Eniola Abioro (ti á bí ní ọdún 1999) jẹ́ módẹ́lì ẹ̀ṣọ́ aṣọ ti Nàìjíríà. O jẹ módẹ̀lì Nàìjíríà akọkọ láti rìn fún Prada .

Ìgbésí Ayé Èwe

àtúnṣe

Abioro jẹ́ ọmọ àárín ní ìdílé rẹ̀; ó ní ẹ̀gbọ́n ọkùnrin kan àti àbúrò obìnrin kan Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àwọn ọmọdé ní Ilé Ìwé kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Grace Academy ní Ìpínlẹ̀ Èkó, ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Olùdarí ilé iṣẹ́ kékeré kan ni ó ṣe àwárí rẹ̀ tí ó sì yi àwọn ẹbí rẹ̀ ni ọkàn padà láti fún láyé àti má ṣe iṣẹ́ módẹ́lì ẹ̀ṣọ́ aṣọ.

Iṣẹ́ Rẹ̀

àtúnṣe

Abioro fọwọ́ síwe pẹ̀lú Next Management o sì di gbígbà wọlé gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ tún tún àti òṣìṣẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ ti Prada ni ọdún 2018. Ó rìn ojú òpópónà fun Versace, Giambattista Valli, Tommy Hilfiger, Off-White, Miu Miu, Saint Laurent, Paco Rabanne àti Loewe, Salvatore Ferragamo àti Altuzarra . Ó tún rìn fún Jason Wu ó ṣe iṣẹ́ módẹ́lì fún Revlon, Fenty Beauty, Calvin Klein àti Tiffany ati Co. Lẹ́yìn ìgbà iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́, àwọn models.com pè ní 'Ṣẹ̀ṣẹ̀ dé tí ó pógo já' àti ọ̀kan lára àwọn 'àádọ́ta tí ó pógo já' tí wọ́n ní.

Abioro ti fara hàn nínú àwọn ìwé tí a tẹ̀ jáde fun Vogue, Harper's Bazaar, Vogue Italia, WSJ àti Elle .