Dufuna Canoe jẹ́ ọkọ̀ ojú-omi kékeré kan tí a ṣe àwárí i rẹ̀ ní ọdún 1987 látipasẹ̀ Fulani darandaran màálù kan ní ibùsọ̀ díẹ̀ si abúlé ti Dufuna ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Fune èyí tí kò jìnnà sí odò Komadugu Gana, ni Ipinle Yobe, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ Radiocarbon ti àpẹẹrẹ èédú tí wọ́n ṣe àwárí ní agbègbè ná à ni ọkọ̀ ojú-omi kékeré kan tí ọdún rẹ ẹ̀ tó 8,500 sí ọdún 8,000, èyí tí ó sì sọ agbègbè náà pọ̀ mọ́ Ilẹ̀ Lake Mega Chad.[3] Ọkọ̀ yí gùn tó ìwọ̀n mẹ́jọ (èyí tí í ṣe ìwọ̀n ẹsẹ̀ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n) 8 metres (26 ft) ní gígùn[4]

Ìbẹ̀rẹ̀ àtúnṣe

Ọkọ̀ Dufuna ni wọ́n ṣe àwárí i rẹ̀ ní abúlé Dufuna tí ó wà ní àárín Potiskum àti Gashua ní Ipinle Yobe.[5] Ní ọjọ́ kẹrin oṣù karùn ún ọdún 1987, Fulani darandaran kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mallam Ya'u ṣe àwárí ohun líle kan tí ìwọ̀n rẹ tó 4.5 meter ní ibi tí ó ti ń wa kànga kan. Fulani yi sọ fún olórí abúlé rẹ nígbà tí ó ṣe àwárí yi.

Ní ọdún 1989 àti ọdún 1990, ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Maiduguri ṣe ìsàwárí àkọ́kọ́ ní agbègbè yí láti lè ri i dájú bóyá ǹ kan yì í jẹ́ ọkọ̀ ojú-omi kékeré kan nípasẹ̀ ṣíṣe àwọn àyẹ̀wò igi yì í. Lẹhinna, látipasẹ̀ iṣẹ́ àkànṣe ìwádì àpapọ̀ ti Yunifásítì ti Frankfurt àti ti Maiduguri ṣe agbátẹrù rẹ látipasẹ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Peter Breuning àti Garba Abubakar tí wọ́n padà lọ sí agbègbè yí láti tẹ̀síwájú ní ṣíṣe àwọn àyẹ̀wò igi yì í ní àwọn ilé àyèwò méjì tí ó jẹ ti Jamaní

Ní ọdún 1994, ẹgbẹ́ archeology láti ilẹ̀ Jamani àti ilẹ̀ Nàìjíríà ti wa ilẹ̀ ní agbègbè ná à tí wọ́n sì wa ọkọ̀ ojú-omi kékeré yi jáde lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ méjì látipasẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tí ó tó ààdọ́ta. Wọ́n ṣe àwárí i rẹ̀ pé ọkọ̀ yí wọ̀n tó ìwọ̀n 8.4 ní gígùn, ìwọn 0.5 ní fífẹ̀ àti 5cm bí o tí nípọn tó. Wọ́n rí ọkọ̀ ojú-omi kékeré yi ní ipò adágún omi kan tí ó sì wà lórí ipò ìbùsùn lórí iyanrìn tí fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ amọ̀ si wà ní àárín rẹ àti ojú ilẹ̀ èyítí ó dáábò bò ní agbègbè tí kò ní atégùn Àyẹ̀wò ọkọ̀ yí fi hàn gbangba ipò tí ọkọ̀ yí wà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Breuning sọ wípé ọgbọ́n àti ìmọ̀ tí wọ́n fi ṣe ọkọ̀ yí ṣe àfihàn ìdàgbàsókè pípé àti wípé ọkọ̀ ojú-omi kékeré yi kì í ṣe àpẹrẹ tuntun. Nínú ìwádì míràn tí ẹgbẹ́ ìmọ̀ Science ti ìlú Amẹ́ríkà ṣe ní ọdún 2015, wọ́n rí i wípé omi adágún odò Lake Chad ti dínkù ní ìwọ̀n márùndínlọ́gọ́rùn ún (95%) ní ogójì ọdún, nítorínà ni a ṣe lè gbà wípé agbègbè abúlé ti Dufuna yíò ti jẹ́ apákan ní ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ ìṣàn omi adágún ní ìgbà kan rí.

