Àdàkọ:Infobox museum

Mùsíọ̀mù Esiẹ jẹ́ Mùsíọ̀mù ní ilẹ̀ Esiẹ, ní Ìpínlẹ̀ Kwara, ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ní abúlé Igbomina náà ìlú Esie, ní Ìjọba ìbílẹ̀ Ìrẹ́pọ̀dùn ní ìpínlẹ̀ Kwara jẹ́ mùsíọ̀mù àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Wọ́n dá mùsíọ̀mù náà lẹ̀ ní ọdún 1945 láti kó ọ̀kan lára àwọn ìṣúra tó ga jùlọ tí ó ṣe iyebíye sí ìran ènìyàn, àwọn àwòrán òkúta Esiẹ (Ere Esie).

Mùsíọ̀mù yìí jẹ́ Alàkọ́kọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ dá sílẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nígbà tí wọ́n ṣíi ní ọdún 1945.[1] Mùsíọ̀mù yìí fẹ̀kàn tẹ́lẹ̀ rí gba ọgọ́rùn-ún àwọn ère olókùúta itẹ́kù tí wọ́n fi dípò àwọn ènìyàn.[2]

Mùsíọ̀mù Esie ni wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1945 tí ó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun ti ìpínlẹ̀ Kwara. Wọ́n mọ mùsíọ̀mù yìí sí tí tọ́jú àwọn ère òkúta tí wọ́n gbẹ́ bíi ènìyàn.

Ìwúrí ni láti ní àtòpọ àwọn àwòrán ère olókúta tí ó pọ̀jù lọ lágbàáyé.[3] Láyé òde-òní mùsíọ̀mù Esie tí di gbọ̀ngán ètò ẹ̀sìn àti ibi tí wón ti ń ṣe ayẹyẹ ní oṣù kẹrin gbogbo ọdún.[4]

Ìtàn gbajúgbajà náà sọ pé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn àwọn olùgbé ìlú náà ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú ńlá kan tí àrá sì sán pa gbogbo wọn yí wọn padà sí òkúta.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "(PDF) NIGERIA SCULPTURAL TRADITION AS VIABLE OPTION FOR TOURISM PROMOTION: AN ASSESSMENT OF ESIE MYSTERIOUS STONE SCULPTURES". ResearchGate (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-21. 
  2. "Esie: Nigeria’s first museum, generates N10,000 monthly". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-21. 
  3. "Esie Museum". All Africa. Retrieved 1 February 2013. 
  4. "Tourism". Nigerian Embassy, Budapest, Hungary. Retrieved February 1, 2013. 

Àdàkọ:Museums in Nigeria

Àdàkọ:Coord missing


Àdàkọ:Nigeria-museum-stub