Ẹ̀kó Ìjìnlẹ̀ nípa Ìfitónilétí

OWOLABANI JAMES AHISU

Ẹ̀KÓ ÌJÌNLẸ̀ NÍPA ÌFITÓNILÉTÍ (INFORMATICS)

Ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí n kọ́ nípa ètò, ìṣesí àti ìbáṣepọ̀ àwọn ìlànà adánidá àti ìfi-ọgbọ́n-se, tó n pamọ́, tó sì n ṣe ìyípàdà àti ìkójọ ìfitónilétí. Bákan náà, ní ó n sẹ̀dá àwọn ìpìnlẹ̀ ajẹmérò àti tíórì tirẹ. Láti ìgbà tí àwọn ẹ̀ro kọ̀mpútà, àwọn aládáni àti àwọn onílé-iṣé nlánlá tí n ṣe ìyípadà àwọn abala àwùjọ. Ní ọdún 1957, Karl Steinbush tó jẹ́ orílẹ̀-èdè Germany, tí ó sì tún jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀rọ kọ̀mpútà (1917-2005) kọ ìwé kan tí ó pè ní “Informatik: Automatisdie Informationsverarbeitung”) èyí tó túmọ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì sí “Informatics: automatic information processing”) ohun ni a túmọ̀ ní èdè Yorùbá bí Ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí: ìlànà ìlò ìfitónilétí tí kò yí padà. Ní òde-òní, “Informatik” ni wọ́n n lò dípo “Computerwissescraft” ni orílẹ̀-èdè Germany èyí tó túmọ̀ sí (Computer Science) ní èdè Gẹ̀ésì, tí ó sì túmọ̀ sí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀rò kọ̀mpútà ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ nípa èkọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí. Bákan náà oríṣìírisìí àwọn onímọ̀ ìjìnlè nípa ẹ̀ro kọ̀mpútà láti àwọn orilẹ̀-èdè àgbáyé ni ó fún Ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí ní oríkì tiwọn pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ oríkì èyí wá láti orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì nípa ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí: ̣̣ Informatics is the discipline of science which investigates the structure and properties (not specific content) of scientific information, as well as the regularities of scientific information activity, its theory, history, methodology and organization. ̣ Èyí tó túmọ̀ sí:

Ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí jẹ́ ẹ̀ka kan lára ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó n wádìí nípa ètò àti àwon àkòónú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìfitónilétí, pẹ̀lú àwọn ìṣedédé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, tí ọ́rì rẹ̀, ìtàn rẹ̀, ogbọ́n-`ikọ́ni àti ètò rẹ̀ pẹ̀lú.

Oríṣìíríṣi ni ó ti bá ìlò rẹ̀, ọ̀nà mẹ́ta ni wọ́n ti túmọ̀ rẹ̀ sí. Ìkíní ni pé ìyípadà tó bá ìmò, ìjìnlẹ̀ ìfitónilétí ni wọ́n ti yọ kúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí ti ẹ̀kọ́ ìyìnlẹ́ nípa ìfitónilétí tó jẹmọ́ ètò ọrọ-ajé àti òfin ikejì ní, nígbà tí ó jẹ́ pé ọ̀pò nínú àwọn ìfitónilétí yìí ni wọ́n ti n kó pamọ́ nílànà tòde-òní, ìdíyelé tí wá jẹ pàtàkì sí ẹ̀kó ìjìnlẹ̀ nipa ìfitónilétí Ìkéta jẹ́ ìlò àti ìbánisọ̀rọ̀ nípa ìfitónilétí tí a rò pọ̀ láti lò fún ìwádìí, nígbà tí ó jé pé wọ́n ti gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe pàtàkì sí ohun kóhun tó bá jẹ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀.

Fún ìdí èyí ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà ní àgbáyé, wọn kò fọwọ́ yẹpẹre mú ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ nípa ìfitónilétí àti gbogbo ohun tó so mọ́ ọ ̣̣