Eyín
Eyín jẹ́ ẹ̀yà ara kan tí ó le koko tí kìí rọ̀ tí ó ma ń hù jáde láti inú erìgì nínú ẹnu tí a ma ń lò láti jẹun tàbí fọ́ egungun. Gbogbo eranko tí ó ní egungun lẹ́yìn tí wọ́n sì ma ń rún ónjẹ lẹ́nu ni wọ́n ma ní eyín. Nígbà tí p7pọ̀ nínú wọn ma ń fi eyin ṣọdẹ tàbí dáàbò bo ara wọn lọwọ́ ewu. Àwọn onímọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé eyín kìí ṣe egungun rárá bí ó ti wulẹ̀ kí ó mọ, amọ́ eyín jẹ́ àkójọ pọ̀ àwọn tíṣù kan tí wọ́n ń pè ní ectoderm ni wọ́n para pọ̀ di eyín.

Híhù eyín láàrín àwọn ẹrankoÀtúnṣe
Híhù eyín láàrín àwọn ẹranko elégungun ma ń sábà jẹ́ bá ká ń náà, àmọ́ ìyàtọ̀ ma ń wà láàrín ipò àti bí wọ́n ṣe ń hù láàrín ẹranko sí ẹranko. Kìí ṣe àwọn ẹranko nikan ni ó ma ń hu eyín, àwọn ẹja àti ẹran inú omi náà ma ń hu eyín. .[1][2][3] Eyín kìí sábà ju nínú ẹnu nikan gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ́yà ẹranko kan ṣe ma hu ti wọn. Híhù eyín láàrín àwọn ẹjaa sábà ma ń wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹnu wọn, nígbà tí ti àwọn kan so mọ́ ẹ̀gbẹ́ erìgì wọn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. [4][5]
Àwọn Ìtọ́kasíÀtúnṣe
- ↑ Romer, Alfred Sherwood; Parsons, Thomas S. (1977). The Vertebrate Body. Philadelphia, PA: Holt-Saunders International. pp. 300–310. ISBN 978-0-03-910284-5.
- ↑ "Root or crown: a developmental choice orchestrated by the differential regulation of the epithelial stem cell niche in the tooth of two rodent species". Development 130 (6): 1049–57. March 2003. doi:10.1242/dev.00332. PMID 12571097.
- ↑ Hunt AM (1959). "A description of the molar teeth and investing tissues of normal guinea pigs". J. Dent. Res. 38 (2): 216–31. doi:10.1177/00220345590380020301. PMID 13641521. https://www.semanticscholar.org/paper/8015c2356eeef37b14df1c69d4cfd9c932187970.
- ↑ McCOLLUM, MELANIE; SHARPE, PAUL T. (July 2001). "Evolution and development of teeth". Journal of Anatomy 199 (1–2): 153–159. doi:10.1046/j.1469-7580.2001.19910153.x. PMC 1594990. PMID 11523817. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=1594990.
- ↑ nature.com, Fossil scans reveal origins of teeth, 16 October 2013