Fíìmu

Ìwà Ọ̀daràn

C.O. Odéjobí

C. O. Ọdẹjọbi (2004), ‘Àyẹ̀wò Ìgbékalẹ̀ Ìwà Ọ̀daràn nínú fíìmù Àgbéléwò Yorùbá’., Àpilẹ̀kọ fún Oyè Ẹẹ́meè, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria.

ÀṢAMỌ̀

Iṣẹ́ yìí ṣe àyẹwò sí bí isẹlẹ inú àwùjo se jé òpákùtèlè ìwà òdaràn nínú ìsòwó àwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá kan, b.a. ‘Ogun Àjàyè’, ‘Owọ́ Blow’, ‘Aṣéwó Kánò’, ‘Agbo Ọ̀dájú’, ‘Ṣaworoidẹ’, ‘Ìdè’, abbl. Àlàyé wáyé lórí ọ̀nà ìgbékalè ọ̀ràn nínú fíìmù àgbéléwò Yorùbá, bákan náa ni a sì tún se àyèwò ipa tí fíìmù àgbéléwò ajemọ́ ọ̀ràn dídá ń ní lórí àwọn òǹwòran, òsèré lọ́kùnrin-lóbìnrin àti àwùjo lápapọ̀. Iṣẹ́ yìí ṣe àyèwò ohun tó ń mú kí àwọn asefíìmù ó máa ṣe àgbéjáde fíìmù Yorùbá ajemó òràn dídá tó lu ìgboro pa báyìí, a sì tún wo orísirísi ìjìyà tí àwọn ọ̀daràn máa ń gbà.

Tíọ́rì ìmò ìfojú ìbára-eni-gbépò ni a lò kí a lè fi òràn dídá inú fíìmù wé tí ojú ayé. Ìfọ̀rọ̀ wá àwọn aṣefíìmù lénu wò wáyé láti mọ ìdí tí wọ́n fi ń gbé fíìmù ajẹmó òràn dídá jáde. A tún fi ọ̀rọ̀ wá àṣàyàn àwọn òṣèré lókùnrin àti lóbìnrin àti ònwòran lénu wò láti mo ìhà tí wón ko sí fíìmù ajemó òràn dídá àti ipa tí wíwo irúfé fíìmù béè lè ní lórí àwọn ènìyàn nínú àwùjo. Àwọn fíìmù àgbéléwò Yorùbá tó jẹ mọ́ iṣẹ́ yìí ni a wò tí a sì tú palè. Ní àfikún. Olùwádìí tún lọ sí ilé ìkàwé láti ka ọ̀pọ̀ ìwé bíi jọ́nà, átíkù, ìwé iṣé àbò-ìwádìí láti lè mo àwọn isé tó ti wà nílè.

Iṣẹ́ ìwádìí yìí fi hàn pé ìyàgàn àti àìní tó je mó owó, ipò, obìnrin àti àwọn nǹkan mìíràn tí ẹ̀dà lépa ló ń ti àwon ènìyàn sínú ìwà ọ̀daràn. Iṣẹ́ yìí se àkíyèsí pé lára àwọn tó ń lówó nínú ìwà ọ̀daràn ni a ti rí òré, ebí àti àwọn agbófinró. Bákan náà ni isẹ́ yìí tún se àfihàn onírúurú ọ̀nà tí àwọn ọ̀daràn wọ̀nyí ń gbà dá ọ̀ràn.

Ní ìparí. iṣé yìí gbà pé àwọn ìwà ọ̀daràn tó ń ṣelè ni a lè kà sí ọ̀kan lára ohun tí ìsẹ̀lẹ̀ àwùjọ bí àti pé ìjìyà ti a ń fún ọ̀daràn máa ń ní ipa nínú ẹbí wọn nígbà mìíràn.


Alábòójútó Kìíní: Ọ̀jọ́gbọ́n T.M. Ilésanmí

Alábòójútó Kejì: Ọ̀jọ̀gbọ́n B. Àjùwọ̀n

Ojú Ìwé: 249 ì