Emma Dabiri
Emma Dabiri FRSL (tí wọ́n bí ní 25 March 1979) jẹ́ òǹkọ̀wé, onímọ̀ àti akàròyìn ọmọ orílẹ̀-èdè Ireland. Ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ ni àkọlé rẹ̀ ń jẹ́, Don't Touch My Hair, ni ó tẹ̀ jáde ní ọdún 2019. Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ he Royal Society of Literature ní ọdún 2023.[1]
Emma Dabiri | |
---|---|
Dabiri in 2021 | |
Born | Dublin, Ireland |
Alma mater | |
Influences |
Ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeÌlú Dublin ni wọ́n bí Dabiri sí, ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ireland, bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Yorùbá, láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lẹ́yìn tó lo ìbẹ̀rẹ̀ ọdún rẹ̀ ní ìlú Atlanta, ní Georgia, ìdílé rẹ̀ padà lọ sí Dublin, nígbà tí Dabiri wà ní ọmọ-ọdún márùn-ún.[2] Ó ní pé òun dá wà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà, nígbà tí òun ń dàgbà nítorí ẹlẹ́yàmẹyà.[3] Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó kó lọ sí ìlú London láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa African Studies ní School of Oriental and African Studies. Ẹ̀kọ́ rè ló mu bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akàròyìn, ó sì jẹ́ olóòtú ètò BBC Four's Britain's Lost Masterpieces, ètò orí Channel 4, bí i Is Love Racist?, àti ètò orí rédíò kan tó pè ní Afrofuturism, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[4]
Àwọn ìwé rẹ̀
àtúnṣe- Don't Touch My Hair, London: Allen Lane (an imprint of Penguin), 2019. Hardback ISBN 9780241308349 Ebook ISBN 9780141986296
- What White People Can Do Next: From Allyship to Coalition, Penguin, 2021. ISBN 9780141996738.
- Disobedient Bodies: Reclaim Your Unruly Beauty, Wellcome Collection, 2023. ISBN 9781800817920.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Creamer, Ella (12 July 2023). "Royal Society of Literature aims to broaden representation as it announces 62 new fellows". The Guardian. https://www.theguardian.com/books/2023/jul/12/royal-society-of-literature-aims-to-broaden-representation-as-it-announces-62-new-fellows.
- ↑ Dabiri, Emma (27 April 2019). "I'm Irish but not white. Why is that still a problem 100 years after the Easter Rising?". Irish Times. https://www.irishtimes.com/news/ireland/irish-news/i-m-irish-but-not-white-why-is-that-still-a-problem-100-years-after-the-easter-rising-1.2590841.
- ↑ Ganatra, Shilpa (27 April 2019). "Emma Dabiri: 'I wouldn't want my children to experience what I did in Ireland'". Irish Times. https://www.irishtimes.com/life-and-style/people/emma-dabiri-i-wouldn-t-want-my-children-to-experience-what-i-did-in-ireland-1.3866197.
- ↑ "Irish writer and actor among the rising stars of 2019". Irish Central. 11 January 2019. https://www.irishcentral.com/culture/entertainment/irish-rising-stars-2019.