Echinococcosis, tí a tún npè ní àìsàn hydatidhydatidosis, tàbí àìsàn echinococcal, jẹ́ àrùn kòkòrò ajọ̀fẹ́ ti àràn mùjẹ̀mùjẹ̀ pẹlẹbẹ tó jẹ́ ti orìṣi Echinococcus. Àwọn ènìyàn a má ní orìṣi méjì irú àrùn yìí, echinococcosis tó níí ṣe pẹ̀lú àpò tí omi gbè sí àti echinococcosis tó níí ṣe pẹ̀lú ihò nínú ara. Àwọn oríṣi méjì mìíràn tí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ni echinococcosis alápò omi púpọ̀ àti echinococcosis alápò omi kanṣoṣo. Àrùn náà a má a sábà bẹ̀rẹ̀ láìsí àmì àrùn kankan, èyí sì lè rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Irú àwọn àmì àrùn tó má a nfarahàn dá lórí ipò àti títóbi àpò omi náà. Àrùn tó níí ṣe pẹ̀lú ihò nínú ara náà a má a bẹ̀rẹ̀ nínú ẹ̀dọ̀ ṣùgbọ́n ó lè tàn dé àwọn ẹ̀yà ara mìíràn bíi ẹ̀dọ̀fóró tàbí ọpọlọ. Bí ó bá ti kan ẹ̀dọ̀, ènìyàn náà lè má a ní inú rírun, ara jíjò wálẹ̀, àti àyípadà àwọ̀ yellow. Àrùn ẹ̀dọ̀fóró lè ṣe òkùnfà àyà dídùn, àìlèmíkanlẹ̀ àti ikọ́.[1]

Echinococcosis
EchinococcosisEchinococcus life cycle (click to enlarge)
EchinococcosisEchinococcus life cycle (click to enlarge)
Echinococcus life cycle (click to enlarge)
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B67. B67.
ICD/CIM-9122.4, 122 122.4, 122
DiseasesDB4048

Òkùnfa

àtúnṣe

Àrùn náà a má a tàn káàkiri nígbàtí ènìyàn bá jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tó ní ẹyin kòkòrò ajọ̀fẹ́ nínú, tàbí nípasẹ̀ fífarakan ẹranko tó ti ní àrùn náà.[1] Ẹyin náà a má a jáde síta pẹ̀lú ìgbọ̀nsẹ̀ àwọn ẹranko tó njẹ ẹran, tí kòkòrò ajọ̀fẹ́ náà ti kó àrùn bá.[2] Àwọn ẹranko tó má a nsábà ní àrùn náà ni: ajá, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti ìkokò.[2] Fún àwọn ẹranko wọ̀nyí láti ní àrùn náà, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹ̀yà ara ẹranko tó ní àpò omi náà nínú, gẹ́gẹ́ bíi àgùtàn tàbí àwọn oríṣiríṣi èkúté.[2] Oríṣi àrùn náà tó má a nwáyé lára ènìyàn dá lè irú Echinococcus tó fa àkóràn àrùn náà. Ìwádìí àrùn a má a sábà jẹ́ nípasẹ̀ lílo ìró ohùn láti yàwòrán, èyítí à npè ní ultrasound bí ó tilẹ jẹ́ pé a tún lè lo fífi ẹ̀rọ kọmputa ya àwòrán onígun mẹta àwọn àgbékalẹ̀ ètò inú ara ènìyàn, tí à npè ní computer tomography (CT) tàbí lílo iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ òòfà irin láti fi yàwòrán àwọn àgbékalẹ̀ ètò inú ara tí à npè ní magnetic resonance imaging (MRI. Àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ tí nwá àwọn àkóónú inú ẹ̀jẹ̀ tí ngbógun ti kòkòrò àrùn, tí à npè ní antibodies tí nkojú kòkòrò ajọ̀fẹ́ náà lè ṣe ìrànwọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni àyẹ̀wò ẹran ara tí a gé kúrò láti ara ènìyàn láti lè mọ orísun àti òkùnfà àrùn, tí à npè ní biopsy pàápàá.[1]

==Ìdènà àrùn àti Ìtọ́jú ==  Ìdènà àrùn tó níí ṣe pẹ̀lú àpò omi nínú ara jẹ́ nípasẹ̀ ìtọ́jú àwọn ajá tó lè ti ní àrùn náà lára àti nípasẹ̀ fífún àwọn àgùtàn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára. Ìtọ́jú a má a ṣòro nígbà púpọ̀. Àpò omi nínú ara náà ni a lè fà jáde láti awọ ara, lílo òògùn sì gbọ́dọ̀ tẹ̀lé èyí.[1] Nígbà mìíràn, a kàn má a nwo irú àrùn báyìí ni.[3] Oríṣi tó níí ṣe pẹ̀lú ihò nínú ara a má a sábà nílò iṣẹ́ abẹ, òògùn lílò a sì tẹ̀lé e.[1] Òògùn tí à nlò ni albendazole èyítí ènìyàn lè nílò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.[1][3] Àrùn tó níí ṣe pẹ̀lú ihò nínú ara náà lè fa ikú.[1]

Àtànká àti Ìṣàkóso àtànká àrùn

àtúnṣe

Àrùn náà a má a wáyé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè káàkiri àgbáyé, a sì má a ran iye àwọn ènìyàn tó tó mílíọ̀nù kan. Ní àwọn agbègbè kan ní Gúsù Amẹ́ríkà, Afrika àti Eṣíà, iye àwọn ènìyàn tó tó mẹwa nínú ọgọrun (10%) nínú gbogbo akójọpọ̀ ènìyàn tó wà ní agbègbè náà ni àrùn náà má a nràn.[1] Ní ọdún 2010 ó ṣe òkùnfà ikú ènìyàn tó tó 1200, èyítí ó wálẹ̀ láti 2000 ní ọdún 1990.[4] Iye ìwọ̀n owó tí àrùn náà ngbà ni a ṣírò sí bíi bílíọ̀nù 3 USD lọ́dún. Ó lè ran àwọn ẹranko mìíràn bíi ẹlẹ́dẹ̀, mààlúù àti ẹṣin.[1]

Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 1.7 1.8 "Echinococcosis  Fact sheet N°377". World Health Organization. March 2014. Retrieved 19 March 2014. 
  2. 2.0 2.1 2.2 "Echinococcosis [Echinococcus granulosus] [Echinococcus multilocularis] [Echinococcus oligarthrus] [Echinococcus vogeli]". CDC. November 29, 2013. Retrieved 20 March 2014. 
  3. 3.0 3.1 "Echinococcosis Treatment Information". CDC. November 29, 2013. Retrieved 20 March 2014. 
  4. Lozano, R (Dec 15, 2012). "Global and regional mortality from 235 causes of death for 20 age groups in 1990 and 2010: a systematic analysis for the Global Burden of Disease Study 2010.". Lancet 380 (9859): 2095–128. doi:10.1016/S0140-6736(12)61728-0. PMID 23245604.