Farida Mzamber Waziri (tí a bí ní ọjọ́ keje oṣù keje ọdún 1949) jẹ́ òṣìṣẹ́ agbófinró àti Executive Chairperson ti Economic and Financial Crimes Commission nígbà kan rí.[1] Òun ló bọ́ sípò náà lẹ́yìn tí Nuhu Ribadu fi ipò náà sílẹ̀.

Farida Mzamber Waziri
Chairman of Nigeria's Economic and Financial Crimes Commission
In office
May 2008 – 23 November 2011
AsíwájúNuhu Ribadu
Arọ́pòIbrahim Lamorde
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1949-07-07)7 Oṣù Keje 1949
Gboko, Benue State.
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Alma materLagos State University
OccupationPolice officer, lawyer

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀ àtúnṣe

Ọjọ́ keje oṣù keje ọdún 1949 ni a bí Farida Mzamber Waziri ní ìlú Gboko ní ìpínlẹ̀ Benue. Ó gboyè degree nínú Law ní University of Lagos àti master's degree ní Law bákan náà ní Lagos State University.[2] Ní ọdún 1996, ó gba master's degree nínú Strategic Studies ní University of Ibadan. Òun ló kọ ìwé kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Advance Fee Fraud, National Security and the Law.[3] Senator Ajuji Waziri ni ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ sì ṣaláìsí ní ọdún 2017.[4]

Iṣẹ́ rẹ̀ àtúnṣe

Ní ọdún 1965, Farida Waziri wà lára àwọn tí wọ́n gbà wọlé sí Nigeria Police Force. Ó sì bọ́ sí ipò Assistant Inspector General of Police. Ó di ipò Assistant Commissioner of Police (Operations), screening and selection, Assistant/Deputy Commissioner of Police Force C.I.D Alagbon, Lagos, Commissioner of Police, General Investigation àti Commissioner of Police in charge of X-Squad mú nígbà náà. Ipò ìkẹyìn tó dì mú ní èyí tó ń rí sí ìwà ìbàjẹ́ àti gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láàárín àwọn agbófinró. Ó tún jẹ́ Commissioner of Police (special fraud unit) nígbà náà, èyí tó ń rí sí ìwà jìbìtì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ó kó àwọn ikọ̀ West African tó ń rí sí ìwà jìbìtì lọ sí ìlú Lyons ní France ní ọdún 1996. Ó tún kó àwọn ikọ̀ ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí ìlú Dallas ní Texas fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí United States Secret Service ṣagbátẹrù ní ọdún 1998.

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Executive Chairman, EFCC". Economic and Financial Crimes Commission. 11 June 2008. Archived from the original on 20 October 2009. Retrieved 25 September 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Nigeria: EFCC Chair – Farida Will Do Better". Leadership (Abuja). 7 June 2008. Retrieved 25 September 2009. 
  3. Farida Mzamber Waziri (2005). Advance fee fraud: national security and the law. BookBuilders / Editions Africa. pp. 152. ISBN 978-8088-30-9. 
  4. Levinus, Nwabughiogu (19 April 2017). "Former EFCC boss, Farida Waziri loses husband". Vanguard Media Limited. https://www.vanguardngr.com/2017/04/former-efcc-boss-farida-waziri-loses-husband/. Retrieved 11 March 2019.