Fáwẹ̀lì Yorùbá

Fáwẹ̀lì ni ìró tí a pè tí kò sí ìdiwọ́ fún afẹ́fẹ́ tàbí èémí tÍ ó ń ti inú ẹ̀dọ̀ fóró bọ̀ wá sí ọ̀nà ẹnu. Bí àpẹẹrẹ: a, e, ẹ, i, o, ọ, u, an, ẹn, in, ọn, un,.

Gbogbo ìró fáwẹ̀lì èdè Yorùbá ló jẹ ìró akùnyùn. Èyí ni pé tán-án-ná gbọ̀n rìrì nígbà tí a pè wọ́n.

Oríṣi méjì ni fáwẹ̀lì èdè Yorùbá, àwọn ìsọ̀rí méjì náà ni…Fáwẹ̀lì àìránmúpè àti fáwẹ̀lì àránmúpè....

Fóníìmù àtúnṣe

Fóníìmù ni òṣùwọ̀n ìró tó mú ìyàtọ̀ wá láàrin ọ̀rọ̀ méjì. Nínú orí yìí, a ó ṣe àgbéyẹ̀wò fóníìmù fáwẹ̀lì àti fóníìmú kọ́ńsónáǹtì. A ó yẹ fóníìmú ohùn wò ni orí kárùn-ún ìwé yìí.

Àpẹẹrẹ Fóníìmú èdè Yorùbá

(a)(b) bí bọ́

ká kó

sọ̀ sè

fò fẹ̀...

Yorùbá Èdè Olóhun àtúnṣe

Àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá a máa dún bí orin nítorí pé èdè olóhùn ni èdè náà í ṣe. Àwọn ọ̀rọ̀ kan ní sípẹ́lì kan náà, ṣùgbọ́n ìtumọ̀ wọn yàtọ̀ nitorí ohùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọn gbérù. Bí àpẹẹrẹ:

agba

àgbà

àgbá ...


Rótìmí Ọláníyan ati Fẹ́mi Ọlọ́runfẹ́mi (2003), Àtùpà Àṣeyọrí, Àkọkún Ìsípayá Lórí Fònẹ́tíìkì pẹ̀lú ètò ìró Yorùbá ìwé Kìn-ín-ní. Ascent & Thrust Books Lagos, ISBN 978-32402-4-4, oju-iwe 8-25.