Fatima Yusuf-Olukoju (Tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejì 2 oṣù karùn-ún, Ọdún 1971 ní Ọ̀wọ̀, Ìpínlẹ̀ Òndó) jẹ́ Asáré Nàìjíríà tó ti fẹhìntì, tó sáábà máa ń díje ní 400 mitàsì ní gbogbo ìgbà tó ń sáré. Ó gba ipò kìíní ní ìdíje 400 mitàsì ní 1991 All-Africa Games àti ipò kejì ní ìdíje 200 mitàsì. Ó fẹ́ Adewale Olukoju.[1]

Fatima Yusuf
Òrọ̀ ẹni
Ọjọ́ìbí2 May 1971


Ayé rẹ̀

àtúnṣe

Ó padà díje ní 200 mitàsì, ìdíje ti gbogbo ayé ní Spain níbi tó ti sá 22.28 Ìṣẹ́jú-àáyá. Òun náà tún ni obìnrin àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti sáré lábẹ́ àádọ́ta Ìṣẹ́jú-àáyá ní 400 mitàsì. Ó sá 49.43 Ìṣẹ́jú-àáyá ní ọdún 1995 ní ìdíje tó wáyé láàárín àwọn Adúláwọ̀.[2]

Ó díje fún Nàìjíríà ní súmà Òlípíkìsì ti ọdún 1996 tí wọ́n ṣe ní Atlanta United States ní 400 mitàsì níbi tó ti gbá ipò kẹfà pẹ̀lú Ìṣẹ́jú-àáyá 49.77 àti 4 x 400 mitàsì níbi tó ti gba ẹbùn fàdákà pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ Bisi Afolabi, Charity Opara àti Falilat Ogunkoya lẹ́yìn ìlú America tó gbé ìdíje náà kalẹ̀. Ó lọ sí Azusa Pacific University.[3]

Ìtọ́kasí

àtúnṣe

Àdàkọ:Footer African Champions women's 200 metres Àdàkọ:Footer African Champions women's 400 metres Àdàkọ:Footer Commonwealth Champions 400m Women Àdàkọ:Footer All-Africa Champions 200 m Women Àdàkọ:Footer All-Africa Champions 400 m Women Àdàkọ:Authority control

Àdàkọ:Nigeria-athletics-bio-stub Àdàkọ:Nigeria-Olympic-medalist-stub

  1. "Fatima Yusuf". Wikipedia. 2006-08-28. Retrieved 2022-05-20. 
  2. "Fatimat YUSUF - Profile". worldathletics.org. 1996-01-01. Retrieved 2022-05-20. 
  3. Akpodonor, Gowon (2021-05-18). "Yusuf Alli, Ogunkoya, Fatima Yusuf, others warm up for AFN elections - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2022-05-20. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]