Ẹfọ̀n-Alààyè

(Àtúnjúwe láti Efon-Alaaye)

Nínú àwọn ìwé ti mo yẹ̀ wò. kò sí èyí tó sọ pàtó ìgbà tàbí àkókò tí a dá ìlú Ẹ̀fọ̀m-Aláayè sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti àbúdá ìtàn ìwáṣẹ̀. púpọ̀ nínú ìtàn yìí ló máa ń rújú pàápàá tó bá jẹ́ ìtàn ìtẹ̀lúdó ni ìlẹ Yorùbá. (Akínyẹmí 1991:121) Ìlànà ìtàn àròsọ ìwásẹ̀ ní a gbé ìtàn wọ̀nyí lé. Ní ìgbà ìwáṣè kò sí pé a ń kọ nǹkan sílẹ̀. Nítorí àìkọ sílẹ̀ ìtàn yìí, kò jẹ́ kì a rí àkọsílẹ̀ gidi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá nínú ibi tí ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè ti jé ọ̀kan nínú awọn ìlú bẹ́ẹ̀. Ìtàn ti a rí jójọ kò kọjá ìtàn atẹnúdẹnu. ìtàn ìwáṣẹ̀ ìlú Ẹ̀fọ̀n Aláayé kò yàtọ̀ sí èyí. Oríṣìí òpìtàn ni a rí, ìtàn wọn máa ń yàtọ̀ sí ara wọn, bí kò ní àfikún yóò ni àyọkúro ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí àwọn òpìtàn ti ṣiṣẹ́ lé lórí nípa ìtàn ilẹ̀ Aáfíríkà ni ìyànjú wọn lati wo ìtàn ìwáṣẹ̀, kí wọ́n tó lè fa òótọ́ yọ jáde. Ṣàṣà ni onímọ̀ kan tó ṣiṣẹ́ lórí ìtàn ìlú kan tàbí àdúgbò kan tí kò mú ìlànà ìtàn ìwáṣẹ̀ ló láti ṣàlàyé to bojumu nípa orírun ìlú kan (Johnson 1921;3).

Ẹfọ̀n-Alààyè
Àwòrán agbègbè kan ní Ẹfọ̀n alààyè
Country Nigeria
StateEkiti State

Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn ilẹ̀ Yorùbá, àwọ òpìtàn ìlú Ẹ̀fọ̀n Aláayè gbà pé ọ̀dọ̀ odùduwà ni wọ́n tí ṣẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀. Lára àwọn òpìtàn yìí tilẹ̀ lérò pé ẹni tó tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè dó rọ̀ lati ojú ọ̀run sílé ayé. Ìlú tó sọ̀kalẹ̀ sí ní Ilé-Ifẹ̀ tó jẹ́ orírun àwọn Yorùbá. Ìtàn yìí ṣòro láti gbàgbọ́, nítorí kò ri ìdí múlẹ̀. Kò tí ì sí ẹni tí a rí tó wọ̀ láti ojú ọ̀run rí. Nínú ìtàn ìwáṣẹ̀, òrìṣà àti odù mẹ́rìndínlógún ni a gbọ́ pé wọ́n rọ̀ láti ìsálọ̀run wá sí ìsálayé (Abimbọla, W. 1968:15). Awọn òpìtàn yìí lè rò pé bóyá nítorí tí a ti ń pe àwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá ni ìgbákejì òrìṣà ni àwọn náà ṣe rò pé Aláayè àkọ́kọ́ rọ̀ sílẹ́ ayé lati ọ̀run.

‘Ọmọ ọwá, ọmọ ẹkún

Ọmọ òkìrìkìsì

Ọmọ ọ̀ tójú ọ̀run á yé’

Nínu ìtàn ìwáṣẹ̀ mìíràn, a gbọ́ pé Ọbàlùfọ̀n Aláyémore ni ọba àkọ́kọ́ ti o tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè dó. Ọbalùfọ̀n Aláyémọrẹ yìí jẹ́ ọmọ Ọbàlùfọ̀n Ogbógbódirin tí í ṣe àkọ́bí Odùduwà tí ó jẹ́ Ọọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀ ni àkókó ìgbà kan. Lẹ́yìn Ikú rẹ̀, Ọ̀rànmíyàn lò yẹ kí ó jẹ ọba ní Ilé-Ifẹ̀ ṣùgbọ́n ó ti lọ sílùú àwọn ọmọ rẹ̀, Eweka ni Eìní ati Aláàfin ni Ọ̀yọ́. Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ ti jẹ oyè Ọọ̀ni kí Ọ̀rànmíyàn tó dé.

