Dora Francisca Edu-Buandoh
Francisca Dora Edu-Buandoh jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́nbìnrin ti èdẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó wá láti orílẹ̀-èdè Ghana, tó sì tún jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tó di ipò Vice-Chancellor ti University of Cape Coast mú.[1][2][3][4][5] Wọ́n yàn án sípò ní ìpàdé ìkọkọ̀ndínlọ́gọ́rùn-ún (99th) ti àwọn ìgbìmọ̀ ìṣèjọba ti UCC, tó wáyé ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kọkànlá, ọdún 2018.[6][7] Lẹ́yìn tí Ọ̀jọ̀gbọ́n George K.T Oduro kúrò lórí ipò náà ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, ọdún 2018, ni ó gún orí ipò yìí.[8][9]
Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeỌ̀jọ̀gbọ́n Dora Edu-Buandoh gba oyè PhD láti University of Iowa, USA, MPhil àti Bachelor's degree nínú ẹ̀kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní University of Caoe Coast. Bákan náà ni ó gba ìwé-ẹ̀rí láti kọ́ èdẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sí àwọn tó ń kọ́ èdè náà gẹ́gẹ́ bí èdè àkọ́kúntẹnu ti (TESOL) láti University of Wisconsin, ní Madison, USA. Yàtọ̀ sí èyí, ó jẹ́ olùkọ́ akọ́ṣẹ́mọsẹ́, láti Komenda Training College, tó jáde pẹ̀lú 'A' tó jẹ́ èsì ìdánwò tó dára lọ́pọ̀lọpọ̀[10] ó tún gba oyè Diploma nínú ètò ẹ̀kọ́ láti University of Cape Coast. Ó kópa níní èkọ́ ti DAAD gbé kalẹ̀ láti lọ ní ìmọ̀ kún ìmọ̀ nínú Higher Education Management, ní Galilee International Management Institute. [11]
Iṣé tó yàn láàyò
àtúnṣeÒun ni Vice Chancellor University of Cape Coast lọ́wọ́lọ́wọ́. Láti ọdún 2016 wọ ọdún 2018, òun ni Provost ti College of Humanities and Legal Studies.[12] [13] Iṣé ìṣakóso rẹ̀ ní ṣe pẹ̀lú ìdá mẹ́ta nínú iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti ìdá ọgbọ̀n nínú iye àwọn ènìyàn ní ẹ̀ka tó ń rí sí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní University of Cape Coast. Ó ṣe ìdásílẹ̀ ètò àkọ́kọ́ tó dá lórí ilé-iṣẹ́ àti ilé-ẹ̀kọ́ tó sì la ojú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí àwọn ilé-iṣé tó wà ní àwùjọ bí i epo rọ̀bì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sì tún ṣètò iṣẹ́-ìwádìí fún GNPC, tí wọ́n lo mílíọ́ọ̀nù kan dọ́là fún ìṣàkóso epo rọ̀bì. Bákan náà ni ó ṣe akitiyan láti ṣe ìdásílẹ̀ ẹ̀ka Institute for Law and Governance ní ilé-ẹ̀kọ́ náà.[14]
Iṣẹ́-ìwádìí
àtúnṣeỌ̀jọ̀gbọ́n Edu-Buandoh ṣojú dé English Linguistics, English Language, Literacy nínú ẹ̀ka ẹ̀kọ́ rẹ̀, ìwádìí rẹ̀ sì dá lórí Discourse Studies, Multilingualism, Language àti Ideology pẹ̀lú Literacy.[15][16][17]
Ìgbésí ayé ara ẹni
àtúnṣeÓ ní ọmọkùnrin kan, ọmọ-ọmọbìnrin mẹ́ta àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ tó gbà tọ́.
Àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
àtúnṣeProfessor Edu-Buandoh ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ bíi ti T. Anne Cleary International Dissertation láti ọwọ́ University of Iowa, Fulbright Award láti ọwọ́ United States Government, Government of Ghana Scholarship, Graduate Fellowship láti Ohio University, AILA Solidarity Award láti ọwọ́ Association Internationale de Linguistique Appliquée (International Association of Applied Linguistics) àti Alpha Delta Kappa International Women Educators Award.[18]
Ìfitọrẹ
àtúnṣeÓ ṣe ìpèsè shopping vouchers, àti àwọn ohun èlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti University of Cape Coast, nítorí àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19.[19]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Frimpong, Enoch Darfah (23 November 2018). "Prof Dora Francisca Edu-Buandoh appointed UCC Pro V-C". Graphic Online. Retrieved 6 April 2024.
- ↑ Online, Peace FM. "Prof Dora Francisca Edu-Buandoh Appointed UCC Pro V-C". Peacefmonline.com - Ghana news. Archived from the original on 2023-01-26. Retrieved 2024-04-06.
- ↑ "UCC Appoints Prof. Dora F. Edu-Buandoh As Pro-Vice-Chancellor". November 29, 2018. Archived from the original on February 3, 2023. Retrieved April 19, 2024.
- ↑ Coast, University of Cape (2019-05-29), UCC11TH-13THOF51ST-18, retrieved 2021-03-24
- ↑ "Help plan future of staff-UCC Pro VC". Ghanaian Times (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-08-02. Retrieved 2021-03-24.
- ↑ "Prof Dora Francisca Edu-Buandoh now UCC Pro V-C". Prime News Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-11-24. Retrieved 2021-03-24.
- ↑ "UCC Council appoints Prof. Edu-Buandoh as Pro Vice Chancellor". GhanaWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-11-23. Retrieved 2021-03-24.
- ↑ Effah, Steven (2018-11-23). "UCC Council appoints Prof. Edu-Buandoh as Pro Vice Chancellor". 3news (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-03-24.
- ↑ "UCC Appoints Prof. Dora F. Edu-Buandoh As Pro-Vice-Chancellor Archives". 2021/2022 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2023-02-03. Retrieved 2021-03-24.
- ↑ "COVID-19: Use innovative ways for higher education— Prof. Dora Edu-Buandoh". Graphic Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-03-24.
- ↑ "DORA FRANCISCA EDU-BUANDOH, PhD". May 20, 2017.
- ↑ "myghanalinks - Prof Dora Francisca Edu-Buandoh appointed UCC Pro V-C". www.myghanalinks.com.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ "Staff Directory | University of Cape Coast".[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Edu-Buandoh, Dora F. (January 2010). "Discourse in Institutional Administration of Public Universities in Ghana: A Shift towards a Market Paradigm?" – via ResearchGate.
- ↑ "Dora Francisca Edu-Buandoh | Semantic Scholar". www.semanticscholar.org.
- ↑ Edu-Buandoh, Dora Francisca (October 16, 2006). "Mulitilingualism in Ghana: An Ethnographic Study of College Students at the University of Cape Coast". University of Iowa – via Google Books.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedauto
- ↑ Agency, Ghana News (2020-05-06). "COVID 19: UCC supports its international students with shopping vouchers". News Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-03-24.