Elizabeth Olsen
Elizabeth Chase Olsen (tí a bí ní ọjọ́ kẹríndínlógún oṣù kejì ọdún 1989) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Wọ́n bi ní Sherman Oaks, California, Olsen ti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe láti ìgbà tí ó ti jẹ́ ọmọ ọdún merin. Ó kópa nínú fíìmù fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú fíìmù Martha Marcy May Marlene ní ọdún 2011, ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ Critics' Choice Movie Award nítorí ipa rẹ̀ nínú fíìmù náà. Olsen tún padà gba àmì-ẹ̀yẹ BAFTA Rising Star Award ní New York University lẹ́yìn ọdún méjì.
Elizabeth Olsen | |
---|---|
Olsen ní ọdún 2019 | |
Ọjọ́ìbí | Elizabeth Chase Olsen 16 Oṣù Kejì 1989 Sherman Oaks, California, U.S. |
Iléẹ̀kọ́ gíga | New York University |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 1994–present |
Olólùfẹ́ | Robbie Arnett |
Àwọn olùbátan |
|
Olsen gbajúmọ̀ káàkiri àgbáyé fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Wanda Maximoff / Scarlet Witch nínu àwọn fíìmù Marvel Cinematic Universe, ó wà nínú àwọn fíìmù bi Avengers: Age of Ultron (2015), Captain America: Civil War (2016), Avengers: Infinity War (2018), Avengers: Endgame (2019), àti Doctor Strange in the Multiverse of Madness (2022), pẹ̀lú pẹ̀lú WandaVision (2021).