Eleanor Nabwiso
Eleanor Vaal Nansibo Nabwiso jẹ́ òṣèré àti adarí eré lórílẹ̀-èdè Uganda. Ó gbajúmọ̀ fún ipa tí ó kó nínú eré The Hotel[1], Rain[2], Beneath the Lies- The Series àti Bed of Thorns gẹ́gẹ́ bí oludarí àwọn eré náà.[3] Ó dá ilé iṣẹ́ tó má ń gbé eré jáde kalẹ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, ó sì pèé ní Nabwiso Films.[4]
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Nabwiso sí ilé ìwòsàn ti Sir Albert Cook Mengo Hospital. Bàbá rẹ̀ ni Rev. Dr. Kẹfa Sempangi, orúkọ ìyá rẹ sí jẹ́ Jane Frances Nakamya. Òun ni ọmọ kẹta nínú àwọn ọmọ márùn-ún tí àwọn òbí rẹ bí. Bàbá rẹ̀ ni olùdásílẹ̀ ilé ìjọsìn ti Presbyterian Church ní orílẹ̀ èdè Uganda.[5] Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Namagunga Girls' Primary School àti Seeta High School kí ó tó tẹ̀ síwájú sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Sikkim Manipal University níbi tí ó tí gboyè nínú ìmò Science.[6]
Iṣẹ́
àtúnṣeNabwiso bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe nígbà tí ó ṣì wà ní ọmọdé. Ó kópa nínú eré K-Files nígbà tí ó sì wà ní ilé ìwé. Ó kópa nínú eré The Hostel èyí tí ó ṣọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé àwọn ọmọ ilẹ̀ ìwé yunifásítì. Ó kópa nínú eré Kyaddala tí Emmanuel Ikubese ṣe adarí rẹ̀. Lára àwọn eré tí ó tí ṣe ni Reach a Hand, #Family, Beneath The Lies, Watch Over Me àti Bed of Thorns. Ní ọdún 2018, ó gbà àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèré tó dára jù lọ níbi ayẹyẹ Uganda Film Festival Awards.[7] Wọ́n yàán fún àmì ẹ̀yẹ Best Feature Award láti ọ̀dọ̀ London Arthouse Film Festival Award àti Africa Focus Award fún ipa tí ó kó nínú eré Bed of Thorns.[8][9]
Ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeÓ jẹ́ ìyàwó fún Matthew Nabwiso tí ó jẹ́ òṣèré àti olórin, wọ́n sì ti bí ọmọ mẹ́rin.[10][11]
Àwọn Ìtọ́kàsi
àtúnṣe- ↑ Kamukama, Polly. "Babe of the Week: The Hostel's Nansibo shares her life in the spotlight". The Observer - Uganda (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-10-14. Retrieved 2020-03-10.
- ↑ Andrew Kaggwa. "Is this time for Ugandan film on the African stage? – Sqoop – Its deep" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-10.
- ↑ Akasula, Nicolas. "Eleanor Nabwiso's 'Bed of Thorns', scoops award in the UK – Sqoop – Its deep" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-10.
- ↑ Nantaba, Agnes (2017-09-27). "Eleanor Nansibo Nabwiso: Young actress eyes global success". The Independent Uganda (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-07.
- ↑ "Kefa Sempangi dedicated his life to the vulnerable - National | NTV". www.ntv.co.ug. Retrieved 2020-03-07.
- ↑ Nantaba, Agnes (2017-09-27). "Eleanor Nansibo Nabwiso: Young actress eyes global success". The Independent Uganda (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-07.
- ↑ filmblogafrica (2019-12-01). "Uganda Film Festival Awards 2019 winners announced in Kampala.". Film Blog Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-03-17. Retrieved 2020-03-10.
- ↑ "LAHFF 2019 Films - London Arthouse Film Festival". LAHFF. https://lahff.uk/lahff-2019-films/. Retrieved 14 October 2019.
- ↑ "Ugandan movie 'Bed Of Thrones' (Tosirika) wins at London Art House Film Festival". Doberre. Archived from the original on 16 October 2020. https://web.archive.org/web/20201016203752/https://doberre.com/ugandan-movie-bed-of-thrones-tosirika-wins-at-london-art-house-film-festival/. Retrieved 14 October 2019.
- ↑ "Eleanor and Matthew Nabwiso's fairytale". Daily Monitor (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-07.
- ↑ "CONGRATULATIONS! A fourth child for the Nabwisos". MBU (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-09. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)