Djaili Amadou Amal
Djaili Amadou Amal jẹ́ òǹkọ̀wé àti ajà-fẹ́tọ̀ọ́-obìnrin ti orílẹ̀-èdè Cameroon.
Djaili Amadou Amal | |
---|---|
Djaili Amadou Amal ní ayẹyẹ Atlantide Festival, ní Nantes, ní ọdún 2021 | |
Ọjọ́ ìbí | 1975 Diamare, Cameroon |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Cameroonian |
Ayé rẹ̀
àtúnṣeDjaili Amadou Amal jẹ́ ọmọ ẹ̀yà Fula, tó jẹ́ ìbílẹ̀ sí Diamare ní Far North Region (Cameroon). Ó dàgbà sí olú-ìlú náà, ìyẹn Maroua. Ó kọ̀wé nípa àṣà Fulbe àti àwọn ìṣòro tí ó ń kojú wọn, èyí tó jẹ́ ti ìgbàlódé àti àwọn èyí tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Iṣẹ́ rẹ̀ tako ìṣòro tí ó ń dójú kọ àwọn obìnrin Fulani, àti àwọn ìṣòro tó ń dójú kọ wọ́n ní agbègbè rẹ̀, ìyẹn Sahel, pàápàá jù lọ ẹlẹ́yàmẹyà tó ń dé bá àwọn obìnrin náà. Lára àwọn ìwé rẹ̀ ni Walaande, tí ó jẹ́ ọ̀rọ̀ Fulfulde fún ìsopọ̀, tó sì dá lórí ọ̀rọ̀ níní ìyàwó púpọ̀ láàárín àwọn ará Fulani, nítorí ìṣe yìí wọ́pọ̀ láàárín wọn.[1] Walaande sọ̀rọ̀ nípa ìtàn ìyàwó mẹ́rin tí wọ́n ti gbà láti "jọ pín ọkọ kan".[2]
Méjì nínú àwọn ìwé rẹ̀ mìíràn ni Mistiriijo àti La Mangeuse d'âmes. Ó máa ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé rẹ̀ pẹ̀lú èdè French.[1][2]
Ìdánimọ̀
àtúnṣeNí ọjọ́ kejì oṣù kejìlá ọdún 2020, ìwé Djaïli Amadou ìyẹn Les Impatientes gbé ipò kẹtàlélọ́gbọ̀n (33rd) ní French Literary award, Prix Goncourt des Lycéens, gẹ́gẹ́ bíi òǹkọ̀wé-bìnrin ti ilẹ̀ Africa àkọ́kọ́ tó máa dé ìdíje àṣekágbá ti àwọn ìwé lítíréṣọ̀.[3] Wọ́n tún yan ìwé náà gẹ́gẹ́ bíi Choix Goncourt de l'Orient ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kejìlá ọdún 2020,[4] the Choix Goncourt UK[5] ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta ọdún 2021, àti Choix Goncourt Tunisia ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹrin ọdún 2021. Ògbufọ̀ German fún àkọ́lé náà ni wọ́n yàn ní oṣù kẹta ọdún 2023 fún àmì-ẹ̀yẹ tí wọ́n máa gbà ní oṣù kẹwàá, láti ọwọ́ Deutscher Jugendliteraturpreis.[6]
Ní Cameroon lóhùn ún, àjọ UNICEF yan òǹkọ̀wé yìí gẹ́gẹ́ bíi Goodwill Ambassador ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹta ọdún 2021 [7] láti ṣàtìlẹyìn ẹgbẹ́ náà nínú ètò ṣíṣe alágbàwí fún ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé.
Àtòjọ àwọn ìwé rẹ̀
àtúnṣe- Walaande, l'art de partager un mari, éditions Ifrikiya, Yaoundé, 2010, 134 p., ISBN 9956-473-35-9[8]
- Mistiriijo, la mangeuse d'âmes, éditions Ifrikiya, Yaoundé, 2013, ISBN 978-9956-473-85-4[9]
- Munyal, les larmes de la patience, éditions Proximité, Yaoundé, 2017 ISBN 978-9956-429-54-7
- Les Impatientes, éditions Emmanuelle Collas, Paris, 2020, 252p., ISBN 978-2-490155-25-5 – prix Goncourt des lycéens 2020.[10]
- Cœur du Sahel, Paris, Emmanuelle Collas, 2022, 364 p
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Louabalbé, Prospère. "Djaili Amadou Amal, la voix des femmes sans voix". Le Septentrion. Archived from the original on 1 February 2014. Retrieved 27 January 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ 2.0 2.1 Thierry, Raphaël. "Walaande, l'art de partager un mari". Africultures. Retrieved 27 January 2014.
- ↑ "Cameroon’s Djaïli Amadou Amal Wins Prestigious French Literary Award". Africanews. February 12, 2020.
- ↑ "Le Choix Goncourt de l’Orient aux " Impatientes " de Djaïli Amadou Amal".
- ↑ Lamnaouer, Leila (March 19, 2021). "L'auteure camerounaise Djaïli Amadou Amal remporte le Choix Goncourt UK".
- ↑ "Deutscher Jugendliteratur Preis 2023 Nominierungen" (PDF). Arbeitskreis für Jugendliteratur. Retrieved 2023-03-23.
- ↑ "Cameroon:Award-winning writer Amadou Djaili appointed". March 8, 2021.
- ↑ Présentation de Walaande
- ↑ Présentation de Mistiriijo la mangeuse d'âmes
- ↑ Raphaëlle Leyris (2 December 2020). "Djaïli Amadou Amal récompensée du prix Goncourt des lycéens pour Les Impatientes". Le Monde. https://www.lemonde.fr/culture/article/2020/12/02/le-prix-goncourt-des-lyceens-recompense-djaili-amadou-amal-pour-les-impatientes_6061932_3246.html.