Fẹ́mi Odùgbèmí
Fẹ́mi Odùgbèmị́ tí wọ́n bí ní ọdún 1963 jẹ́ òǹkọ̀tàn àti olùya fọ́rán àwọn àkọsílẹ̀ láé láé, adarí eré, olùgbéré jáde àti ayàwòrán ọmọ orịlẹ̀-èdè Nàìjírià.[1][2][3]
Fẹ́mi Odùgbèmị́ | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1963 Ìpínlẹ̀ Èkó |
Orílẹ̀-èdè | Nàìj́íríà |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìj́íríà |
Iṣẹ́ |
|
Notable work | "Tinsel" (TV series,2008)'"Mama Put"(TV Movie, 2005) "Maroko"(feature film,2006) "Gidi Blues"(Feature film, 2016) "And the Chain was Not" (Documentary,2010) "ORIKI"(Documentary,2008) "Battleground"(TV drama, 2017) "The Eve"(Feature film, 2017) and "4th Estate"(Feature film, 2018) "Missing Pages"(Feature film 2018) "CODE WILO"(Feature film 2019) |
Awards | Fellow of Theatre Arts, National Association of Nigerian Theatre Arts Practitioners(NANTAP) 2013 Excellence Award in Film by the Society for the Performing Arts in Nigeria(SPAN). Nigerian Film Corporation Lifetime Achievement Award. |
Website | www.zuri24media.com |
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeFẹ́mi Odùgbèmị́ ni wọ́n bí ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[4] Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Montana State University níbi tí ó ti kọ́ nípa gbígbé eré àti ìṣàgbékalẹ̀ ètò orí ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, Ó ṣiṣẹ̣́ ní ilé-iṣẹ́ amóhùn-máwòrán ti NTA, lẹ́yìn èyí ni ó tún ṣiṣẹ́ ní Lintas Advertising and McCann-Erickson fún eré orí rédíò .
Ó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré, ó sì ti ya àwọn fọ́rán àkọsílẹ láé láé lóríṣiríṣi, ó sì ti gbé àwọn eré oníṣe ọlọ́kan-ò-jọ̀kan jáde pẹ̀lú.[5] Oun ni o gbe ere onise onipele atigbadegba ti Tinsel ti o bere ni aarin osu Kejo odun 2008 jade.[6] Ó ti fipa rẹ̀ lélẹ̀ ní orí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùgbé àwọn eré oníṣe orí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán ní ilẹ̀ Áfíríkà . Odùgbèmí ni ó kọ eré Bariga Boys, òun ni ó darí rẹ̀ tí ó sì gbe jáde pẹ̀lú,. Fọ́nrán àwòrán Bariga Boys jẹ́ ìṣesí àti ìgbé ayé àwọn ènìyàn pàá pàá jùlọ, àwọn òṣèré ojú pópó ní ìlú Bàrígà ní Ìpínlẹ̀ Èkó. [7]
Ní ọdún 2013, òun ni ó kọ tí ó sì ya fọ́rán àwọn àkọsílẹ̀ láé láé tí ó pe àkòrị́ rẹ̀ ní Literature, Language and Literalism nípa gbajú-gbajà òǹkọ̀tàn ìwé Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúmọlẹ̀ ìyẹn olóògbé Daniel O. Fágúnwà .[8]
Ní ọdún 2002, ó di Ààrẹ fụ́n ẹgbẹ́ àwọn Independent Television Producers Association of Nigeria, tí ó sì kúrò ní ipò náà ní ọdún2006.[9] He is a member of the Advisory Board of the School of Media and Communications, Pan-African University, a postgraduate training university.[10] O gbe ere kan ti o pe akole re ni Abobaku jade ni odun 2008, ere ti Niji Akanni se adari re.[11] The film won the Most Outstanding Short Film at the Zuma Film Festival held in 2010 and Best Costume at the 6th Africa Movie Academy Awards as held on 10 April 2010 at the Gloryland Cultural Center in Yenagoa, Bayelsa State, Nigeria.[12]
Ní ọdún 2010, òun àti àwọn kan dá IREPRESENT International Documentary Film Festival Lagos, èyí tí ó gbé àkòrí rẹ̀ kalẹ̀ lé “Africa in self-conversation” kí wọ́n lè ma ṣe àgbéjáde ìtàn ilẹ̀ Áfíríkà láti ọwọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà.
Wọ́n fìwé pèé kí ó wá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ tí ó ń rí sí ìdìbòyàni lábẹ́ The Academy of Motion Picture Arts and Sciences ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹfà ọdún 2018, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà[13]
Àjọ Nigeria Film Corporation fún Fẹ́mi ní àmì-ẹ̀yẹ ti ROCK OF FAME ni odun 2018 fún iṣẹ́ ribiribi rẹ̀ .
Ẹ tún lè wo
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Krings, M.; Okome, O. (2013). Global Nollywood: The Transnational Dimensions of an African Video Film Industry. Indiana University Press. p. 44. ISBN 9780253009425. https://books.google.com/books?id=uTVlKirJmGgC. Retrieved 2015-04-12.
- ↑ "Making documentary films relevant in a digital age". tribune.com.ng. Archived from the original on 2015-04-12. Retrieved 2015-04-12. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "iREP 2014 explores rhythms of identity". tribune.com.ng. Archived from the original on 2015-04-12. Retrieved 2015-04-12. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "In Kampala, Odugbemi meets Ozokwor". punchng.com. Archived from the original on 2015-04-12. Retrieved 2015-04-12. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Ekenyerengozi, M.C. (2013). NOLLYWOOD MIRROR®. LULU Press. p. 41. ISBN 9781304729538. https://books.google.com/books?id=RL01BgAAQBAJ. Retrieved 2015-04-12.
- ↑ "Tinsel, a return to the golden age of TV drama - Entertainment". dailyindependentnig.com. Archived from the original on 2013-10-11. Retrieved 2015-04-12. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Hidden wealth in documentary films". punchng.com. Archived from the original on 2015-04-12. Retrieved 2015-04-12. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Candid lens on a legendary writer". punchng.com. Archived from the original on 2015-04-12. Retrieved 2015-04-12. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Parekh, B. (2008). A New Politics of Identity: Political Principles for an Interdependent World. Palgrave Macmillan. p. 197. ISBN 9781137050700. https://books.google.com/books?id=soodBQAAQBAJ. Retrieved 2015-04-12.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Africultures - Biographie de Fémi Odugbemi". africultures.com. Retrieved 2015-04-12.
- ↑ "Africultures - Fiche film : Abobaku". africultures.com. Retrieved 2015-04-12.
- ↑ "AMAA 2010: 280 films entered, as Ghana hosts nomination party - Vanguard News". vanguardngr.com. Retrieved 2015-04-12.
- ↑ "Nigeria's Femi Odugbemi becomes member of Oscars voting academy – Punch Newspapers". punchng-com.cdn.ampproject.org. Retrieved 2018-06-26.