Elechi Amadi
Elechi Amadi (Ọjọ́ kejìlá, Oṣù Èbìbí, Odjny 1934 - Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, Oṣù Òkudù, Ọdún 2016) jẹ́ òǹkọ̀wé àti jagunjagun ọmọ Orílẹ̀èdè Nàìjíríà. Ọmọ ẹgbẹ́ àwọn ológun ilẹ̀ Nàìjíríà ni tẹ́lẹ̀. Òǹkọ̀wé àwọn eré onísẹ́ àti ìtàn àròsọ ni tí wọ́n dálé ìgbéayé abúlé Adúláwọ̀, ìṣe, ìgbàgbọ́ àti àwọn ìṣẹ̀sìn ṣáájú ìbáṣepọ̀ ọ̀làjú òyìnbó. Iṣẹ́ Amadi tí ó peregede ní ìwé ìtàn àròsọ tí i ṣe igi àkọ́sẹ́ rẹ̀ "The Concubine" tí wọ́n sọ pé òun ló tayọ jù nínú ìtàn àròsọ. .[1]
Elechi Amadi | |
---|---|
Ọjọ́ ìbí | Naijiria | 12 Oṣù Kàrún 1934
Ọjọ́ aláìsí | 29 June 2016 Port Harcourt | (ọmọ ọdún 82)
ÌBẸ̀RẸ̀PẸ̀PẸ̀ AYÉ ÀTI ÈTÒ Ẹ̀KỌ́
àtúnṣeIṢẸ́
àtúnṣeIṢẸ́. Ó siṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí awọnlẹ̀ nígbà kan rí, ó sì padà ṣiṣẹ́ Olùkọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ẹ̀kọ́, lára wọn ni Iléẹ̀kọ́ àwọn Ológun ilẹ̀ Nàìjíríà, ní ìlú Zaria láàárín ọdún 1963 - 1966. Ó siṣẹ́ olùkọ́ ní Iléẹ̀kọ́ olùkọ́ni tí Ìpínlẹ̀ Rivers bákan tí ó ti jẹ́ alákòóso agbo ẹ̀ka ìmọ̀ ajẹ́mọ́ṣẹ́ ọnà, bákan náà olórí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ lítíréṣọ̀ àti Olùdarí ẹ̀kọ́ áṣekárí
IṢẸ́ OLÓGUN ÀTI ÒṢÈLÚ
Amadi ṣisẹ́ pẹ̀lú àwọn ológun, ó sì dúró níbẹ̀ lásìkò ogun Abẹ́lé Nàìjíríà, kí ó tó wá fẹ̀yìntì gẹ́gẹ́bí ọ̀gágun. Ìjọba Ìpínlẹ̀ Rivers yàn án sí oríṣìíríṣìí ipò: ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ ní ọdún 1973 - 1983, kọmísọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ ní ọdún 1987 - 1988 àti kọmísọ́nà fún ilẹ̀ ati ilé ní ọdún 1989 sí 1990
Ọdún 1934 ni wọ́n bí Elechi Amadi ní Aluu, Ìjọba Ìbílẹ̀ Ikwere ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nàìjíríà. Ó lọ sí Kọ́lẹ́jì Ìjọba ní ọdún 1948 - 1952, bákan náà ló lọ sí Survey School ní ìlú Ọ̀yọ́, ó tẹ̀síwájú sí Yunifásítì ti Ìbàdàn láàárín ọdún 1955 sí ọdún ọdún 1959, ó sì gba oyè ẹ̀kọ́ nínú Èkọ́ Físíìsì àti Èkọ́ Ìṣirò.
Àwọn ìwé tó kọ
àtúnṣe- The Concubine (1966)
- The Great Ponds (1969)
- Sunset in Biafra (1973)
- Dancer of Johannesburg (1978)
- The Slave (1978)
- Estrangement (1986)
- Speaking and Singing (2003)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Liukkonen, Petri. "Elechi Amadi". Books and Writers (kirjasto.sci.fi). Finland: Kuusankoski Public Library. Archived from the original on 10 February 2015.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |