Evans Hunter
Evans Nii Oma Hunter (kú ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹfà, ọdún 2013) jẹ́ òṣèrẹ́kùnrin tó jẹ́ àgbà òṣèré, àṣàgbéjáde àti olùdarí fíìmù, tí ó sì tún máa ń kọ ìwé. Ó ti dá sí ìdàgbàsókè fíìmù àti ilé-iṣẹ́ orí-ìtàgé.[1]
Evans Hunter | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Evans Nii Oma Hunter |
Aláìsí | 4th of June, 2013 |
Orílẹ̀-èdè | Ghanaian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Ghanaian |
Iṣẹ́ |
|
Gbajúmọ̀ fún | King Ampaw, Testament, No time to die, A mother's Tears |
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
àtúnṣeÓ jẹ́ Ààrẹ ẹgbẹ́ Ghana Actors Guild (GAG) láti ọdún 1989 wọ ọdún 1996, òun sì ni olùdásílẹ̀ Audience Awareness Artistic Organisation.[2]
Ní ọdún 1983, ó kópa gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀dá-ìtàn Addey nínú fíìmù tí King Ampaw darí, èyí tó jé fíìmù apanilẹ́rìn-ín tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Kukurantumi. Ní ọdún 1988, ó kópa gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀dá-ìtàn Rashid nínú fíìmù tí John Akomfrah, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Testament. Àwọn ẹ̀dá-ìtàn mìíràn tí ó ṣe ní Francis Essien ní fíìmù ọdún 1989 tí Kwaw Ansah darí, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Heritage Africa, àti bíi Kokuroko nínú fíìmù apanilẹ́rìn-ín ti ọdún 2006 tí King Ampaw darí, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ No Time to Die, àti ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù Kwaw Ansah, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ A Mother's Tears.[3][4][5]
Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀
àtúnṣe- Kukurantumi (1983) bíi Addey
- No Time to Die (2006) bíi Kokuroko
- Ama
- Heritage Africa (1989) bíi Francis Essien
- The Fortune Island
- Testament(1988) bíi Rashid
- Nana Akoto (1985)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Empty citation (help)
- ↑ "Actor Evans Oma Hunter To Be Buried August 3". Peace FM Online. 15 July 2013. Retrieved 14 April 2021.
- ↑ "Tributes flow for Evans Hunter". Modern Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-11-21.
- ↑ Online, Peace FM. "Actor Evans Oma Hunter To Be Buried August 3". Peacefmonline.com - Ghana news. Retrieved 2020-11-21.
- ↑ "Evans Hunter goes home today | GhHeadlines Total News Total Information". ghheadlines.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 17 August 2013. Retrieved 2020-11-21.