Ewé Ìyànà Ìpájà tí wọ́n sábà máa ń pè ní "hospital-too-far" tabi "Jatropha tanjorensis" jẹ́ ti ìdílé Euphorbiaceae àti pé ó gbajúmọ̀ nípa bí ó ṣe ń wù ní Gúúsù Nàìjíríà. Ní àdúgbò, a ti lo ọgbìn náà gẹ́gẹ́ bí orísun ewéko tí a lè jẹ àti gẹ́gẹ́ bí oògùn. Nínú ewé náà ní èròjà hypoglycemic àti àwọn èròjà tó ń dáàbò bo àwọn sẹ́ẹ̀lì kúrò lọ́wọ́ ìpalára wà, èyí tó jẹ́ kí ó gbajúmọ̀ fún ìtọ́jú àrùn àtọ̀gbẹ, àìsàn ibà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ewé Ìyànà Ìpájà
Alternative namesJatropha tanjorensis, Hospital-Too-Far
TypeẸ̀fọ́
Place of originNàìjíríà
Region or stateGúúsù ìwọ̀ oòrùn
Àdàkọ:Wikibooks-inline 

Àwọn Àǹfààní

àtúnṣe

Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní tí ewé yìí ní ni pé ó ní ọ̀pọ̀ èròjà nínú, ó máa ń ṣèrànwọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro tó jẹ mọ́ ẹ̀jẹ̀ bí àìníẹ̀jẹ̀ tó tó àti àrùn àtọ̀gbẹ. Ó ń ṣèrànwọ́ fún bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń ṣàn fàlà, ó ń mú kí ìfúnpá rẹ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, àti àwọn ìṣòro mìíràn tó jẹ mọ́ ẹ̀jẹ̀.[1]

Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Exploring the Health and Healing Properties of Efo Iyana Ipaja (Tree Spinach) in My Gardens". PeakD. Retrieved 2024-11-07.