Fidelity Bank Nigeria
Fidelity Bank, tí a tún mọ̀ sí Fidelity Bank Plc., jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé-ìfowópamọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí olú ilé-iṣé wọn wà ní Victoria Island, Lagos. Ó jẹ́ ilé-ìfowópamọ́ tó ti gbàwé àṣẹ, tí Central Bank of Nigeria sì ti fòǹtẹ̀ lù gẹ́gẹ́ b́i báǹkì oníṣòwò.[2]
Fidelity-bank-nigeria.png | |
Type | Public |
---|---|
Founded | 1988 |
Headquarters | Lagos State, Nigeria |
Key people | Mustafa Chike-Obi (Chairman), Nneka Onyeali-Ikpe (Managing Director & Chief Executive Officer)[1] |
Industry | Financial Services |
Products | Loans, Credit Cards, Savings, Investments, Mortgages |
Total assets | US$4.2 billion (NGN:1.4 + trillion) (2017) |
Website | fidelitybank.ng |
Ilé-ìfowópamọ́ ti Fidelity ti pẹ̀ka láti ibi gegele, ó sì ti di ilé-ìfowópamọ́ tó dúró ṣinṣin, tó sì ti gbayì láwùjọ. Ní ọdún 2005, ilé-ìfowópamọ́ yìí gba FSB International Bank Plc (“FSB”) àti Manny Bank Plc (“Manny”) láti ṣẹ̀dá ọ̀kan nínú àwọn báǹkì mẹ́wàá tó ga jù lọ ní Nàìjíríà. Ní ọdún 2011, báǹkì náà wà ní ipò keje nínú ààtò àwọn báńkì tó tóbi jù lọ ní Nàìjíríà, àti ipò karùndínlọ́gbọ̀n nínú ààtò àwọn báǹkì tó tóbi jù lọ ní Africa. Wọ́n tún fi sípò kẹrin, ìyẹn lára àwọn báǹkì tó dára jù lọ ní orílè-èdẹ̀ Nàìjíríà.[3]
Ìtàn
àtúnṣeFidelity Bank of Nigeria forúkọ sílẹ̀ ní ọdún 1987, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1988. Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òwò kékèèké.
Fidelity Bank yí padà láti di ilé-ìfowópamọ́, oníṣòwò ńlá ní ọdún 1999, pẹ̀lú ìgbìyànjú láti dàgbà gẹ́gẹ́ bíi ilé-iṣẹ́ tó ní ìpín ìkọ̀kọ̀ àmọ́ ó di ilé-iṣẹ́ tó nípìín gbangba ní ọdún 1999 bákan náà. Ọdún náà lorúkọ rẹ̀ sì yí padà sí Fidelity Bank Plc.[4]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Nneka Onyeali-Ikpe Managing Director/CEO". Bloomberg. Retrieved January 2, 2020.
- ↑ "Central Bank of Nigeria | Commercial Banks". www.cenbank.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2017-08-24.
- ↑ Chima, Obinna (2014-01-15). "Nigeria: Okonkwo Resumes As Fidelity Bank CEO". This Day (Lagos). http://allafrica.com/stories/201401150364.html.
- ↑ "History of Fidelity Bank Nigeria". Archived from the original on 2014-01-16. Retrieved 2014-01-15. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help)