Didi Akinyelure

Akọ̀ròyìn ní Nàìjíríà

Didi Akinyelure jẹ́ akọ̀ròyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Britain tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi. University of Nottingham ní ó ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde lórí Chemical Engineering. Ní oṣù keje ọdún 2016, ó gba àmì-ẹ̀yẹ BBC World News Komla Dumor.[1][2][3] Ní ọdún 2016 bákan náà, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Special Excellence Alumni Laureate ti University of Nottingham. Didi ni wọ́n lò fún ojú CNBC Africa's live morning show Open Exchange ti West Africa.[4]

Didi Akinyelure
Orílẹ̀-èdèBritish/Nigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaNottingham University
Iṣẹ́Journalist
Ìgbà iṣẹ́2011-present
Olólùfẹ́Akin Akinyelure
Àwọn ọmọ2
AwardsBBC World News Komla Dumor Award 2016, University of Nottingham Special Excellence Alumni Laureate Award 2018

Ètò-èkó àti iṣẹ́ tó yàn láàyò

àtúnṣe

Didi jẹ́ akọ̀ròyìn tó ti ní ọ̀pọ̀ ìrírí látàrí iṣẹ́ ṣíṣe rẹ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ìgbéròyìn jáde lóríṣiríṣi.[5]   Ó ṣatọ́kùn ètò CNBC Europe tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ ‘I.O.T: Powering the Digital Economy’ àti BBC World Service tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ ‘Living on the Edge’.[6][7][8]


Ó ti ṣiṣẹ́ atọ́kùn, olóòtú, àti àtúnkọ ìròyìn lórí rédíò àti tẹlifíṣọ́ọ̀nù fún ìròyìn lórí BBC News lágo mẹ́wàá, BBC World News, BBC World Service, BBC Focus on Africa, BBC Business Daily, BBC Newsday, àti BBC Radio 4.[9]

Iṣẹ́ rẹ̀ lórí ètò ìṣòwò fún obìnrin wà lára iṣẹ́ tí World Bank yàn fún àmì-ẹ̀yẹ Women Entrepreneurship reporting category ni One World Media lọ́dún 2018.[10]

Ó ti hàn lórí Forbes Africa Magazine, ó sì wà lára àwọn akọ̀ròyìn lóbìnrin tó lọ́lá jù lọ lágbàáyé. 

Ó jẹ́ oníṣòwò ẹ̀rọ ìgbéròyìn jáde látàrí ètò orí afẹ́fẹ́ A Place in Africa tó dá sílẹ̀. Ó tún ṣagbátẹrù REAP, ètò kan lórí ẹ̀rọ ìgbéròyìn jáde. Didi ń ṣiṣẹ́ ribiribi nínú iṣẹ́ tó yàn láàyò gẹ́gẹ́ bíi olóòtú àti adarí ètò láyẹyẹ. Ní oṣù karùn-ún ọdún 2019, ó ṣagbátẹrù ètò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn èèyàn ńláńlá ní United Nations ní Geneva. Lára àwọn ìgbìmọ̀ aṣèdájọ́ náà ni Dame Wendy Hall,  Nobel Laureate, Prof. Carlo Rubbia àti Prof. Jurgen Schmidhuber. Ní ọdún 2018, ó ṣagbátẹrù ètò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí United Nations pẹ̀lú Sir Roger Penrose àti Nobel Laureate Jacques Dubochet.

Ó tún jẹ́ olóòtú ètò Africa CEO forum àti olóòtú fún ayẹyẹ Africa CEO awards and gala dinner. Ó ṣagbátẹrù ètò kan lórí òwò ṣíṣe ní London Business School fún Africa Summit, àti Future Energy Africa exhibition and conference ní Cape Town, South Africa. Ó dárí ètò BBC Africa Debate on Fake News ní Malawi àti The BBC Women in Digital Journalism panel fún ayẹyẹ ọ̀sẹ̀ ìgbéròyìn jáde lórí ayélujára ní ìpínlẹ̀ Èkó.[11]

Ó tún ṣolóòtú Africa Summit fún University of Nottingham, The Future Energy Exhibition and Conference, The West Africa Property Investment Summit, The ‘Lagos at 50’ International Conference àti The Lagos Kano Economic Summit.

Ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2017, United Nations pe Didi láti ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn èèyàn ní UN Convention to Combat Desertification ní Ordos ìlú China.

Didi ti ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olóṣèlú ńláǹlà àti adarí iṣẹ́ lóríṣiríṣi.

Kó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ̀ròyìn, ó ti ṣiṣẹ́ ní Barclays Wealth ní ìlú London.[12][13]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Editor. "Didi Akinyelure: Driven by dreams". The Guardian. Archived from the original on 6 August 2016. Retrieved 6 August 2016. 
  2. PeoplePill. "Didi Akinyelure: Nigerian journalist - Biography and Life". PeoplePill. Retrieved 2020-05-03. 
  3. "Didi Akinyelure’s Biography". Muck Rack. Retrieved 2020-05-03. 
  4. "Nigeria’s Didi Akinyelure wins BBC World News Komla Dumor Award", Bella Naija, 19 July 2016.
  5. "Your favorite newspapers and magazines.". PressReader.com. 2018-01-27. Retrieved 2020-05-03. 
  6. "BBC - Didi Akinyelure Awarded the Second BBC World News Komla Dumor Award - Media Centre". www.bbc.co.uk. Retrieved 30 July 2016. 
  7. "Komla Dumor Award winner in her own words". BBC News. 2016-07-19. Retrieved 2020-05-03. 
  8. "How BBC Komla Dumor award change my level - Didi Akinyelure". BBC News Pidgin. 2019-02-05. Retrieved 2020-05-03. 
  9. "Nigerian journalist Didi Akinyelure wins Komla Dumor Award", Focus on Africa, BBC World Service, 19 July 2016.
  10. "Be Inspired! CNBC Africa’s Entrepreneur of the Week Show Features Inspiring Nigerian Women in Business", Bella Naija, 17 April 2016}}
  11. "About Didi". www.didiakin.com. Retrieved 27 July 2018. 
  12. "Who is Komla Dumor Award winner Didi Akinyelure? - BBC News". BBC News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 30 July 2016. 
  13. "Didi Akinyelure biography, net worth, age, family, contact & picture". Nigeria Business Directory - Find Companies, People & Places in Nigeria. 2010-07-10. Retrieved 2020-05-03.