Fóníìmù
Fóníìmù ni àwọn ìró tí wọn bá lè fi ìyàtọ̀ láàárín ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí òmíràn hàn tàbí tí wọ́n bá lè mú ìyàtọ̀ ìtumọ̀ bá ọ̀rọ̀ ní sàkání kan náà, àwọn irú ìró bẹ́ẹ̀ ni a máa ń pè ní fóníìmù. Irú àdàkọ ti a sì máa ń ṣe fún àwọn fóníìmù ni èyí tí a mọ̀ sí àdàkọ fóníìmù.[1]
Báwo ni a ṣe lè wá fóníìmù rí nínú èdè kan? Ọ̀nà kan tí a fi lè wá fóníìmù rí nínú èdè kan ni nípa wíwá àwọn àpẹẹrẹ wúnrẹ̀n méjì tí ìró wọn jẹ́ bákannáà, àyàfi ẹyọ ìró kan ṣoṣo tí yóó yàtọ̀. Àwọn wúnrẹ̀n méjì tí wọn bá fi ìró kan ṣoṣo yàtọ̀ sí ara wọn báyìí ni à ń pè ni èjì-ọ̀kán-yà (minimal pairs), fún àpẹẹrẹ wo àwọn àtòjọ ọ̀rọ̀ ìsàlẹ̀ yìí
ètè ɛ̀tɛ̀ ɛ̀tɛ́
èdè ɛ̀fɛ̀ ɛ̀sɛ́
èkpè ɛ̀bɛ̀ ɛ̀kpɛ́
Àwọn ìró wo ni fóníìmù nínú àwọn ọ̀rọ̀ òkè yìí?
Kín ni ó sì fà á?
Ìró /t/, /d/, /kp/, /b/, /f/, àti /s/ jẹ́ fóníìmù. A ó ri pé ìró [t], [d], àti [kp] ni ó mú ìyàtọ̀ ìtumọ̀ bá ètè, èdè, àti èkpè. A jẹ́ pé fóníìmù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni /t/, /d/, àti /kp/ jẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni [t], [f] àti [b] jẹ́ nínú àpẹẹrẹ ɛ̀tɛ̀, ɛ̀fɛ̀, àti ɛ̀bɛ̀. Fóníìmù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni /t/, /f/. /b/ nítorí pé àwọn ni wọ́n fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀ nínú àpẹẹrẹ náà. Ẹ̀wẹ̀, bí a bá wo àpẹẹrẹ ɛ̀tɛ́, ɛ̀sɛ́ àti ɛ̀kpɛ́, ìró [t], [s] àti [kp] ni ó fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀, láìsí àní àní, fóníìmù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni /t/, /s/ àti /kp/ nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ìyàtọ̀ ìtumọ̀ bá àwọn ọ̀rọ̀ òkè yẹn.
Jẹ́ kí á tún wo àpẹẹrẹ mìíràn:
dá (dá owó)
dé (dé ọbẹ̀)
dí (dí garawa)
dú (dú adìrẹ)
dó (tẹ ìlú dó)
A ó rí i pé, àwọn ìró /á/, /é/, /í/, /ú/, àti /ó/ ni ó fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀. Nítorí náà fóníìmù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n.
Tún wo àpẹẹrẹ yìí
gbá
gbà
gba
Kín ni ó fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ òkè yìí?
Ohùn, àbí?
A jẹ́ pé ohun náà lè fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀, èyí já sí pé àwọn ohùn náà jẹ́ fóníìmù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Fóníìmù Kọ́nsónántì
àtúnṣeFóníìmù Kọ́nsónáǹtì ni àwọn fóníìmù tí wọ́n jẹ́ kọ́nsónáǹtì. Ìyẹn ni pé, àwọn kọ́nsónáǹtì tí wọ́n lè mú ìyàtọ̀ ìtumọ̀ bá ọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé lókè. Owólabí (2013:108) sọ pé, kò sí fóníìmù tí kì í ní ẹ̀dà-fóníìmù tirẹ̀. Òmíràn lè ní ẹ̀dà-fóníìmù kan ṣoṣo péré, òmíràn sì lè ní ju ẹ̀dà kan lọ. Nínú èdè Yorùbá, bí fóníìmù kan bá ní ju ẹ̀dà-fóníìmù kan lọ, àwọn ẹ̀dà-fóníìmù bẹ́ẹ̀ a máa wà ní ìfọ́nká aláìṣeyàtọ̀. Ní báyìí àwọn fóníìmù tí wọ́n jẹ́ kọ́nsónáǹtì èdè Yorùbá ni ìwọ̀nyí: /b/, /t/, /d/, /(/, /k/, /g/, /kp/, /gb/, /f/, /s/, /(/, /h/, /m/, /r/, /l/, /j/, /w/.
