Elédùmarè Yorùbá gbàgbọ́ wípé elédùmàrè ni ó dá ayé àti ọ̀run pẹ̀lú gbogbo ohun tí ń bẹ nínú wọn. Yorùbá sì gbàgbọ́ wí pé kò sí ohun tí Elédùmarè kò lẹ ṣe, òhun ni wọ́n fí ń ki Elédùmarè wí pé

"ọba àìkú,
 Ọba àjíyìn,
 Alayé gbẹlẹgbẹlẹ
 bí ẹni láyin,
 Ọba atẹ́lẹ̀ bi ẹni tẹ́ní,
 Ọba atẹ́ sánmọ̀ bí ẹní tẹ́sọ, 
 Alọ̀run-layé-alayé-lọ̀run, 
 Olọ́wọ́ gbọgbọrọ tí ń yọ ọmọ rẹ̀ nínú ọ̀fìn 
 Atẹ́rẹrẹ káríayé."
Bí a bá ti ojú inú wò ó á ri wí pé àwọn oríkì yìí fi bí Elédùmarè ṣe jẹ́ hàn láwùjọ Yorùbá. Ohun tí a ń sọ ni wí pé ọ̀pọ̀ ìtàn iwásẹ̀ ló ṣàlàyé bi Elédùmarè ṣe dá ayé àti ọ̀run. Èrò Yorùbá ni pé kọ̀ sí ohun ti a lẹ̀ fi wé Elédùmarè ní torí àwọn àwòmọ́ tàbí àbùdá rẹ̀ tó tayọ àwárí ẹ̀dá. Fún àpẹẹrẹ, Ẹlédàá, Alẹ̀mí, Òun ló ni ọ̀sán àti òru, Ọlọ́jọ́ òní, òní ọmọ ọlọ́rin ọ̀la ọmọ ọlọ́run ọ̀tunla ọmọ ọlọrin, ìrèmi ọmọ ọlọrin, òrún ni ọmọ ọlọ́rin. 

Yorùbá máa ń sọ wí pé iṣẹ́ ọlọ́run tóbi tàbí àwámárídì ni iṣẹ́ olódùmarè. ọ̀rúnmìlà lọ́ fẹ̀yìntì, ó wo títítítí ó ní ẹ̀yin èrò òkun, ero ọ̀sà ǹ jẹ́ ẹ̀yin ò mọ̀ wí pé iṣẹ́ elédùmarè tòbí. Olódùmarè gẹ́gẹ́ bí alágbaára láyé àti lọ́run a dùn ń se bí ohun tí elédùmarè lọ́wọ́ sí a sòro se bí ohun tí elédùmarè kò lọ́wọ́ sí, a lèwí lese, asèkanmákù, ohun tí Yorùbá rò nípa elédùmarè ni wí pé kò sí nǹkan tí kò le se àti wí pé ohunkíhun tí ó bá lọ́wọ́ sí ó di dandan kí ó jẹ́ àseyọrí àti àseyege. Ní ọ̀nà míràn Yorùbá tún gbàgbọ́ wí pé ọlọ́run nìkan ni ó gbọ́n, ìdí ni ìyí tí Yorùbá fi máa ń sọ ọmọ wọn ní Ọlọ́rungbọn elédùmarè rí óhun gbogbo, ó sì mọ ohun gbogbo arínúríde, olùmọ̀ràn ọkàn. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé ojú ọlọ́run ni sánmọ̀ Yorùbá sọ wí pé amùokùn sìkà bí ọba ayé kòrí o, Ọba ọ̀rùn ń wò ọ́, ki ni ẹ̀ ń se ní kọ̀kọ̀ tí ojú ọba ọ̀run kò tó. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé elédùmarè ni olùdájọ́ ìyẹ ni wí pé elédùmarè ni adájọ́ tó ga jù láyé àtọ̀run, òun ni ọba adákẹ́ dájọ́, àwọn òrìṣà ló, máa ń jẹ àwọn orúfin níyà ṣùgbọ́n ọlọrun ló ń dájọ́. Bí àpẹẹrẹ ní ìgbnà kan láyé ọjọ́un àwọn òrìṣà fẹ̀sùn kan ọ̀rúnmìlà níwájú elédùmarè, lẹ́yìn tí tọ̀tún tòsì wọn rojọ́ tán elédùmarè dá ọ̀runmìlà láre. Odù ifá kan ọ báyìí wí pé Ọ̀kánjúà kìí jẹ́ kí á mọ nǹkanán-pín, adíá rún odù mẹ́rìndínlógún níjọ́ tí wọ́n ń jìjà àgbà lọ ilé elédùmarè, nìgbà tí àwọn ọmọ irúnmọlẹ̀ mẹ́rìndínlógún ń jìjà tani ẹ̀gbọ́n tan i àbúrò, wọ́n kí ẹjọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ elédùmarè, níkẹyìn elédùmarè dájọ̀ wí pé èjìogbè ni àgbà fún àwọn Odù yókù. Yorùbá gbàgbọ́ wí pé onídájọ́ ododo ni elédùmarè ìdí nì yí tí Yorùbá fi máa ń sọ wí pé ọlọ́run mún-un tàbí ó wa lábẹ́. Pàsán ẹlẹ́dùmarè Ní ọ̀nà míràn Yorùbá gbàgbọ́ wípé ọta àìkú ni elédùmarẹ̀ Yorùbá máa ń sọ wípé rẹ̀rẹ̀kufẹ̀ a kì í gbọ́ ikú elédùmarè. Ẹsẹ ifá kan ìyẹn ni ogbè ìyẹ̀fún sọ fún wa wí pé: -

Rèròfo awo àjà ilẹ̀

Ló dífá fún elédùmarè

Tí ó sọ wí pé wọn ò ní gbọ́ ikú rẹ laalaa.

Ní àkótán Yorùbá gbàgbọ́ wí pé ọba tó mọ́ Ọba tí je ni èérí ni elédùmarè ń se. Òun ni àwọn Yorùbá ń pè ní alálàfunfun ọ̀kàn àwọn Yorùbá gbàgbọ́ wí pé bí àwọn ángẹ́lù ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún elédùmarè lóde ọ̀rùn bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn òrìṣà jẹ́ orùrànlọ́wọ́ fún elédùmarè lóde ayé. Awọn òrìṣà wọ̀nyí sì ni wọ́n jẹ́ alágbàwí fún àwọn ènìyàn lọ́dẹ̀ elédùmarè.


Àwọn ìtọ́ka sí

àtúnṣe