Nígbà tí Ọ̀rànmíyàn dé, Aláyẹ́mọrẹ sá kúrò lórí oyè nítorí pé ní ayé àtijọ́ wọn kì í fi ẹni ìṣááju sílẹ̀ láti fi àbúrò joyè. Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ rìn títí ó fi dé orí òkè kan. Wọn pe ibẹ̀ ni Ọba-òkè. Èyí ni ọba tó tẹ̀dó sorí òkè ṣùgbọ́n lónìí ọ̀bàkè ni wọn ń pe ibẹ̀.

Ni orí òkè yìí, Ọbàlùfọ̀n ṣe àkíyèsí pé ẹranko búburú pọ̀ ní agbègbè tó tẹ̀dó sí, èyí tó pọ̀jù ni ẹfọ̀n. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ẹfọ̀n yìí ni àparun. Awọn ẹfọ̀n kékeré níbẹ̀ ni wọn kójọ sínu ọgbà, ti wọn so wọn mọ́lẹ̀ títí wọ́n fi kú. Ọmọdé tó bá lọ sì igbó ibi tí wọ́n kó ẹfọ̀n kékeré sí, ni awọn òbí wọn a ké pé: ‘Kọ́ ọ̀ yàá ṣe lúgbó ẹfọ̀n alaayè’

Nibi yìí ni Ẹ̀fọ̀n ti kún orúkọ Ọbalufọn Aláyémọrẹ. Lára Aláyémọrẹ ni wọn tí yọ Aláayè to fid i: Ẹ̀fọ̀n-Aláayè títí dí òní. Nígbà tí ó ṣe Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ ránṣẹ́ sí Ọ̀rànmíyàn kí o fi nǹkan ìtẹ̀lúdó ṣọwọ́ sí òun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi nǹkan yìí ránṣẹ́ sí Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ; kò pẹ́ ti Ọ̀rànmíyàn kú. Àwọn ará Ilé-Ifẹ̀ wá ránṣẹ́ si Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ láti wá jọba lẹ́ẹ̀kejì. Kí o tó lọ, ó fí ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀. Ìyàwó mẹ́ta ni Aláyémọrẹ ni kí ó tó kúrò ní Ẹ̀fọ̀n-Aláayè. Àwọn ni Adúdú Ọ̀ránkú tí ì ṣe ìran àwọn Obólógun; Aparapára ọ̀run ìran awọn Aṣemọjọ, ẹ̀ẹ̀kẹta ni Èsùmòrè-gbé-ojú-ọ̀run-sàgá-ìjà. Ìtàn sọ pé lásìkò tí Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ padà sí Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọọ̀ni, bọ́ sí àkókò ti Ọba Dàda Aláàfin Ọ̀yọ́ wá lórí oyè ni nǹkan bí 1200-1300AD.

Bí ìtàn ìwáṣẹ̀ yìí ìbá ṣe rọrún tó láti gbàgbọ́ awọn àskìyèsí kan ní a rí tọ́ka sí tí ó jẹ́ kí ìtàn náà rú ènìyàn lójú. Nínú ìtàn yìí, wọn sọ pé Ọbàlùfọ̀n Ògbógbódirin ni àkọ́bí Odùduwa, èyí tó tako ìtàn tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa Odùduwa. Ọ̀kànbí ni àkọ́bí Odùduwa. Bó bá tilẹ̀ ṣe orúkọ ló yípadà, àwọn ọmọ Ọkànbí ni ọba méje pàtàkì ni ilẹ̀ Yorùbá tí kò sí Ọbàlùfọ̀n nínú wọn. Ohun tí òpìtàn ìbá sọ fun wa nip é ìran Odùduwà ni Ọbàlùfọ̀n jẹ́.

Àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ rú ni lójú púpọ̀. Nínú ìtàn yìí a ri i pe Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ mọ àsìkò ti Ọ̀rànmíyàn wà láyé. A rí i pé ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ni wọn. Kó yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kó jẹ ọmọ àti bàbá. Lóòótọ́ ni Ọ̀rànmíyàn jẹ ọba ni Òkò, tó tún wá sí Ilé-Ifẹ̀. Àwọn ará Ọ̀y;ọ ló fi Àjàká jẹ ọba sí Òkò. Aláàfin Dada tí òpìtàn fẹnu bà pé ó jẹ ọba ní Ọ̀yọ́ da ìtàn rú. Johnson (1921:144) gbà pé Àjàká ló wá lórí oyè gẹ́gẹ́ bí Aláàfin Ọ̀yọ́ nígbà tí Ọ̀rànmíyàn kú. Tó bá jẹ́ òtítọ́ ní Ọbàlùfọ̀n Aláyémọrẹ tún wa jọba lẹ́ẹ̀kejì ní Ilé-Ifẹ̀ a jẹ́ pé àsìkò Aláàfin Àjàkáló jẹ ọba.

