Ewébẹ̀ ni àwọn ewéko tí ènìyàn tàbí ẹranko mìíràn máa ń jẹ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ. [1][2] Ènìyàn lè se ewébẹ̀ jẹ tàbí kí wọ́n jẹ ẹ́ ní tútù. Àǹfààní pọ̀ jáǹtirẹrẹ nípa jíjẹ ewébẹ̀, pàápàá jù lọ nínú àgọ́-ara ènìyàn. Púpọ̀ nínú àwọn ewébẹ̀ ló kún fún àwọn èròjà aṣaralóore bíi èròjà-ara afúnnilókun (carbohydrate), èròjà-ara amúnidàgbà (protein), ọ̀rá (fat) àti àwọn èròjà-ara amárajípépé (vitamins). [3] [4]. Oríṣiríṣi ewébẹ̀ ló wà, fún àpẹẹrẹ, ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, ẹ̀fọ́ ṣọkọ, ìgbó, ewédú, ilá, gbúre àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, àwọn Wọ́n máa ń ka àwọn èso jíjẹ mìíràn sí ewébẹ̀. [5]

Àwọn Ìtọ́kasíÀtúnṣe

  1. "vegetable - Description, Types, Farming, & Examples". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2020-05-13. 
  2. "Definition of VEGETABLE". Definition of Vegetable by Merriam-Webster. 2017-07-20. Retrieved 2020-05-13. 
  3. "Vegetables A-Z". Vegetables. Retrieved 2020-05-13. 
  4. "Definition of vegetable". www.dictionary.com. 2014-12-27. Retrieved 2020-05-13. 
  5. Abadi, Mark (2018-06-24). "14 vegetables that are actually fruits". Business Insider. Retrieved 2020-05-13.