Pastor Enoch Adéjàré Adébóyè, ẹni tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kejì oṣù kẹta (oşù Ęrénà) ọdún 1942, jẹ́ òjíṣẹ̀ Ọlọ́run ọmọ bíbí Ifẹ̀wàrà ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni Pásítọ̀-àgbà yànyàn ati Olùdarí ìjọ oníràpadà, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ìjọ Ìràpadà Ti Krístì (The Redeemed Christian Church of God).[1][2]

Enoch Adejare Adeboye
Enoch Adeboye
Ọjọ́ìbí2 Oṣù Kẹta 1942 (1942-03-02) (ọmọ ọdún 82)
Ifewara, Osun State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Pastor, profesor
EmployerRedeemed Christian Church of God, University of Lagos
Olólùfẹ́
Foluke Adenike Adeboye (m. 1967)
WebsiteÀdàkọ:Official URL

Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Òjíṣẹ́ Ọlọ́run àgbà yìí, Enoch Adéjàré Adébóyè ní Ọjọ́ kejì oṣù kẹta ọdún 1942 ni Ifẹ̀wàrà ni ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ìlú Ifẹ̀wàrà wà ní ìtòsí Ilé-Ifè. Ó kàwé gboyè dìgírì àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ ìṣirò/Matimátììkì (Mathematics) ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ifáfitì ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó (The University of Lagos) l'ọ́dún 1967. Ṣíwájú àkókò yìí, ó ti kọ́kọ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ifáfitì Nàìjíríà (The University of Nigeria, UNN) ní ìlú Nsukka ṣùgbọ́n Ogun Biafra kò jẹ́ kó kàwé gboyè níbẹ̀. Ó fẹ́ aya rẹ̀, Folúkẹ̀ Adéníkẹ̀ẹ́ ní ọdún 1967 bákan náà, wọ́n sì bímọ mẹ́rin.[3] Lọ́dún 1969, ó kàwé gboyè dìgírì kejì (Master Degree) nínú ìmọ̀ ìṣowó-ṣàn-omi àti àwọn ohun tó jo omi (hydrodynamics) láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ifáfitì Ìpínlẹ̀ Èkó (University of Lagos) bákan ná à. Ó dára pọ̀ mọ́ Ìjọ Ìràpadà, the Redeemed Christian Church of God ní ọdún 1973, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Oǹgbufọ̀ fún Pásítọ̀ ìjọ náà nígbà náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pásítọ̀ Josiah Olúfẹ́mi Akíndayọ̀mi. Lọ́dún 1975, ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́, ó sì kàwé gboyè Ọ̀mọ̀wé (Ph.D.) nínú Àmúlò Matimátíìkì (Applied Mathematics) láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ifáfitì Ìpínlẹ̀ Èkó (University of Lagos) kan ná a (University of Lagos). Ó sì tún padà gboyè ọ̀jọ̀gbọ́n (Professor) nínú ìmọ̀ ìṣirọ̀ ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Ifáfitì Ìpínlẹ̀ Èkó (University of Lagos) òhún pèlú.[4] [5]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. About the author (2019-12-15). "Pastor Enock Adeboye: Trademark of humility – Zambia Daily Mail". Zambia Daily Mail – Without fear or Favour. Retrieved 2019-12-15. 
  2. vanguard (2018-03-02). "76 Garlands for Adeboye". Vanguard News. Retrieved 2019-12-15. 
  3. Ikeke, Nkem (2015-02-21). "Pastor Adeboye Reveals 4 Equations Of Marriage (NO. 3 Will Make You Laugh)". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2019-12-15. 
  4. Published (2015-12-15). "Adeboye's story: From lecture hall to global pulpit". Punch Newspapers. Retrieved 2019-12-15. 
  5. "Obafemi Awolowo University, Ile-Ife » Endowment of Professorial Chair in Mathematics: Pastor Adeboye gives fifty (50) Million Naira to OAU". oauife.edu.ng. 2014-06-05. Archived from the original on 2014-06-05. Retrieved 2019-12-15.