Ebbe Bassey
Ebbe Bassey jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ati Amẹ́ríkà tí a yàn fún àmì-ẹ̀yẹ Africa Movie Academy Award kan fún tí òṣèré tí ó dára jùlọ ní ipa àtìlẹyìn nípasẹ̀ ipa tí ó kó gẹ́gẹ́ bi "Maa Dede" nínu Ties That Bind ní ọdún 2011.
Ebbe Bassey | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | New York |
Iṣẹ́ | Osere |
Ìgbà iṣẹ́ | 1997 di lowolowo |
Olólùfẹ́ | Mark Manczuk |
Iṣẹ́-ìṣe
àtúnṣeBassey ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà ati ti Amẹ́ríkà, lára wọn ni Doctor Bello, Mother of George, NYPD Blue, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ti rí yíyàn fún àmì-ẹ̀yẹ òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tí ó dára jùlọ látàrí ipa rẹ̀ nínu eré Ties That Bind.[1] Ní ọdún 2012, ó kéde rẹ̀ wípé òun fẹ́ gbé eré ṣókí kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Saving Father, léte àti la àwọn ènìyàn lọ́yẹ̀ nípa níní àti gbígbé ayé pẹ́lú kòkòrò àrùn AIDS.[2] Níbi ayẹyẹ Nigeria Entertainment Awards ti ọdún 2013, wọ́n tún yan Bassey gẹ́gẹ́ bi òṣèré tó n ṣe àtìlẹyìn tó dára jùlọ nínu fiimu.[3] Ní ọdún 2012 bákan náà, Bassey kópa nínu fiimu Turning Point. fiimu náà ṣì gba àwọn àmì-ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ Nollywood and African Film Critics Awards, èyí tí ó wáyé ní Amẹ́ríkà.[4] Ní ọdún 2016, ó kó ipa "Imani" nínu fiimu Tomorrow Ever After, ó sì ní àwọn èsì àtúnyẹ̀wò rere fún ipa rẹ̀ nínu fiimu náà.[5][6] Bassey pẹ̀lu Richard Mofẹ́-Damijo ni wọ́n jọ ṣètò ayẹyẹ Nigeria Entertainment Awards ti ọdún 2016 ní Ilé-iṣẹ́ tó wà fún eré ṣíṣe, Ilé-iṣẹ́ BMCC Tribeca Performing Arts Center ní ìlu New York.[7]
Ìgbé ayé rẹ̀
àtúnṣeA bí Bassey ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ṣùgbọ́n ó lo àwọn ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ní ìlu Calabar ṣááju kí ó tó padà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti máa gbé níbẹ̀.[8] Ó ti ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lu Mark Manczuk.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Sam-Duru, Prisca (May 25, 2012). "Women need spiritual core to be empowered – Ebbe Bassey". Vanguard. Retrieved 2017-11-11.
- ↑ admin (March 20, 2012). "AFRICAN CINEMA: ACTRESS EBBE BASSEY MANCZUK NEEDS YOUR HELP TO COMPLETE HIV/AIDS AND SENIOR CITIZENS FILM PROJECT". ladybrillemag.com. Archived from the original on 2017-12-01. Retrieved 2017-11-30.
- ↑ Michael, Abimboye (May 31, 2013). "Nigerian Entertainment Award announces 2013 nominees". Premium Times. Retrieved 2017-11-12.
- ↑ Izuzu (May 24, 2016). "Governor Ayade launches Callywood, appoints filmmaker to run it". Pulse. Retrieved 2017-11-30.
- ↑ "Movie Review: Tomorrow Ever After". theyoungfolks.com. May 26, 2017. Retrieved 2017-11-12.
- ↑ Linden, Sheri. "Tomorrow Ever After’: Film Review". Hollywood Reporter. Retrieved 2017-11-12.
- ↑ Izuzu (August 6, 2016). "Joseph Benjamin, Faithia Balogun, Sambasa Nzeribe among winners". Pulse. Retrieved 2017-11-30.
- ↑ "American Actress Ebbe Bassey Making A Comeback On African Screens". Modern Ghana. June 15, 2012. Retrieved 2017-11-11.