Emirate of Say jẹ́ ilẹ̀ Mùsùlùmí kan tí Alfa Mohamed Diobo, adarí Qadiriyya Sufi kan dá kalẹ̀ ní ọdún 1825, Mohamed wá sí Say àti Djenné ( ni Mali) ní ọdún 1810. Bí ó tilè jẹ́ pé Diobo kìí ṣe akọ́gun wọ̀lú, ó sì láṣẹ lórí Say nítorí pé ó jẹ́ Alfa àti pé ó wà lára àwọn tí ó dà àbò bo Sokoto Empire, tí àlùfáà Qadiriyya Sufi, Usman Dan Fodio kalẹ̀.

Emirate of Say

1825
OlùìlúSay
Àwọn èdè tówọ́pọ̀Arabic, Fulani, Songhay, Zarma
Ẹ̀sìn
Islam
List of rulers of Say 
• 1825—1834
Alfa Mohamed Diobo
• 1834-1860
Boubacar Modibo
Ìtàn 
• Dídásílẹ̀
1825
Today part of

Nígbà tí ó sì gbajúmọ̀, emirate of Say jẹ́ ibi tí àwọn ènìyàn mọ̀ láti Gao dé Gaya gẹ́gẹ́ bi ibi tí wọn ti ń kó nípa ẹṣin Islam. Àwọn adarí ìlú Say láti ọdún mọ́dún jẹ́ àwọn ìran Diobo. Àwọn ni; Alfa Mohamed Diobo (1825—1834), Boubacar Modibo (1834–1860), Abdourahman (1860–1872), Moulaye (1872–1874), Abdoulwahidou (1874–1878), Saliha Alfa Baba (1878–1885), Amadou Satourou Modibo (1885—1893), Halirou Abdoulwahabi (1893—1894).[1][2]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Idrissa, Abdourahmane; Decalo, Samuel (2012), Historical Dictionary of Niger by Abdourahmane Idrissa, Samuel Decalo, Page 399, ISBN 9780810870901, retrieved 2021-03-18 
  2. Seeda (2014), Qui est Alpha Mahaman Diobbo ?, Niamey.com, retrieved 2021-03-18