Ọkọ̀ ojú-omi yi jẹ́ ọkọ̀ tí ọjọ́ orí rẹ pẹ́ jùlọ tí wọ́n ṣe àwárí rẹ ní Áfíríkà àti wípé ó jẹ́ ọkọ̀ ojú-omi kejì ní àgbáyé tí ọjọ́ orí rẹ pẹ́ jùlọ. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyì í, ọkọ̀ ojú omi yi wà ní Damaturu tí ó jẹ́ olú ìlú Ìpínlẹ̀ náà.[6]

Ó ṣe é se kí ó jẹ́ wípé ní àárín 6556/6388 cal BCE àti 6164/6005 cal BCE ni wọ́n dá ọkọ̀ ojú-omi yi sílẹ̀. Ọkọ̀ ojú-omi Dufuna ni ọkọ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ mọ̀ ní Áfíríkà àti wípé ó tún wà lára àwọn ọkọ̀ ojú-omi tí wọ́n kọ́kọ́ mọ̀ ní àgbáyé. Ó tún ṣe é ṣe kí ó jẹ́ wípé ọkọ̀ ojú-omi Dufuna jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ ojú-omi tí ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ṣe ìdásílẹ̀ wọn. Ó sì ṣe é ṣe kí ó jẹ́ wípé ọkọ̀ ojú-omi Dufuna ni wọ́n ńlò láti fi ṣe iṣẹ́ ẹja pípa ní agbègbè Komadugu Gana River. Ọkọ̀ ojú omi yì í ni ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ wípé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ olùgbé tí wọ́n fi ìdí kalẹ̀ sí agbègbè ìwọ̀ oòrùn ti Sahara, lọ sí Nile tí ó jẹ́ àáríngbùgùn Sudan, lọ sí agbègbè àríwá ti Kenya ni ó ṣe ẹ̀da rẹ̀.[7]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Garba, Abubakar. The architecture and chemistry of a dug-out: the Dufuna Canoe in ethno-archaeological perspective. http://publikationen.ub.uni-frankfurt.de/oai/container/index/docId/1859. 
  2. Ujorha, Tadaferua O. (16 September 2002). "Nigeria: Dufuna Canoe: a Bridge Across 8,000 Years". Daily Trust (Abuja). https://allafrica.com/stories/200209170457.html. 
  3. Gumnior, Maren (2003). Holocene fluvial dynamics in the NE Nigerian Savanna. 
  4. "Africa’s oldest boat set for exhibit in Nigeria". Africa Times. 6 April 2018. Archived from the original on 28 February 2020. https://web.archive.org/web/20200228205238/https://africatimes.com/2018/04/06/africas-oldest-boat-set-for-exhibit-in-nigeria/. 
  5. Adewumi, Afolasade A (2014). "Dufuna Canoe Find: Birthing the Underwatercultural Heritage In Nigeria". University of Ibadan Journal of Public and International Law 4: 1-12. https://www.academia.edu/35514815/DUFUNA_CANOE_FIND_BIRTHING_THE_UNDERWATER_CULTURAL_HERITAGE_IN_NIGERIA. 
  6. Trillo, R. (2008). The Rough Guide to West Africa. Rough Guides. p. 2640. ISBN 978-1-4053-8070-6. https://books.google.com.ng/books?id=TL1q6BiISt8C&pg=PT2640. Retrieved 2021-07-28. 
  7. Breunig, Peter; Neumann, Katharina; Neer, Wim. "New research on the Holocene settlement and environment of the Chad Basin in Nigeria". The African Archaeological Review 13 (2): 111–145. ISSN 0263-0338. https://www.academia.edu/6747300/New_research_on_the_Holocene_settlement_and_environment_of_the_Chad_Basin_in_Nigeria. Retrieved 2021-07-28.