Ewúro tí ó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára ẹbí asteraceae, jẹ́ ewébẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Ewúro
Veronica amygdalina
Ìṣètò onísáyẹ́nsì
Ìjọba:
Ará:
Tracheophyta
Ẹgbẹ́:
Magnoliopsida
Ìtò:
Asterales
Ìbátan:
Vernonia
Irú:
Vernonia amygdalina

Ìrísí rẹ̀

àtúnṣe

Igi ewúro máa ń ga nílẹ̀ tó iye bàtà 2–5 m (6.6–16.4 ft). Tí ewé rẹ̀ sì máa ń gùn tó 20 cm (7.9 in) níye, ẹ̀yìn ewé náà kò sì dán mọ́rán.[1].

Àwọn orúkọ tó ń jẹ́

àtúnṣe

Ewúro ni wọ́n máa ń pè ní bitter leaf ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, nítorí adùn kíkorò tó ní. Wọ́n máa ń pè ní grawa ní èdè Amharic, etidot ní èdè Ibibio, onugbu ní èdè Igbo, ityuna ní èdè Tiv, oriwo ní èdè Ẹdó, awɔnwono ní èdè Akan, Shuwaka/Chusar doki ní èdè Haúsá, mululuza ní èdè Luganda, labwori ní èdè Acholi, olusia ní èdè Luo, àti ndoleh ní orílẹ̀-èdè Cameroon.[2][3][4]

Ìwúlò Ewúro

àtúnṣe

Fún ìpèlò ọbẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n máa ń fi ewúro se ọbẹ̀ jẹ nígbà tí wọ́n bá ti gbo adùn kíkorò inu rẹ̀ kúrò pẹ̀lú iyọ̀ àti epo pupa. Lẹ́yìn èyí, kò sóhun tí wọn kò lè fi dá lárà. Wọ́n lè fi se ọbẹ̀, tàbí kí wọ́n sèé pọ̀ mọ́ àsáró iṣu tàbí òmíràn.

Fún ìwòsàn

àtúnṣe

Wọ́n máa ń lo ewé yìí fún ìwòsàn àìsàn Ibà, àárẹ̀ inú, inú rírun, jẹ̀dí-jẹ̀dí, igbẹ́ gbuuru, inú kíkùn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìwúlò rẹ̀ mìíràn

àtúnṣe

Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, wọ́n sábà máa ń jẹ egbò tàbí ẹ̀ka igi yí láti fi ṣe inọ́-tótó èyí, àti láti fi pa àwọn kòkòrò búburú tí ó bá ń ṣàkóbá fún wa lẹ́nu. Ẹ̀wẹ̀, wọ́n ń lo ẹ̀ka igi yí láti fi ṣe ọṣẹ ní orílẹ̀-èdè Ùgáńdà, tí àwọn Gánà náà sì ń lò ó láti fi dènà àrùn ìtọ̀ ṣúgà. [5] [6]

Òwe nípa rẹ̀

àtúnṣe
  • ''Adùn ni ń gbẹ̀yìn ewúro'' - èyí túmọ̀ sí wí pé lẹ́yìn tí a bá ṣiṣẹ́, adùn àti fàájì á tẹ̀lé.
  • ''Ewúro ò fi tojo korò'' - èyí túmọ̀ sí wí pé a ṣe nǹkan tí a gbọdọ̀ ṣe láìka iṣẹ́ tàbí ìfẹ́-ọkàn ẹlòmíì.
  • ''Òjò tó rọ̀ sí ewúro, náà rọ̀ sí ìrèké'' - èyí túmọ̀ sí wí pé ìhùwàpadà ló ń fi ìwà ẹnì kan hàn; lọ́pọ̀ ìgbà, ìkanra ni ìpinnu.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Ijeh II; Ejike CECC (2011). "Current perspectives on the medicinal potential of Vernonia amygdalina Del". J Med Plant Res 5 (7): 1051–1061. 
  2. Àdàkọ:Cite thesis
  3. Kokwaro, John (2009). Medicinal Plants of East Africa 3rd ed. Nairobi, Kenya: University of Nairobi Press. ISBN 978-9966-846-84-6. 
  4. Appiah, Kwame (2018). "Medicinal Plants Used in the Ejisu-Juaben Municipality, Southern Ghana: An Ethnobotanical Study". Medicines 6 (1): 1–27. doi:10.3390/medicines6010001. PMC 6473417. PMID 30577439. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=6473417. 
  5. Asante, Du-Bois et al. (2016). "Antidiabetic Effect of Young and Old Ethanolic Leaf Extracts of Vernonia amygdalina: A Comparative Study". Journal of Diabetes Research 8252741: 8252741. doi:10.1155/2016/8252741. PMC 4884890. PMID 27294153. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=4884890. 
  6. Asante, Du-Bois et al. (2019). "Anti-inflammatory, anti-nociceptive and antipyretic activity of young and old leaves of Vernonia amygdalina". Biomedicine & Pharmacotherapy 111: 1187–1203. doi:10.1016/j.biopha.2018.12.147. PMID 30841432.