Awọn òtìtọ́ kọ̀ọ̀kan farahàn nínú ìtàn yìí. Lóòótọ́ ni Ọbalùfọ̀n Aláyémọrẹ kan wá ni Ilé-Ifẹ̀. Títí dí oní ọ̀gbọ́n Ọbàlùfọ̀n wa ní Ilé-Ifẹ̀. Àdúgbò Aláayè si wa ní Ilé-Ifẹ̀ títí dí òní. Kò sí irọ́ níbẹ̀ pé Ẹ̀fọ̀n Aláayè bá Ilé-Ifẹ̀ tan. Nínú ìtàn mìíràn, a gbọ pé àwọn oríṣìí ènìyàn bí i mẹ́fà ni wọ́n tẹ̀dó lásìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sí Ẹ̀fọ̀n-Aláayè. Nínú ìtàn yìí, a gbọ́ pé Èkúwì ló kọ́kọ́ dé sílùú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, igbó-àbá ni Èkúwì tẹ̀dó sí. Ọdẹ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oríkin náà tẹ̀dó sí Igbó àayè. Lọ́jọ́ kan, lásìkò tí oríkin tẹ̀dó, ó rí iná tó ń rú ni Igbó-Àbá. Ó ṣe ọ̀dẹ lọ sí igbó yìí. Oríkin rọ àwọn tó wa ni Igbó àbá kí wọn jọ má gbé ní Igbó-Àayè. Wọ́n gbà bẹ́ẹ̀. Lásìkò tí wọn jọ ń gbé ni wọn fí Ọbàlùfọ̀n jẹ ọba. Igbákejì Ọbàlùfọ̀n tí wọ́n jọ wá láti Ilé-Ifẹ̀ ní wọn fi jẹ igbákejì ọba tí a mọ̀ sí Ọbańlá. Bàbá Igbó Àbá ọjọ́sí ni wọn fi jẹ baba ọlọ́jà tí a mọ sí Ọbalọ́jà. Ọbàlùfọ̀n àti Ọbalọ́jà jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nígbà náà. Bí ọba ṣe ń pàṣẹ fún àayè ní Ọbalọ́jà ṣe n pàṣẹ ní Ọ̀bàlú láyé ìgbà náà. Lónìí, Ọbalọ́jà jẹ Olóyè pàtàkì ní ìlú Ẹ̀fọ̀n. Ọbalọ́jù ní olórí àwọn Ọ̀bàlú. Àjọṣe wá láàrìn Ọba àti Ọbalọ́jà. Bí ọba kan bá wàjà ní ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, iwájú ilé ọba-ọlọ́ja ni wọn yóò kó ọjà lọ.

Nínú ìtàn mìíran a gbọ́ pé ààfin Odùduwà ni wọ́n bí Aláayè sí. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọba obinrin ló bii. O jẹ́ arẹwà okùnrin ti ènìyàn púpọ̀ fẹ́ràn rẹ̀ pàápàá àwọn babaláwo tó ń wá sí ààfin. Ìtàn yìí tẹ̀síwájú pé ọkùnrin yìí ní aáwọ̀ ni ààfin, èyí ló mú kí Odùduwà ṣe fún Aláayè ní ilẹ̀ sí ìráyè tí a mọ̀ sì Modákẹ́kẹ́ lónìí. Odùduwà fún un ni adé tó sì n jẹ́ Ọba Láayè. Nínú ìtẹ̀sìwájú, Ìtàn mìíràn tó fara jọ ìtàn òkè yìí, a gbọ́ pé àwọn ọmọọba méjì ló fẹ́ lọ tẹ ìlú dó. Bó ba rí bẹ́ẹ̀ á jẹ́ pé ìlú Ẹ̀fọ̀n tí wá kí Modákẹ́kẹ́ tó dáyé. Àtàdá ati Johnson tilẹ̀ maa ń to Aré àti Ẹ̀fọ̀n tẹ̀lé ara wọn.

