Àṣá
Bùkọ́lá Elémidé tí wọ́n ń pè ní "Àṣá", ni wọ́n bí ní oṣù (September 17, 1982)[1] tí ó jẹ́ ọmọ Yorùbá ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n bí sí ilẹ̀ Faransé. Jẹ́ olù-korin, àti òṣèré tí ó ń gbé àwo orin jáde.
Aṣa | |
---|---|
Background information | |
Orúkọ àbísọ | Bùkólá Elemide |
Ọjọ́ìbí | 17 Oṣù Kẹ̀sán 1983 Paris, France |
Irú orin | |
Instruments |
|
Labels |
|
Website | http://asaofficial.com |
Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Bùkọ́lá Elémidé, (Àṣá) ní ìlú Paris, ní orílẹ̀ èdè Faransé nígbà tí àwọ́̀n òbí rẹ̀ jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ darí padà sí orílẹ̀ èdè baba wọn nígbà tí Àṣá wà ní ọmọ ọdún méjì, tí ó sì dàgbà sí ìlú Èkó. Àmọ́, lẹ́yìn ogún ọdún, Àṣá padà sí ìlú Paris ní orílẹ̀ èdè Faransé níbi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣè orin kíkọ rẹ̀.
Ìpìlẹ̀ rẹ̀
àtúnṣeÀṣá jẹ́ ọmọ obìnrin kan ṣoṣo fún àwọn òbí rẹ̀ láàrín àwọn ọmọ mẹ́rin tí wọ́n bí, òun ló má ń ṣe ìtọ́jú ilé bí àwọn òbí rẹ̀ kò bá sí nílé, ìgbà yí ni Àṣá ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ. Ó najú tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin àwọn gbajú-gbajà olórin olókìkí bíi: Marvin Gaye, Fẹlá Kútì, Bob Marley, Aretha Franklin, King Sunny Adé, àti Ebenezer Obey. tí ó sì tara wọn gba ìmísí orin kíkọ.
Ní ọdún 2004, Àṣá pàdé alákòóso (Manager) rẹ̀ tí ó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ìyẹn Janet, ẹni tí ó mu dé ọ̀dọ̀ Cobhams Emmanuel Asuquo, tí ìyẹn náà sì tún padà di amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ níbi iṣẹ́ orin, tí ó sì tún ba gbé àwo orin rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde tí ó pè àkọ́lé rẹ̀ ní Àṣá (Asha)
Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ (IMFP) láti lọ kọ́ nípa orin Jáàsì (Jazz).Àdàkọ:When
Ó gbé àwo orin rẹ̀ "Ẹyẹ Àdàb̀a", tí ó dá kọ jáde ní orílẹ̀ èdè bàbá rẹ̀ Nàìjíríà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sì ti ń gbọ́ orin rẹ̀. Àṣá dara pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́́ (Naïve Records). Ìbáṣepọ̀ òun àti Cobhams, ni ó jẹ́ kí ó mọ ọ̀gbẹ́ni Christophe Dupouy àti Benjamin Constant, ní ó so èso rere tí ó fi gbé àwo orin rẹ̀ "Àṣá" jáde. kò pẹ́ kò jìnà tí wọ́n fi ń gbọ́ àwo orin Àṣá káà kiri ilẹ̀ Aláwọ̀ funfun àti ilé Adúláwọ̀ àti orí rédíò káà kiri. Èyí ni ó ṣokùnfà gbígba àmì ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá ilẹ̀ Faransé ìyẹn: (French Constantin Award) ní ọdún 2008, nígbà ti wọ́n dìbò yàán gẹ́gẹ́ bí ẹni àkọ́kọ́ làárin àwọn olùdíje akọrin mẹ́wàá tó lẹ́bùn ọpọlọ jùlọ nílùú Parisi.
Àwo orin rẹ̀ ẹlẹ́kejì tí ó pè ní "Beautiful Imperfection", ni ó gbé jáde ní ọjọ́ karùún oṣù Kẹ́wàá ọdún 2010 (25 October 2010). Orin tí ó síwájú nínú àwo orin "Beautiful Imperfection" ni àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Be My Man". Ó gbe jáde ní ìparí ọdún 2010.
Àwo orin rè kẹ́ta ní ó pè àkọ́lé rẹ̀ ní "Bed Of Stone", ní ó gbé jáde ní oṣu Kẹ́jọ ọdún 214 (August 2014), tí orin tí ó ṣíwájú nínú àwo náà jẹ́ 'Dead Again', tí àwọn bíi: 'Eyo', 'Satan Be Gone' àti 'The One That Never Comes' tẹ̀lé. Àṣá ṣe ìrìn àjò orin káà kiri àgbáyé láàrín ọdún 2015 sí 2017.
Àwọn Àwo orin rẹ̀
àtúnṣeÀwo
àtúnṣeYear | Album | Chart positions[2] | |||||
---|---|---|---|---|---|---|---|
FRA [3] |
BEL [4] |
ESP [5] |
SUI [6] |
US Heat [7] |
World [8] | ||
2007 | Aṣa (Asha) | 15 | 81 | - | 65 | 32 | 3 |
2009 | Live in Paris | 112 | - | - | - | - | - |
2010 | Beautiful Imperfection | 14 | 35 | 61 | 54 | - | 3 |
2014 | Bed of Stone | 38 | 80 | - | 64 | - | - |
Ní ọdún 2014, wọ́n jábọ̀ rẹ̀ wípé ṣáájú kí ó tó gbé àwo "Bed of Stone" jáde, Ó ti tà àwo orin tí ó tó 400,000 jákè jádò àgbáyé.[9]
- 2022: V (feat. Wizkid)
Àwọn orin àdákọ
àtúnṣeYear | Title | FRA |
BEL |
Album |
---|---|---|---|---|
2009 | "Fire on the Mountain" | - | - | Aṣa (Asha) |
"Jailer" | - | - | ||
2010 | "Be My Man" | 89 | 76 | Beautiful Imperfection |
2011 | "Why Can't We" | - | 94 | |
2012 | "The Way I Feel" | - | - | |
"Ba Mi Dele" | - | - | Beautiful Imperfection (re-release) | |
2014 | "Dead Again" | 109 | - | Bed of Stone |
2015 | "Eyo" | - | - |
Àwọn orin tí ó ti kópa
àtúnṣe- 2007: "Kokoya" - on the soundtrack to the film The First Cry
- 2011: " Zarafa" - soundtrack for the Animation movie Zarafa
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ tí ó gbà
àtúnṣe- 2008: Prix Constantin
- 2011: French Music Awards Victoires de la Musique nomination for "Female Artist of the Year".
Àwọn ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ http://lescharts.com/showinterpret.asp?interpret=Asa+%5BFR%5D
- ↑ http://www.ultratop.be/fr/showinterpret.asp?interpret=Asa+%5BFR%5D
- ↑ http://www.spanishcharts.com/showitem.asp?interpret=Asa+%5BFR%5D&titel=Baby+Gone&cat=s
- ↑ http://www.hitparade.ch/showinterpret.asp?interpret=Asa+%5BFR%5D
- ↑ http://www.billboard.com/artist/280043/asa/chart
- ↑ http://www.billboard.com/artist/280043/asa/chart?f=339
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2016-09-21. Retrieved 2018-07-17.