Doris Simeon

Òṣéré orí ìtàgé

Doris Simeon jẹ́ òṣèré fíìmù èdè gẹ̀ẹ́sì àti yorùbá ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Edo ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Simeon si Ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí PEFT Institute níbi tí ó ti gboyè nínú ìmò Production Management.

Iṣẹ́

àtúnṣe

Ó kópa nínú eré ẹ̀fẹ̀ ti Papa Ajasco.[1] Ní ọdún 2010, ó farahàn nínú eré Ghetto Dreamz gẹ́gẹ́ bí olólùfẹ́ Da Grin.[2][3] Ó ti kópa nínú orísìírísìí àwọn eré bíi Oloju Ede, Alakada, Ten Million Naira , Modupe Temi àti Eti Keta.[4] Yàtọ̀ sí eré ṣíṣe, Simeon má ń ṣe alága ìdúró àti atọ́kùn ètò lórí tẹlẹfíṣọ̀nù.

Ẹ̀bùn

àtúnṣe

Ó gbà àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèré ìbílẹ̀ tó dára jù lọ láti ọ̀dọ̀ AMAA ní ọdún 2008.[5] Ní ọdún 2010, ó gbà àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèré ìbílẹ̀ tó dára jù lọ láti ọ̀dọ̀ Zafaa Award fún ipá tí ó kó nínú eré Àṣírí.[6] [7]Àwọn àmì ẹ̀yẹ tí ó tún ti gbà ní Award for excellence láti ọ̀dọ̀ Okpella Movement ní ilẹ̀ United States, Best indigenous artist láti ọ̀dọ̀ Afemiah Development Group àti 2015 All Youths Tush Awards AYTA Role Model (Movie) Award.[8]

Ìgbéyàwó

àtúnṣe

Ó fẹ́ Daniel Ademinokan, wọ́n sì bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ David.[9] Òun àti ọkọ rẹ̀ pínyà ni oṣù karùn-ún ọdún 2013.[10]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Adeola Balogun (9 August 2008). "I regret dating Yomi Ogunmola". The Punch. Archived from the original on 17 September 2008. https://web.archive.org/web/20080917170917/http://www.punchng.com/Articl.aspx?theartic=Art200808092122215. Retrieved 26 March 2011. 
  2. "My Experience As Dagrin's Girlfriend - Doris Simon". allafrica.com. 4 March 2011. Retrieved 26 March 2011. 
  3. "Doris Simeon to Star in Ghetto Dreamz". allafrica.com. 20 February 2011. http://allafrica.com/stories/201102210981.html. Retrieved 26 March 2011. 
  4. Jayne Usen (29 January 2011). "Kate Henshaw, the ‘Third Party' and I". next. Archived from the original on 8 April 2011. Retrieved 26 March 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "My wife is sexy says Ademinokan". Vanguard. 5 September 2009. http://www.vanguardngr.com/2009/09/my-wife-is-sexy-says-ademinokan/. Retrieved 26 March 2011. 
  6. "Zafaa Award Winners 2010". African film and Television arts. Archived from the original on 2016-03-04. Retrieved 2020-11-06. 
  7. "Nadia Buari, Majid Michel & Co Nominated For African Films Festival And Academy Awards 2010". Ghanaweb. 25 September 2010. Retrieved 26 March 2011. 
  8. "Seyi Law, Doris Simeon, Jaywon & More Grace TUSH Awards 2015" (in en-US). SecureNigeria365. 2015-12-10. Archived from the original on 2018-09-17. https://web.archive.org/web/20180917143312/http://www.securenigeria365.com/seyi-law-doris-simeon-jaywon-more-grace-tush-awards-2015/. 
  9. Aramide Pius. "Why my life is scandal free - Doris Simeon". nigeriafilms.com. Archived from the original on 4 February 2011. https://web.archive.org/web/20110204172241/http://www.nigeriafilms.com/news/9955/9/why-my-life-is-scandal-free-doris-simeon.html. Retrieved 26 March 2011. 
  10. ""My Ex-Wife Was Sleeping Around With Different Men" – Daniel Ademinokan Bombs Doris Simeon". Pulse NG. 10 December 2017. Archived from the original on 7 May 2018. https://web.archive.org/web/20180507003238/http://www.pulse.ng/entertainment/movies/messy-divorce-my-ex-wife-was-sleeping-around-with-different-men-daniel-ademinokan-bombs-doris-simeon-id2569604.html. Retrieved 6 May 2018.