Ni pàtàkì, ogun kò ṣẹgún Ẹ̀fọ̀ Aláayè rí àyàfi Ogun Ọdẹ́rinlọ (1852-54). Ọdẹ́rìnlọ jẹ ọmọ Ìrágberí, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀fọ̀n-Aláayè ni ìrágberí ti kúrò. A le sọ pe ọmọ bíbi Ẹ̀fọ̀n ló kó Ẹ̀fọ̀n-Aláayè kì í ṣe ọ̀tá nítorí òkè to yí wọ́n ká jẹ ìrànlọ́wọ́ púpọ̀ fún ìlú Ẹ̀fọ̀n-Aláayè, ó sì jẹ wàhálà fun ọ̀tá. Àwọn ọ̀tá to fẹ jà wọn lógun nígbó Òòyè, wọn ṣe lásán ni. Ogun yìí fà á ti Aláayè kì í fi jẹ osun ògògó titi dòní. Ohun àrífàyọ nínú ìtàn yìí nip é ọdẹ ló tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n dó gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlú mìíran ni ilẹ̀ Yorùbá. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn mìíràn ń tẹ̀lé e wá sí ibi ìtẹ̀dó. Ó ṣe é ṣe bẹ́ẹ̀ nitori ibi ti ọdẹ máa ń tẹ̀dó sí kò ní jìnnà sí omit i ń sàn; àtipé yóò ti kó àwọn ẹran rẹ̀ jọ sí ojú ibi ìdáná. Ọja ló ṣéyọ láti ibẹ̀. A tún rí i pé ẹni tó jẹ ọba Ẹ̀fọ̀n gbé adé rẹ̀ wá láti Ilé-Ifẹ̀; ṣùgbọ́n àsìkò tó dé sí ibùdó yìí ni a kò mọ̀. Lóòótọ́, ẹni tó bá jẹ́ alágbára láyé àtijọ, tó sì ní àmúyẹ ni wọn fi i jọba, lẹ́yìn ti Ifá bá ti fọre. Kò yá wá lẹ́nu pé wọ́n fi ẹni tí adé ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ jẹ ọba nítorí àwọn ohun àmúyẹ ọba wà ni sàkání rẹ̀.

Ní ìparí, Finnegan (1970:368) sọ nínú ọrọ rẹ pé: …they (myths) depict the deeds of human rather then supernatural heroes and deal with or allude to, events such as migrations, war, or the establishment of ruling dynasties.

Èyí ni pé ìtàn ìwáṣẹ̀ jẹ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ti pẹ́, ó ń sọ nípa ènìyàn akọni àti awọn nǹkan to yi i ka bí ìrìnàjò láti ibi kan sí èkejì, ogun jíjà ati bí wọn ṣe tẹ ìlú dó. Encyclopaedia Britanica (1960:54) ṣàlàyé pé ìtàn ìwáṣẹ̀ jẹ́ ìtàn nípa àṣà tí ó ń ṣàlàyé nípa ènìyàn, ẹranko, òrìṣà àti ẹ̀mí àìrí. Irú ìtàn yìí kì í sọ àkókò gan-an tí ìṣẹ̀lẹ̀ ṣẹ́ ṣùgbọ́n wọn jẹ́ kí ìtàn ní kókó àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò lò rí nínú ìtàn lásán. Ìtàn ìwáṣẹ̀ máa ń jẹ ọ̀nà kan pàtàkì láti ṣàlàyé ìgbé ayé tó ti kọjá. Ò máa ń sọ nípa bí àwọn ènìyàn ṣe dé sí ilẹ̀ kan ati ìdí tí àwọn kan fi jẹ gàba lórí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Volume Library (267) tilẹ̀ sọ pé o yẹ kí ìgbàgbọ́ wa rọ̀ mọ́ ìtàn ìwáṣẹ̀ nítorí ó jẹ́ mọ́ àṣà bí o tilẹ jẹ́ pé kò sí ẹni tó mọ ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n ohun ti a mọ̀ nip é ìtàn ìwáṣẹ̀ ti wáyé lásìkò tó ti pẹ́.

A kò lè fọ́wọ́ rọ́ ìtàn ìwáṣẹ̀ ìlí Ẹ̀fọ̀n-Alàayè ṣẹ́yìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú àwọn ìtàn tí àwọn òpìtàn sọ fún wa, ìdáṣọró okùn-ìtàn wà níbẹ̀ ṣùgbọ́n nǹkan tó ṣe pàtàkì ní pé ẹni tó tẹ ìlú Ẹ̀fọ̀n Alàayè dó wá láti Ilé-Ifẹ̀ ní àsìkò ìgbà kan tí a kò mọ̀. Ìlú ibi ti wọ́n tẹ̀dó sí tù wọn lára, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí dí òní.

Àkíyèsí: A yọ iṣẹ́ yìí láti inú àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹ́meè I.A. Ologunleko.