Fenda Lawrence
Fenda Lawrence (1742[1] – lẹ́yìn 1780), jẹ́ olóko òwò ẹrú Áfíríkà tí ó ṣiṣẹ́ yìí ní Saloum, ìlú Kaur.
Fenda Lawrence | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | circa 1742 Saloum |
Aláìsí | After 1780 |
Iṣẹ́ | Slave trader |
Ìtàn ayé rẹ̀
àtúnṣeFenda Lawrence gbé lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Gambia ní àwọn ọdún 1700s. Ní àdúgbò náà, ó jé òlùbádúna dúrà láàrin àwọn oníṣòwò Britain, France àti àwọn oníṣòwò Áfíríkà. Ó di ipò yìí mú lẹ́yìn ìgbà tí ó fẹ́ Òyìnbó kan. Lawrence ṣiṣẹ́ láti Saloum ìlú tí Kaur.[2] Ní ọdún 1772, Lawrence lọ sí Thirteen Colonies ti America láti ṣòwò.[3] Nígbà yìí, ó ti yapa láti ọ̀dọ̀ Oko òyìnbó tí ó fẹ́.[2]
Nígbà tí ó wọ ọkọ ojú New Britannia, Lawrence mú ẹrú márùn-ún pẹ̀lú ara rẹ̀. Ọkọ̀ náà déCharleston, South Carolina, lẹ́yìn ọjọ́ méjìdínlógójì tí ọ́ gbéra. Adarí ọkọ̀ náà, Stephen Deane, sì tẹ̀lé Lawrence lọ sí Georgia.[2]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Hassoum Ceesay: Gambian women: an introductory history. 1. Auflage. Fulladu Publishers, Gambia 2007
- ↑ 2.0 2.1 2.2 Akyeampong & Gates, Jr. 2012, p. 475.
- ↑ Holloway 2005, p. 49.