Femi Gbajabiamila
Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 1962 (June 25, 1962) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèlú, Agbẹjọ́rò àti Agbẹnusọ Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣojú-ṣòfin ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú, All Progressives Congress tí ó ń ṣojú ìjọba ìbílẹ̀ Sùúrùlérè ni ìpínlẹ̀ Èkó láti ọdun 2019[1] [2] [3] [4]
Rt. Hon. Femi Abdulhakim Gbajabiamila | |
---|---|
Femi Gbajabiamila | |
Speaker of the House of Representatives of Nigeria | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga June 2019 | |
Asíwájú | Yakubu Dogara |
House Leader of the House of Representatives of Nigeria | |
In office June 2015 – June 2019 | |
Asíwájú | Ogor Okuweh |
Minority Leader of the House of Representatives of Nigeria | |
In office June 2011 – June 2015 | |
Arọ́pò | Ogor Okuweh |
Minority Leader of the House of Representatives of Nigeria | |
In office June 2007 – June 2011 | |
Asíwájú | Ahmed Salik |
Member of the House of Representatives of Nigeria | |
In office 2003–2007 | |
Asíwájú | yakubu Dogara |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 25 Oṣù Kẹfà 1962 Lagos State, Nigeria |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressive Congress (APC) |
Residence | Lagos |
Alma mater | University of Lagos |
Occupation | Legislature |
Website | http://femigbajabiamila.com |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeA bí Olufemi "Femi" Hakeem Gbajabiamila ní 25 June 1962 sí ìdílé Mr àti Mrs Lateef Gbajabiamila àti Olufunke Gbajabiamila ni Ìpínlè Èkó, Nàìjíríà. Ó lọ ilé ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ti Mainland fún àkọ́bẹ̀rẹ̀ àti Igbobi College[5] ní ọdún 1973, níbi tí ó ti parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ó tún padà lọ King's William's College ni Isle Of Man, orílè-èdè United Kingdom fún ìwé-ẹ̀rí A-Level rẹ̀.[6] Wọ́n gbà sí Yunifásítì Ìlú Èkó, Nàìjíríà.[7] níbí tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ nínú ìmò òfin(LL.B) pẹ̀lú ẹ̀yẹ ní ọdún 1983, a sì pé é láti wá ṣiṣẹ́ òfin(call to bar) ní ọdún 1984.
Ó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ni ilé-ìṣẹ́ agbẹjọ́rò Bentley Edu &Co., ní ìpínlè Eko, kí ó tó dá ilé-iṣẹ́ agbẹjọ́rò kan, Femi Gbaja & Co. kalẹ̀.
Ipa rẹ̀ nínú òṣèlú
àtúnṣeA yan Gbajabiamila sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ọdún 2003, ó sì ń ṣe aṣojú Surulere I ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Gbajabiamila máa ń sọ̀rọ̀ lòdì sí bí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ṣe máa ń yí láti ẹgbẹ́ òṣèlú kan sí òmíràn.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "THISDAYonline". BNW News. Archived from the original on 2020-01-13. Retrieved 2020-01-13.
- ↑ Assembly, Nigerian National (1962-06-25). "Federal Republic of Nigeria". National Assembly. Retrieved 2020-01-13.
- ↑ "When encomiums poured in torrents for Femi Gbajabiamila in Lagos". Premium Times Nigeria. 2012-06-27. Retrieved 2020-01-13.
- ↑ "Ahmed Lawan, Femi Gbajabiamila go lead Nigeria 9th National Assembly". BBC News Pidgin (in Kúẹ́ńjùà). 2019-06-11. Retrieved 2020-01-13.
- ↑ "What Osinbajo, Gbajabiamila have in common". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-02-05. Retrieved 2022-02-28.
- ↑ Ibiam, Agha (2004-02-07). "Gbaja-Biamila: Shocked Beyond Belief...". Thisday (BNW). Archived from the original on 2011-07-07. https://web.archive.org/web/20110707233300/http://news.biafranigeriaworld.com/archive/2004/feb/07/0043.html. Retrieved 2007-11-11.
- ↑ "Hon. Femi Gbaja Biamila". National Assembly website. National Assembly of Nigeria. Archived from the original on 2016-03-03. Retrieved 2007-10-23. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)