Fáwẹ̀lì Yorùbá
Fáwẹ̀lì Yorùbá
Fáwẹ̀lì ni ìró tí a pè tí kò sí ìdiwọ́ fún afẹ́fẹ́ tàbí èémí tÍ ó ń ti inú ẹ̀dọ̀ fóró bọ̀ wá sí ọ̀nà ẹnu. Bí àpẹẹrẹ: a, e, ẹ, i, o, ọ, u, an, ẹn, in, ọn, un,.
Gbogbo ìró fáwẹ̀lì èdè Yorùbá ló jẹ ìró akùnyùn. Èyí ni pé tán-án-ná gbọ̀n rìrì nígbà tí a pè wọ́n.
Oríṣi méjì ni fáwẹ̀lì èdè Yorùbá, àwọn ìsọ̀rí méjì náà ni…Fáwẹ̀lì àìránmúpè àti fáwẹ̀lì àránmúpè....
Fóníìmù
àtúnṣeFóníìmù ni òṣùwọ̀n ìró tó mú ìyàtọ̀ wá láàrin ọ̀rọ̀ méjì. Nínú orí yìí, a ó ṣe àgbéyẹ̀wò fóníìmù fáwẹ̀lì àti fóníìmú kọ́ńsónáǹtì. A ó yẹ fóníìmú ohùn wò ni orí kárùn-ún ìwé yìí.
Àpẹẹrẹ Fóníìmú èdè Yorùbá
(a)(b) bí bọ́
ká kó
sọ̀ sè
fò fẹ̀...
Yorùbá Èdè Olóhun
àtúnṣeÀwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá a máa dún bí orin nítorí pé èdè olóhùn ni èdè náà í ṣe. Àwọn ọ̀rọ̀ kan ní sípẹ́lì kan náà, ṣùgbọ́n ìtumọ̀ wọn yàtọ̀ nitorí ohùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọn gbérù. Bí àpẹẹrẹ:
agba
àgbà
àgbá ...
Rótìmí Ọláníyan ati Fẹ́mi Ọlọ́runfẹ́mi (2003), Àtùpà Àṣeyọrí, Àkọkún Ìsípayá Lórí Fònẹ́tíìkì pẹ̀lú ètò ìró Yorùbá ìwé Kìn-ín-ní. Ascent & Thrust Books Lagos, ISBN 978-32402-4-4, oju-iwe 8-25.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |