Elvan Abeylegesse, (tó fìgbà kan jẹ́: Hewan Abeye (አልቫን አበይለገሠ, ní èdè Amharic) àti Elvan Can (ní orílẹ̀-èdè Turkey) ni a bí ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù September ní ọdún 1982 jẹ́ eléré ìdárayá tó máa ń sáré ọlọ́nà jínjìn ta bí sí orílẹ̀-èdè Ethiopia. Arábìnrin náà ti kópa nínú eré ìdíje ti marathon fún 1500 metres[1][2][3].

Elvan Abeylegesse
Elvan Abeylegesse
Òrọ̀ ẹni
Ọmọorílẹ̀-èdèTurkish
Ọjọ́ìbí11 Oṣù Kẹ̀sán 1982 (1982-09-11) (ọmọ ọdún 42)
Addis Ababa, Ethiopia
IbùgbéIstanbul, Turkey
Height1.59 m (5.2 ft)
Weight40 kg (88 lb)
Sport
Erẹ́ìdárayáRunning
Event(s)5000 metres, 10,000 metres
ClubEnkaspor Athletics Team
Coached byCarol Santa
Achievements and titles
Personal best(s)5000m: 14:24.68
10000m: 29:56.34

Ìgbésí ayé eléré ìdárayá náà

àtúnṣe

Abeylegesse ni a bí sí Addis Ababa, Ethiopia. Ní ọdún 2011, oṣù February, Elvan fẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀ ìgbà pípẹ́ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Semeneh Debelie[4]. Ní ọdún 2011, oṣù July arábìnrin náà bímọ obìnrin, tí wọ́n sọ ni Arsema.

Àṣeyọrí

àtúnṣe

Ní ọdún 1999, Elvan kópa nínú ìdíje IAFF Cross ti àgbáyé fún àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ ti ilẹ̀ Ethiopia ní Belfast, Northern Ireland níbi tó ti parí pẹ̀lú ipò kẹsàn-án. Ní eré ti Evergood Bergen Bislett Games tó wáyé ní Norway, oṣù June, ní ọdún 2004 Abeylegesse yege nínú record àgbáyé àwọn obìnrin ti 5000m[5][6]. Ní ọdún 2010, Abeylegesse gba wúrà ní marathon ti 10,000m nínú ìdíje ti eré-ìdárayá ti orílẹ̀-èdè Ethiopia níbi tí arábìnrin náà ti parí pẹ̀lú ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lé ní ẹyọ̀kan, ìṣẹ́jú àáyá ti 10.23[7].

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Elvan Profile
  2. Elvan ABEYLEGESSE Profile
  3. women’s race, a group of 10 runners emerged after 5km
  4. Abeylegesse married her long-time boyfriend Semeneh Debelie
  5. Olympic Records
  6. Abeylegesse obliterates the women's 5000m World record
  7. 12th IAAF World Championships in Athletics