Kọ́nsónáǹtì [l] àti [n] jẹ́ ẹ̀dà fóníìmù kan náà. Ìdí ni pé wọ́n jẹyọ ni ìfọ́nká aláìṣèyàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe fi hàn saájú tí a ó tún fi hàn báyìí fún ìtẹnumọ́.
oní + ilé = onílé
oní + asọ = alásọ
ìró [n] jẹyọ ní sàkání ìránmú nígbà tí ìró [l] lè jẹyọ ní ipò mìíràn. Nítorí náà ẹ̀dà fóníìmù ni ìró [n] àti ìró [l] jẹ́. Ẹ̀dà fóníìmù wo wá ni wọ́n jẹ́? Wọ́n jẹ́ ẹ̀dà fóníìmù /l/. Àlàyé ni pé àgbègbè ìránmú nìkàn ni ìró [n] tilè jẹyọ. A jẹ́ pé bí ìró [l] bá ti jẹyọ ní sàkání ìránmú yóó yí padà sí ẹ̀dà rẹ́ tí ṣe ìró [n].
Ó yẹ kí a fi kún un pé bẹ́ẹ̀ kọ ni ọ̀rọ̀ rí nínú àwon ẹ̀ka èdè Yorùbá kan o. Àpẹẹrẹ ni ẹ̀kà èdè Òǹdó. Dípò
oní + owó = olówó
Ẹ̀ka èdè Òǹdó yóó sọ pé onówó. A jẹ́ pé fóníìmù ni /n/ jẹ́ nínú irú ẹ̀ka èdè bẹ́ẹ̀.
Àpẹẹrẹ ẹ̀dà fóníìmù mìíràn ni ọ̀rọ̀ ìsàlẹ̀ yìí fi hàn wá
wọ́n wọ́
tí a bá ṣe àdàkọ ọ̀rọ̀ òkè yìí yóó fi ìyàtọ̀ wọn hàn dáadáa
w᷈ↄ᷈́ wↄ́
kí ni o sàkíyèsí nípa [w] méjéèjì?
ọ̀kan ní ìránmú nígbà tí èkejì kò ní. Ṣùgbọ́n oun gan tí ó fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀ ni fáwẹ́lì aránmúpè àti àìránmúpè. Nítorí náà, ìfọ́nká aláìṣèyàtọ̀ ni [w] méjééjì ti jẹyọ wọ́n sì jẹ́ ẹ̀dà fóníìmù.
Fóníìmù Fáwẹ́lì
àtúnṣeÀwọn fóníìmù fáwẹ́lì èdè Yorùbá ni ìwọ̀nyí:
Fóníìmù fáwẹ̀lì àìránmúpè
/ i /, / e /, / ( /, / a /, / ( /, / o /, / u /
Fóníìmù fáwẹ̀lì àránmúpè
/ ĩ /, / (̃ /, / (̃ /, / ũ /
Jẹ́ kí a wo ìpèdè yìí:
[ìbàda᷈̀] àti [ìbàdↄ᷈̀]
[aha᷈́] àti [ahↄ᷈́]
Àkíyèsí wa ni pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàtọ̀ wà nínú pípe ìbàdàn síbẹ̀ kò mú ìyàtọ̀ ìtumọ̀ dán, nítorí náà, ìfọ́nka aláìṣèyàtọ̀ ni [ↄ᷈] ati [a᷈] wà, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀dà fóníìmu kan.
Fóníìmù ohùn tàbí Tóníìmù
àtúnṣeGẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé ohùn mẹ́ta ni ó máa ń fa ìyàtọ̀ ìtumọ̀ nínú èdè Yorùbá, a jẹ́ pé tóníìmù mẹ́ta náà ni ó wà nínú èdè Yorùbá. Wó àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ yìí:
gbá sún wá
gbà sùn wà
gba sun wa
a jẹ́ pé àwọn tóníìmù Yorùbá kò ní ẹ̀dà.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Speech Sounds, Phonetics, Phonology". Encyclopedia Britannica. 1998-07-20. Retrieved 2024-08-01.