa ni isokan.

Awọn igbimo idajo ti a gbe kale fi idi re mule wipe Bentley jẹbi esun ti a fi kann lori itumo ti agbejoro ijoba fun oro kan ti Bentley so wipe "Jẹ ki o gbaa" (iyanju ti Bentley fun Craig), ti a ko si le fi itumo re lele ni pato tabi idaniloju leyin ti onidajọ.Oloye Goddard, ti ṣe apejuwe Bentley gẹgẹbi "eni ti o se iranlọwọ ọpọlọ ninu ipaniyan Sidney Miles".Goddard ṣe idajọ iku fun Bentley nipa siso ro titi ti emi yi o fi bo ni enu re lai bikita fun idirebe awon igbimo idajo lati dari ji arakunrin naa: Labẹ Idajọ ti Ofin Iku 1823, ko si idajo miiran ti o ṣee ṣe (biotilejepe Ofin ipaniyan 1957, eyiti o ṣafihan awọn aabo ojuse ti o din(biotilejepe Ofin ipaniyan 1957, eyiti o ṣafihan awọn aabo ojuse ti o dinku ti o lagbara, ti fẹrẹẹ jẹ ipa nipasẹ ejo Bentley yi).

Ẹjọ Bentley yi di mimo kaakiri ilu ti o fi je wipe o yori si ipolongo ọdun marun din laadota lati gba idariji fun Derek Bentley lẹhin iku re, eyiti o di sise ni ọdun 1993, pelu ipolongo lati pa ejo iku ti pa ejo iku ti a da fun rẹ, eyiti o waye ni ọdun 1998. Nitoribẹẹ ọran rẹ yi ni a ka si ọran ti ilodi si idajọ pelu ejo ti Timothy Evans, eyi ti o si je idi kan pataki ninu aṣeyọri ipolongo lati fopin si ijiya iku ni ile Geesi .

Ibere Igbesi aye re

àtúnṣe

Derek Bentley wo ile iwe Norbury Manor Secondary Modern School ni odun 1944.leyin igba ti o ti idi r'emi ninu idanwo awon omo odun mokanla soke. Ki o to pari ninu osu March,odun 1948,Bentley ati omodekunrin kan ni a awon olopa fi kele ofin gbe fun esun ole. Leyin osu mefa, a da won lejo lati lo se ewon odun meta ni Kingswood Approved School,leba Bristol.Christopher Craig naa je akeko ni ile iwe Secondary Modern school yi.

Ilera ati idagbasoke ti opolo

àtúnṣe

Derek Bentley ni opolopo awọn iṣoro idagbasoke ilera. Awọn obi rẹ royin wipe ninu ijamba kekere kan ni o ti fọ imu rẹ ati wipe lati naa naa o ni ijagba mẹta, okan ninu eyiti wọn sọ pe o fẹrẹ gba emi re. Ebi naa tun sọ wipe emeta otooto ni a fi ado oloro le won jade lakoko Ogun Agbaye II, ati wipe ninu ọkan ninu awọn iṣẹlẹ wọnyi, ile ti o ngbe wó moo lori, ṣugbọn ile-ẹjọ ko rii itọkasi kanka wipe o fi ara pa naa. [1] :102

A ran Bentley lo si Ile-iwe Ikẹkọ Kingwood, Bristol ni ọjọ keta din logbon, Oṣu Kẹwa Ọdun 1948. Wọ́n ṣe àyẹ̀wò fún un ní asiko to fi í s'ẹ́wọ̀n níbẹ̀. Ni Oṣu Kejila ọdun 1948 (nigbati o jẹ ọmọ ọdun Meedogun ati abo), ọjọ ori ọpọlọ rẹ ni koju ti omo ọdun mewa ati oṣu mẹrin lo, nigbati o gba 66 ninu opolo kan. Awọn oṣiṣẹ Kingwood royin pe o jẹ “ọlẹ, alaibikita, olufokansi ati ti iru 'alarekereke eniyan'”, ti ile-ẹjọ si ṣe apejuwe rẹ gẹgẹbi “alaibikita, eni ti nkan ko jo loju, ati eni ti o setan lati sọ awọn itan”. Lẹhin igba i a fi kele ofin gbe ni Oṣu kọkanla ọdun 1952, a tun se awọn idanwo opolo fun u ni ogba ewọn Brixton . Ibi ni a ti se apejuwe re geg bi "eni ti ko ni oye", ti o si ni akosile 71 ninu oro siso,87 ninu ise sise ati akojopo akosile ninu idanwo opolo ti o je 77.

A ṣe awari pe o tun jẹ “ alaimọwe pupọ” ni akoko ti a munn ni Oṣu kọkanla ọdun 1952. Awon oṣiṣẹ ilera ninu ogba ewon sọ wipe “ko le ṣe idanimọ tabi kọ gbogbo awọn lẹta ti alfabeti silẹ”.

  1. Murder in Cold Blood ISBN 1-871-61216-0