Ectropion
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10H02.1, Q10.1 H02.1, Q10.1
ICD/CIM-9374.1 374.1
DiseasesDB4108
MedlinePlus001007

Ectropion jẹ́ àrùn tí ìdéjú ìsàlẹ̀ ṣí sí ìta. Ó jẹ́ ìkan gbọ̀n tí a maa ń rí tí wọ́n bá bí ọmọ tuntun tí ó ní ichthyosis ti irú Harlequin ṣùgbọ́n ectropion lè wáyé látàrí àìlágbára àwọn ẹran ara ìdéjú ìsàlẹ̀. Ọ́n lè fi iṣẹ́ abẹ tọ́jú àrùn yìí. Wọ́n tún maa ń rí àrùn yìí lára àwọn ajá gẹ́gẹ́ bí àrùn abínibí ní àwọn ẹ̀yà kan.

Cycatricial ectropion ti ìdéjú ìsàlẹ̀-ojú wà ní ṣíṣí
Cycatricial ectropion - ojú padé

Okùnfà rẹ̀ àtúnṣe

  • Àrùn látàrí ìbíni
  • Ìdarúgbó
  • Ogbẹ́ ara
  • Ìjàmba tí ó lè bara jẹ́
  • Ìlòdì ara sí àwọn nkan
  • Facial nerve palsy
  • Àwọn oògùn tí a fi ń tọ́jú àrùn jẹjẹrẹ bíi erlotinib, cetuximab, àti panitumumab, tí ó maa ń díwọ́ iṣẹ́ EGFR (tí a mọ̀ sí epidermal growth factor receptor).

Ectropion ní ara àwọn ajá àtúnṣe

Ectropion lára àwọn ajá maa ń ń ṣe pẹ̀lú ìdéjú ìsàlẹ̀. Àrùn yìí kò ní àmìn ṣùgbọ́n a lè rí ìwami lójú àti ipin. Àwọn ẹ̀yà ajá tí ó maa ń sábà ní ectropion ni Cocker Spaniel, Saint Bernard, Bloodhound, the Clumber Spaniel, àti Basset Hound.[1] Ó lè wáyé látàrí àìfọkànbalẹ̀ tàbí bíbàjẹ́ ẹṣọ́ ara. Ìtọ́jú (iṣẹ́ abẹ) ni kí a lò tí ipin yìí bá lágbára tàbí tí ẹyin ojú bá fẹ́ bàjẹ́. Wọn a maa yọ díè nínú ìdejú tí ó pa lara, tí wọ́n sì maa rán pàpọ̀ padà.

 
Ectropion ní Cocker Spaniel

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Gelatt, Kirk N. (ed.) (1999). Veterinary Ophthalmology (3rd ed.). Lippincott, Williams & Wilkins. ISBN 0-683-30076-8. 

Àwọn ìjápọ̀ látìta àtúnṣe