Efo Riro
Efo riro (Àdàkọ:Langx) jẹ́ ọbẹ̀ tí a fi ewé aṣara lóore sè ó sì jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ ẹ̀yà àwọn ènìyàn Yorùbá ti apá Ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà àti àwọn àgbègbè Yorùbá. Àwọn ẹ̀fọ́ méjì tí wọ́n sábà máa ń lò fún ni Celosia argentea (ṣọkọ̀ yòkòtò)[1] àti Amaranthus hybridus[2] (ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀).[3][4] Ìtàn Ẹ̀fọ́-rírò jẹ́ èyí tó rinlẹ̀ nínú àṣà àtibìṣe Yorùbá. Wọn máa ń ṣe pẹ̀lú àwọn ewé tí wọ́n máa ń gbìn ní agbègbè wọn, ẹran, ẹja àti àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ èròjà amọ́bẹ̀dùn. Àwọn àṣàyàn ẹ̀fọ́ àti èròjà yìí máa ń yàtọ̀ ní agbègbè dé àgbègbè àti ohun tí ẹni tí ó ń sè é bá fẹ́ràn. Àwọn ẹ̀fọ́ tí wọ́n sábà máa ń lò ni pọ̀pọ̀, ewé Ugu tàbí ewé sorrel , tí a sábà sè pọ̀ mọ tàtàṣe, báwà, ata àti àlùbọ́sà.[5]
Type | Dish |
---|---|
Place of origin | Yorubaland (Western Nigeria) |
Region or state | Nigeria |
Main ingredients | stockfish, Scotch bonnets (atarado), tatashe (red bell pepper), onions crayfish, water, palm oil, red onion, leaf vegetables, other vegetables, seasonings, meat |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
Ẹfọ̀ rírò jẹ́ oúnjẹ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa ń jẹ ní ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n sì máa ń sè níbi ayẹyẹ àti ìnáwó. Wọ́n sábà máa ń jẹ pẹ̀lú Àmàlà, Iyán, Fùfú, Ẹ̀bà, tàbí oríṣi òkèlè mìíràn.[6] Òkìkí Ẹ̀fọ́-rírò ti kàn káàkiri kọjá Nàìjíríà, pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àfikún tàbí àyọkúrò síse oúnjẹ náà. .
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "The many benefits of celosia argentea, celosia trigyna". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-21. Retrieved 2022-12-21.
- ↑ Peter, Kavita; Gandhi, Puneet (2017-09-01). "Rediscovering the therapeutic potential of Amaranthus species: A review" (in en). Egyptian Journal of Basic and Applied Sciences 4 (3): 196–205. doi:10.1016/j.ejbas.2017.05.001. ISSN 2314-808X. https://www.sciencedirect.com/science/article/pii/S2314808X17302166.
- ↑ Iswat Badiru; Deji Badiru (19 February 2013). Isi Cookbook:Collection of Easy Nigerian Recipes. iUniverse, 2013. ISBN 9781475976717. https://books.google.com/books?id=pDj5SB3KF8UC&dq=Efo+riro&pg=PA35. Retrieved July 7, 2015.
- ↑ The Recipes of Africa. Dyfed Lloyd Evans. p. 112. https://books.google.com/books?id=FJxlWwrVcKcC&dq=Efo+riro&pg=PA112. Retrieved July 7, 2015.
- ↑ Tv, Bn (2023-08-29). "Check Out Velvety Foodies’ Delicious Efo Riro Recipe | Watch". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-04-01.
- ↑ Oredola, Tayo (2019-08-16). "Efo riro - Nigerian Spinach Stew". Low Carb Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-04-01.